Ọjọ́Kejì (2), Ọjọ́bọ̀, Oṣù Kejì , Ọdún 2023

IGBỌWỌLÈ ÀTI IṢẸ IRANSẸ (2)

IGBỌWỌLÈ ÀTI IṢẸ IRANSẸ (2)


Ní anaa, a n sọ wípé oore ọfẹ lè yatọ pàápàá jùlọ tí a bá n sọ nípa iṣẹ iransẹ. Lootọ kò sí ààbò Èmi Ọlọrun
nínú ẹni-kọọkan, bẹẹ sì ni gbogbo agbára tí Ọlọrun fífún Kristi náà ló fífún gbogbo àwa ọmọ rẹ nitoripe Kristi
n gbé inú wa nipasẹ Ẹmi Mimọ. Nígbàtí Jésù ṣe ìlérí agbára Èmí Mimọ, kò fi iyatọ sáàrin onigbagbọ kan sí
èkejì. Gbogbo awọn tó wà níbẹ nígbà náà ló ṣe ìlérí kan náà fún.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 1:8
[8]Ṣugbọn ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmí Mimọ́ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ni Jerusalemu, ati ni
gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ aiye.


Nígbàtí a mú ìlérí náà ṣẹ, gbogbo wọn patapata ló kún fún Èmí Mimọ láì yọ ẹnìkankan silẹ láàrin wọn.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 2:4
[4]Gbogbo nwọn si kún fun Ẹmí Mimọ́, nwọn si bẹ̀rẹ si ifi ède miran sọrọ, gẹgẹ bi Ẹmí ti fun wọn li ohùn.

Nitorina gbogbo agbára Èmí Mimọ ní Ọlọrun ti fi jinki onigbagbọ nínú rẹ. Ohun tó yàtọ ni ipè. Ipè ló máa fàá
tí àwọn irú Ifarahan agbára Ọlọrun fi máa n yatọ láàrin ènìyàn kan sí òmíràn. Èmi Mimọ ló máa n fi èyí tó bá
wu hàn nínú ayé onigbagbọ tàbí nínú iṣẹ iransẹ Òjíṣẹ Ọlọrun gẹgẹ bí o bá ti wù.


Onírúurú iṣẹ iransẹ ló wà.


EFESU 4:11
[11]O si ti fi awọn kan funni bi aposteli; ati awọn miran bi woli; ati awọn miran bi efangelisti, ati awọn miran
bi oluṣọ-agutan ati olukọni;


Láàrin ìjọ Ọlọrun ni awọn wọnyi ti máa n jẹyọ, bẹẹ sì ni nínú ìjọ Ọlọrun náà ni wọn ti máa n dagbasoke nínú
ayé Onigbagbọ.


KỌRINTI KINNI 12:28
[28]Ọlọrun si gbé awọn miran kalẹ ninu ijọ, ekini awọn aposteli, ekeji awọn woli, ẹkẹta awọn olukọni,
lẹhinna iṣẹ iyanu, lẹhinna ẹ̀bun imularada, iranlọwọ, ẹbùn akoso, onirũru ède.


Nitorina awọn ẹbun Èmi Mimọ máa n farahàn nínú iṣẹ iransẹ gẹgẹbi ipè tí Ọlọrun pe ẹni-kọọkan sí àti bí
Ọlọrun bá ṣe máa n lo ẹni-kọọkan.


KỌRINTI KINNI 12:11
[11]Ṣugbọn gbogbo wọnyi li ẹnikan nì, ani Ẹmí kanna nṣe, o npín fun olukuluku gẹgẹ bi o ti wù u.


Lootọ ẹbùn Èmi Mimọ tí yóò jẹyọ nínú ayé wa gẹgẹbi Kristẹni niiṣe pẹlu ipè tí Ọlọrun pè wá sí ṣugbọn àwa
náà ní ipa tí a gbọdọ ko níbẹ kí ipè wa tó farahàn sí àwọn ènìyàn wípé lootọ ni Ọlọrun pè wá. Kìíse wípé a o
káwó gbéra. Tó bá di ọla, a o tẹsiwaju nípa àwọn ìgbésẹ tó yẹ kí a gbé láti lè mọ iṣẹ iransẹ tí Ọlọrun pè wá sí
àti láti lè rìn nínú ìfẹ Ọlọrun nípa wọn.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading