Ọjọ́ Kejìlá (12), Ọjọ́bọ̀, Oṣù Kíní , Ọdún 2023

BI ỌLỌRUN ṢE N DARÍ ONIGBAGBỌ (4)

BI ỌLỌRUN ṢE N DARÍ ONIGBAGBỌ (4)


Labẹ Majẹmu Lailai, Èmi Ọlọrun kìíse ìdarí fún àwọn ènìyàn nípa bó ṣe n ṣe ìdarí fún wa labẹ Majẹmu Titun.
Ọna tí Ọlọrun n gbà darí wọn náà ni nípa wòlíì, awọn tí wọn máa n pè ní ariran nitoripe awọn ni Ọlọrun fi
amin òróró yan láti tu Èmi rẹ sí wọn lára. Nígbà tí a n sọ yìí náà kìíse wípé Èmi Ọlọrun kalẹ nínú wọn láti máa
fi ibẹ ṣe ibùgbé, O máa n bà lé wọn tí wọn bá fẹ jẹ iṣẹ iransẹ ni. Ṣugbọn nínú Majẹmu titun. Ọlọrun n fi ayé
onigbagbọ ṣe ibùgbé ni nitoripe èyí gan ni èròngbà Ọlọrun láti ibẹrẹ wá.


ISIKIẸLI 37:27
[27]Agọ mi yio wà pẹlu wọn: nitõtọ, emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nwọn o si jẹ enia mi.
Nínú Majẹmu Titun ni èyí tí wá sí imusẹ.


KỌRINTI KINNI 3:16
[16]Ẹnyin kò mọ̀pe tẹmpili Ọlọrun li ẹnyin iṣe, ati pe Ẹmí Ọlọrun ngbe inu nyin?


Nitorina onigbagbọ kò gbọdọ máa retí wípé nípa ẹlòmíràn nikan ni Ọlọrun yóò fi tọ wa sọnà nitoripe àwa náà
ti ní Èmi Mimọ. Ní wayii, ao ṣeéṣe kí a máa ro wipe bóyá a n sọ wípé labẹ Majẹmu Titun wípé Ọlọrun kò lè
rán ènìyàn sí wa mọ tàbí wípé kò sí iṣẹ iransẹ wòlíì mọ labẹ Majẹmu Titun. Kò rí bẹ́ẹ̀ràrá. Labẹ Majẹmu
Titun, iṣẹ iransẹ wòlíì wà lára àwọn ẹbùn iṣẹ iransẹ márùn tí Jésù fífún ìjọ rẹ.

EFESU 4:11
[11]O si ti fi awọn kan funni bi aposteli; ati awọn miran bi woli; ati awọn miran bi efangelisti, ati awọn miran
bi oluṣọ-agutan ati olukọni;


Ijọ Ọlọrun ni a fi awọn iṣẹ iransẹ yìí fún, a sì ri wipe iṣẹ iransẹ wòlíì wà lára wọn. Nitorina Ọlọrun sì ran àwọn
wòlíì sí onigbagbọ ṣugbọn iṣẹ wọn yàtọ. Iṣẹ iransẹ wòlíì labẹ Majẹmu Titun jẹ àsọtẹlẹ. Àsọtẹlẹ yìí niiṣe pẹlu
imunilokanle tàbí láti ràn wá lọwọ láti dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ.


KỌRINTI KINNI 14:3
[3]Ṣugbọn ẹniti nsọtẹlẹ mba awọn enia sọrọ fun imuduro, ati igbiyanju, ati itunu.


Nitorina iṣẹ iransẹ wòlíì sí wa kìíse pasiparo ojúṣe wa láti gba ìdarí láti ọwọ Èmi Mimọ. Ojúṣe wa ni láti gba
ìdarí láti ọwọ Ọlọrun. Ọlọrun lè lo àwọn wòlíì tàbí àwọn onígbàgbọ míràn láti ṣe ìfimuleẹ̀ohun tí a ti gbọ láti
ọdọ Ọlọrun. Àpẹẹrẹ èyí wà nínú iṣẹ iransẹ Paulu náà Ọlọrun sọ fún nípa ohun tí yóò dojukọ.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 20:23
[23]Bikoṣe bi Ẹmí Mimọ́ti nsọ ni ilu gbogbo pe, ìde on ìya mbẹ fun mi.


Lẹhin èyí, Ọlọrun fihan wòlíì kan ti orúkọ rẹ n jẹ Agabu.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 21:10-11
[10]Bi a si ti wà nibẹ̀li ọjọ pipọ, woli kan ti Judea sọkalẹ wá, ti a npè ni Agabu.
[11]Nigbati o si de ọdọ wa, o mu amure Paulu, o si de ara rẹ̀li ọwọ́on ẹsẹ, o si wipe, Bayi li Ẹmí Mimọ́wi,


Bayi li awọn Ju ti o wà ni Jerusalemu yio de ọkunrin ti o ni amure yi, nwọn o si fi i le awọn Keferi lọwọ.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading