Rírìn Nípa ti Ẹ̀mí (1)
Ọjọ́ Karùndínlógún (15), Ọjọ́ Àbámẹ́ta, Oṣù ́Kíní , Ọdún 2022
Rírìn Nípa ti Ẹ̀mí (1)
Ní ìwọn ìgbà tí ènìyàn bá ti di onígbàgbọ, ọkan ninu awọn ohun tó ṣe pàtàkì láti mọ ni wípé a ti ní ojúṣe láti mọ Ọlọrun. Iyatọ wà nínú kí ènìyàn gbagbọ lati di atunbi àti kí ènìyàn mọ Ọlọrun. Kìíse ọjọ tí a bá di atunbi náà ni a ó mọ ohun gbogbo tó yẹ kí a mọ nípa Ọlọrun. Tí a bá tilẹ fẹ gbọ otitọ, kò ṣeeṣe lati mọ ohun gbogbo nípa Ọlọrun. Ṣugbọn o jẹ ojúṣe wa lati máa dagbasoke si nípa ti òòrè ọfẹ. Peteru sọrọ nípa èyí nínú ìwé rẹ sí gbogbo ènìyàn.
PETERU KEJI 3:18
[18]Ṣugbọn ẹ mã dàgba ninu õre-ọfẹ ati ninu ìmọ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi; ẹniti ogo wà fun nisisiyi ati titi lai. Amin.Ó ṣeni laanu wípé ọpọlọpọ onígbàgbọ máa n rò wipe ní ìwọn ìgbà tí àwọn sáà ti di ẹni ìgbàlà a jẹ wipe o parí síbẹ̀ nìyẹn. Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ohun tó fi ṣe pàtàkì láti mọ Ọlọrun ni wípé bí a ṣe n mú inú Ọlọrun dùn nìyẹn. Kìíse wípé Ọlọrun n bínú sí wa, lootọ ni Olorun fẹ wa, bẹẹ sì ni Ọlọrun kò ṣe ojúsàájú ẹnikẹni.
Gẹgẹ bí òbí, a ó ri wípé inú wa kò ní dùn sí rárá tí a bá bí kò o ọmọ tí kò máa dagbasoke, pàápàá jùlọ lẹhin ọpọlọpọ ọdun tí a ti bí ọmọ náà. Kò lé jẹ dídùn inú wa rárá kí ọmọ ọdún mẹwa má lè sọrọ tàbí rìn. Bẹẹ náà ni a ṣe rí níwájú Ọlọrun. Ọlọrun jẹ òbí tàbí bàbá wa nípa ti èmí gẹgẹ bí a ṣe ní baba nípa ti ara.
PETERU KINNI 1:23
[23]Bi a ti tun nyin bi, kì iṣe lati inu irú ti idibajẹ wá, bikoṣe eyiti ki idibajẹ, nipa ọ̀rọ Ọlọrun ti mbẹ lãye ti o si duro.
Nínú atunbi, a ti bí wa nípa ti Ọlọrun, èyí ló fàá tí a fi sọ wípé Ọlọrun ní bàbá wa nípa ti èmí. Kò tán sibẹ, dídùn inú Ọlọrun ni kí ìdàgbàsókè máa jẹyọ ninu Aye wa nípa ti èmí.
Ọlọrun, nínú ọrọ rẹ, ti fi ìlànà sílẹ fún wa bí a ṣe n dagbasoke nípa ti èmí di
PETERU KINNI 2:2
[2]Bi ọmọ-ọwọ titun, ki ẹ mã fẹ wàra ti Ẹmí na eyiti kò li ẹ̀tan, ki ẹnyin ki o le mã ti ipasẹ rẹ̀ dàgba si igbala,Bíbélì pé ọrọ Ọlọrun ní wàrà ti èmí. Ìdí èyí ni wípé nípa wàrà ni gbogbo awọn alumoni tó ṣe pàtàkì fún ara ọmọdé láti dàgbasoke wà. Bẹẹ náà ni ọrọ Ọlọrun rí. Nínú ọrọ Ọlọrun ni gbogbo awọn ohun tó ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsókè wà. Jésù náà ṣe amenuba èyí ni nínú ìdánwò rẹ.
MATIU 4:4
[4]Ṣugbọn o dahùn wipe, A ti kọwe rẹ̀ pe, Enia kì yio wà lãyè nipa akara nikan, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ ti o ti ẹnu Ọlọrun jade wá.Nínú ẹsẹ yìí, “akara” tumosi awọn ounjẹ nípa ti ara. Ohun tí ẹsẹ yìí n sọ fún wa náà ni wípé gẹgẹ bí onjẹ ṣe ṣe pàtàkì fún ara wa láti máa wà láàyè ati lati máa dagbasoke si, bẹẹ náà ni ọrọ Ọlọrun ṣe pàtàkì sí.