Rírìn Nípa ti Ẹ̀mí (4)
Ọjọ́ Kejìdínlógún (18), Ọjọ́ Ìsẹ́gun , Oṣù ́Kíní , Ọdún 2022
Rírìn Nípa ti Ẹ̀mí (4)
Kò sí ònà kankan tí onigbagbọ fi lè dúró ṣinṣin nínú ìfẹ Ọlọrun ayafi ti irú ènìyàn bẹẹ bá faraji fún ọrọ Ọlọrun.
E jẹ kí a wo ẹrí tó wà nínú ayé Kristi gẹgẹ bí ọmọ Ọlọrun.
HEBERU 4:15
[15]Nitori a kò ni olori alufa ti kò le ṣai ba ni kẹdun ninu ailera wa, ẹniti a ti danwo li ọna gbogbo gẹgẹ bi awa, ṣugbọn lailẹ̀ṣẹ.A lè rò wípé nítorípé Jésù jẹ ọmọ bíbí nikanṣoṣo fún Ọlọrun ni èyí ṣeeṣe ninu ayé rẹ̀. Kò rí béè, ohun tí Jésù ṣe jẹ ohun tó jẹ àpẹẹrẹ fún gbogbo wa tí a jẹ ọmọ Ọlọrun bakanna pẹlu. Njẹ a mọ wipe ìdí tí Jésù fi kú gan ni láti lè fún wa ní ìbáṣepọ̀ kan náà tó ní pẹlu Ọlọrun? Bẹẹ ni, kí àwa náà lè ní irú ìbáṣepọ̀ tí Jésù ní pẹlu Ọlọrun gẹgẹ bí Bàba àti ọmọ ló fàá tó fí kú tí o sì jinde kuro ninu oku.
JOHANU 17:20-22
[20]Kì si iṣe kìki awọn wọnyi ni mo ngbadura fun, ṣugbọn fun awọn pẹlu ti yio gbà mi gbọ́ nipa ọ̀rọ wọn; [21]Ki gbogbo nwọn ki o le jẹ ọ̀kan; gẹgẹ bi iwọ, Baba, ti jẹ ninu mi, ati emi ninu rẹ, ki awọn pẹlu ki o le jẹ ọ̀kan ninu wa: ki aiye ki o le gbagbọ́ pe, iwọ li o rán mi. [22]Ogo ti iwọ ti fifun mi li emi si ti fifun wọn; ki nwọn ki o le jẹ ọ̀kan, gẹgẹ bi awa ti jẹ ọ̀kan;Ó fẹ kí a jẹ ọkan pẹlú baba gẹgẹ bí oun náà ṣe jẹ ọkan pẹlú baba. Kí Jésù tó lọ sí orí Igi agbelebu, Bíbélì pèé ní ọmọ Bíbí nikanṣoṣo fún Ọlọrun. Ṣugbọn lẹhin ìgba tí Jésù jinde kúrò nínú òkú, kò rí bẹ́ẹ̀ mọ.
JOHANU 20:17
[17]Jesu wi fun u pe, Máṣe fi ọwọ́ kàn mi; nitoriti emi kò ti igòke lọ sọdọ Baba mi: ṣugbọn lọ sọdọ awọn arakunrin mi, si wi fun wọn pe, Emi ngòke lọ sọdọ Baba mi, ati Baba nyin; ati sọdọ Ọlọrun mi, ati Ọlọrun nyin.Nínú gbólóhùn kan náà ni Jésù, lẹhin ìgba tó jinde kuro ninu oku, ti pe Ọlọrun ní Baba rẹ àti baba wa, awa tí a ti gbagbọ nínú rẹ. Nitorina, ní ìwọn ìgbà tí Jésù ti sí ònà sílẹ fún wa láti di ọmọ Ọlọrun gẹgẹ bi tirẹ, a jẹ wípé O ti di akọbi nìyẹn, àwa náà wá jẹ mọlẹbi àti àjùmọ̀jogún pẹlu Ọlọrun nìyẹn.
EFESU 2:19
[19]Njẹ nitorina ẹnyin kì iṣe alejò ati atipo mọ́, ṣugbọn àjumọ jẹ ọlọ̀tọ pẹlu awọn enia mimọ́, ati awọn ará ile Ọlọrun;A ti di ará ilé Ọlọrun.
ROMU 8:17
[17]Bi awa ba si jẹ ọmọ, njẹ ajogun li awa, ajogun Ọlọrun, ati ajumọ-jogun pẹlu Kristi; biobaṣepe awa bá a jìya, ki a si le ṣe wa logo pẹlu rẹ̀.A ti di àjùmọ̀jogún pẹlu Kristi gẹgẹ bí ọmọ Ọlọrun.