Rírìn Nípa ti Ẹ̀mí (3)
Ọjọ́ Kẹtàdínlógún (17), Ọjọ́ Ajé , Oṣù ́Kíní , Ọdún 2022
Rírìn Nípa ti Ẹ̀mí (3)
Tó bá jẹ wípé ọrọ Ọlọrun ni ohun tí a n gbọ ní gbogbo ìgbà tí a sì n fetí sí, ìrònú wa yóò yatọ sí bí àwọn tí ayé yi se máa n ronú, nítorípé ó ní bí àwọn tí ayé yi se máa n ronú.
EFESU 4:17
[17]Njẹ eyi ni mo nwi, ti mo si njẹri ninu Oluwa pe, lati isisiyi lọ ki ẹnyin ki o máṣe rìn mọ́, ani gẹgẹ bi awọn Keferi ti nrin ninu ironu asan wọn,Nitorina ohun tó fàá tí àwọn aláìgbàgbọ fi n hùwa gẹgẹ bí aláìgbàgbọ kìíse ojú lásán, kìíse wípé wọn kàn fẹẹ máa hùwa gẹgẹ bí aláìgbàgbọ tàbí bí o ṣe wù wọn, kò bẹẹ rárá. Lootọ wọn lè má mọ tàbí kí wọn má gbagbọ ṣugbọn ohun tó n fàá tí àwọn aláìgbàgbọ fi n hùwa gẹgẹ bí wọn ṣe n hùwa ni èmí tó n ṣiṣẹ ninu wọn.
EFESU 2:2
[2]Ninu eyiti ẹnyin ti nrin rí gẹgẹ bi ipa ti aiye yi, gẹgẹ bi alaṣẹ agbara oju ọrun, ẹmí ti nṣiṣẹ nisisiyi ninu awọn ọmọ alaigbọran:Nínú ẹsẹ yìí, Bíbélì tọkasi èmí tó n ṣiṣẹ nínú àwọn ọmọ alaigbọran. Alaigbọran túmọ̀sí aláìgbàgbọ. Nitorina bí onigbagbọ ṣe lè rí wípé a kò jọwọ ara wa fún irú èmí bẹẹ ni láti máa jiroro nínú ọrọ Ọlọrun. Kò sí ẹnikẹ́ni tí èmi tó wà nínú àwọn ọmọ alaigbọran yìí kò ní gbìyànjú láti lè tàn jẹ. Bẹẹ náà ni a ri nínù ìdánwò Jésù. O ṣeeṣe kí Jésù náà jọwọ ara rẹ fún irú èmí bẹẹ ṣugbọn Jésù pinnu dúró ṣinṣin. Báwo ni Jésù ṣe dúró ṣinṣin?
LUKU 4:4
[4]Jesu si dahùn wi fun u pe, A ti kọwe rẹ pe, Enia kì yio wà lãye nipa akara nikan, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ Ọlọrun.LUKU 4:8
[8]Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Kuro lẹhin mi, Satani, nitoriti a kọwe rẹ̀ pe, Iwọ foribalẹ fun Oluwa Ọlọrun rẹ, on nikanṣoṣo ni ki iwọ ki o si ma sìn.LUKU 4:12
[12]Jesu si dahùn o wi fun u pe, A ti sọ pe, Iwọ kò gbọdọ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.Kí Jésù tó sọ wípé”a ti kọ wípé”, a jẹ wípé Jésù náà ká ọrọ tí a ti kọ sílẹ ni. Nítorí naa tí a bá fẹ mú gẹgẹ bí ojúṣe láti máa tẹlé ọrọ Ọlọrun ní gbogbo ìgbà, ohun tí a gbọdọ mú gẹgẹ bí ojúṣe ni kíkà àti ṣíṣe àṣàrò ninu ọrọ Ọlọrun.
Jésù, gẹgẹ bí ẹni tó tẹle ọrọ Ọlọrun ní ẹrí rere.
JOHANU 8:29
[29]Ẹniti o rán mi si mbẹ pẹlu mi: kò jọwọ emi nikan si; nitoriti emi nṣe ohun ti o wù u nigbagbogbo.Kí ló fún Jésù ní okun láti máa tẹlé ọrọ Ọlọrun ní gbogbo ìgbà? Kíkà ọrọ Ọlọrun ni.