Rírìn Nípa ti Ẹ̀mí (5)
Ọjọ́ Kọkàndínlógún (19), Ọjọ́rú , Oṣù ́Kíní , Ọdún 2022
Rírìn Nípa ti Ẹ̀mí (5)
Nitorina Kristi ni àpẹẹrẹ bí o ṣe yẹ kí onigbagbọ máa hùwa. Irú ohun tí Kristi ṣe láti tẹ Ọlọrun lọrùn náà ni àwa tí a jẹ ọmọ Ọlọrun kan náà pèlú rè gbọdọ máa ṣe. Irú àṣẹ kan náà tí Kristi ní ni àwa náà ní nínú rẹ. Kí ni ìdí èyí? Nitoripe pabambari wípé ènìyàn ti di ọmọ Ọlọrun ni wípé O ní ipò kan náà níwájú Ọlọrun gẹgẹ bí Kristi. Ohun tí Kristi ṣe ìlérí rẹ fún àwọn ọmọlẹyìn rẹ ni eyi.
JOHANU 14:2-3
[2]Ninu ile Baba mi ọ̀pọlọpọ ibugbe li o wà: ibamáṣe bẹ̃, emi iba ti sọ fun nyin. Nitori emi nlọ ipèse àye silẹ fun nyin. [3]Bi mo ba si lọ ipèse àye silẹ fun nyin, emi o tún pada wá, emi o si mu nyin lọ sọdọ emi tikarami; pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu.Nínú ẹsẹ yìí, e jẹ kí a ṣe àkíyèsí ohun kan níbẹ. Jésù sọ wípé “nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu”
Tó bá jẹ wípé ọ̀run ni Kristi n sọ nínú nínú ẹsẹ tí a nkà yí ni Jésù ìbá sọ fún wọn wípé “ni ibití èmí n lọ”, ṣugbọn o sọ wípé ní ibi tí èmí gbé wà. Nitorina, ohun tí Jésù n sọ ni wípé ní ipò tí òun wà níwájú Ọlọrun, kí àwọn ọmọlẹyìn rẹ náà lè wà níbẹ pẹlu. Kíni ipò tí Kristi wà níwájú Ọlọrun nígbà náà?
JOHANU 3:16
[16]Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹ̃ gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun.Ó jẹ ọmọ bíbí nikanṣoṣo fún Ọlọrun. Nitorina gẹgẹ bí a ó ṣe di ọmọ Ọlọrun nípa ìgbàgbọ nínú rẹ ni Jésù n sọ. Báwo ni a ṣe mọ èyí?
Ibí tí Jésù ti sọ fún àwọn ọmọlẹyìn rẹ nípa wípé wọn yóò wà ní ibi, tàbí ipò tí òun wà níwájú Ọlọrun ni Jòhánù orí kẹrinla. Tí a bá kàà siwaju sí, ó rí ohun tí Jésù n sọ kedere gẹgẹ bí atubotan ipò tí òun wà níwájú Ọlọrun.
JOHANU 14:12
[12]Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, iṣẹ ti emi nṣe li on na yio ṣe pẹlu; iṣẹ ti o tobi jù wọnyi lọ ni yio si ṣe; nitoriti emi nlọ sọdọ Baba.Ìyẹn ní wípé àwa náà ti yóò l’agbara láti ṣe àwọn ohun tí Jésù n ṣe gẹgẹ bí ọmọ Ọlọrun. Ṣugbọn o sọ ìgbà tí èyí yóò ṣẹlẹ fún àwọn ọmọlẹyìn rẹ.
JOHANU 14:3
[3]Bi mo ba si lọ ipèse àye silẹ fun nyin, emi o tún pada wá, emi o si mu nyin lọ sọdọ emi tikarami; pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu.Ẹ jẹ kí a wo bí Jésù ṣe pèse ààyè sílẹ fún àwọn onígbàgbọ nínú rẹ láti lè ṣe iṣẹ kan náà tí Jésù n ṣe. Èyí wa sí imusẹ lẹhin ìgba tí Jésù jinde.
MATIU 28:18
[18]Jesu si wá, o si sọ fun wọn, wipe, Gbogbo agbara li ọrun ati li aiye li a fifun mi.