Ọjọ́ Kẹta (3), Ọjọ́ Ìsẹ́gun , Oṣù Kíní , Ọdún 2023

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ WA NIPA AAWẸ̀(3)

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ WA NIPA AAWẸ̀(3)


Ìgbà míràn wà ti a máa n gbèrò láti gba aawẹ̀lai sọ fún ọkọ tabi aya wa, pàápàá jùlọ fún àwa tí a bá wà nínú
ìgbéyàwó. Gẹgẹ bí ìdáhùn Paulu nínú Episteli rẹ sí àwọn ará Kọrinti èyí tí a gbé yẹwo ní àna, kìíse ìwà tó t’ọna
.
KỌRINTI KINNI 7:4-5
[4]Aya kò li agbara lori ara rẹ̀, bikoṣe ọkọ: bẹ̃gẹgẹ li ọkọ pẹlu kò si li agbara lori ara rẹ̀, bikoṣe aya.
[5]Ẹ máṣe fà sẹhin kuro lọdọ ara nyin, bikoṣe nipa ifimọṣọkan, ki ẹnyin ki o le fi ara nyin fun àwẹ ati adura; ki
ẹnyin ki o si tún jùmọ pade, ki Satani ki o máṣe dán nyin wò nitori aimaraduro nyin.


Ojúṣe ọkọ àti aya ni láti sunmọ ara wọn lórí ọrọ Ibalopọ. Ẹtọ ẹnikọọkan wọn ni nínú Olúwa nitoripe tí a bá ti
gbeyewo ara wa kìíse ara wa nikan mọ. Kìíse àwa nikan ni a ní àṣẹ tàbí ẹtọ lórí lílo eya ara wa mo nítorípé a ti
di ara kan náà.

EFESU 5:31
[31]Nitori eyi li ọkunrin yio ṣe fi baba ati iya rẹ̀silẹ, on o si dàpọ mọ́aya rẹ̀, awọn mejeji a si di ara kan.
Aawẹ̀gẹgẹ bíi lilo ara wa fún Oluwa jẹ okan nínú ohun tí a gbọdọ gba àṣẹ lọwọ enikeji wa, ọkọ tàbí aya wa,
kí a tó máa gùn le gbigba rẹ.


Ìdí tí a tún fi gbọdọ ṣe èyí ni wipe aawẹ̀kò niiṣe pẹlu kí ènìyàn kọ láti jẹun nìkan. Wipe ènìyàn takete sí ounjẹ
kò sọ wipe o n gba aawẹ̀. A tilẹ máa n rí àwọn tó máa n kọ jalẹ láti jẹun fún ọpọlọpọ ọjọ nítorípé wọn fi n fi
ehonun hàn sí ìjoba. A rí àwọn tí wọn máa n kọ láti jẹun nitoripe wọn ti tóbi ju nípa tí ara wọn sì mọ wipe èyí
kò dára fún ìlera ara wọn. Nitorinaa wipe ènìyàn kọ láti jẹun kò sọ wipe o n gba aawẹ̀. Aawẹ̀niiṣe pẹlu ọkàn
wa gẹgẹ bí onigbagbo. Nitorinaa, nínú aawẹ̀awọn nkan tí a fẹràn láti ṣe, awọn nkan ti a máa n gbadun rẹ ni a
o ṣẹ ara wa nípa rẹ fún ìgbà kan. Gẹgẹ bí a ti mọ, kìíse wipe awọn nkan náà jẹ ẹsẹ sugbọn awọn nkan tí kò níí
jẹ kí ọkàn wa wà nínú ádùrá láti lè dojukọ awọn nkan tí a torí rẹ gba aawẹ̀ni

DANIẸLI 10:2-3
[2]Li ọjọ wọnni li emi Danieli fi ikãnu ṣọ̀fọ li ọ̀sẹ mẹta gbako.
[3]Emi kò jẹ onjẹ ti o dara, bẹni kò si si ẹran tabi ọti ̃ -waini ti o wá si ẹnu mi, bẹli emi kò fi ororo kùn ara mi ̃
rara, titi ọ̀sẹ mẹta na fi pe.


Nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, Danieli fihàn wá nípa nkan tó takete sí nínú aawẹ̀rẹ. Kìíse wipe kò jẹ oúnjẹ kankan rárá
sugbon awọn nkan tó fẹràn gẹgẹ bí ẹnìkan ló takete sí láti lè gbàdúrà. Nitorina orisirisi ọna ní ènìyàn fi lè gbà
aawẹ̀ṣugbọn ohun tó gbọdọ ṣẹlẹ nínú gbogbo aawẹ̀ni wípé a n takete sí àwọn nkan tí ara wa n fẹ láti lè fi
ọkàn wa sínú adura.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading