Ọjọ́ Kejì (2), Ọjọ́ Ajé , Oṣù Kíní , Ọdún 2023

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ WA NIPA AAWẸ̀(2)


Kìíse ebi tó ní pa wá nígbà tí a bá gba aawe gaan lo se pataki nínú aawẹ̀nítorípé nínú aawẹ̀, a yẹra fún àwọn
nkan tí kìíse ẹsẹ sugbọn tí a nilo lati yẹra fún nítorípé a n fi ara wa ji fún Ọlọrun ní àkókò igba náà. Nitorina
ohun tí a n ṣe tí a bá n gba awẹ ṣe pàtàkì jù ebi tó n pa wá gan lọ. Nitorina tí a bá wo ohun ti a kò sínú Episteli
Paulu sí àwọn ará Kọrinti nípa aawẹ̀, yóò dá wa lójú wipe lootọ a tí takete sí àwọn nkan tí ara nilo ṣugbọn a
lo anfààní náà láti dojukọ awọn nkan tí a o máa ṣe nígbà náà.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ WA NIPA AAWẸ̀(2)

KỌRINTI KINNI 7:5
[5]Ẹ máṣe fà sẹhin kuro lọdọ ara nyin, bikoṣe nipa ifimọṣọkan, ki ẹnyin ki o le fi ara nyin fun àwẹ ati adura; ki
ẹnyin ki o si tún jùmọ pade, ki Satani ki o máṣe dán nyin wò nitori aimaraduro nyin.


Nínú ẹsẹ Bíbélì yii, a ri dajudaju wipe tí ọkọ àti aya bá takete sí ara wọn nígbà tí wọn gba aawẹ̀, ohun tó yẹ ki
wọn ṣe nígbà náà kìíse kí wọn máa retí wipe kí aago mẹfa tètè lu bikòṣe kí wọn fi ara wọn ji fún adura. Aawẹ̀
láìsí ádùrá asan ni, ebi lasan ni. Nítorí èyí ní ọpọlọpọ awọn ẹsẹ Bibeli tó tọkasi aawẹ̀, wọn máa sọ nípa ádùrá
náà nítorípé méjèèjì máa n lọ papọ ni.
A o ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Bíbélì tó fihàn wípe aawẹ̀àti adura máa ṣọrẹ ara wọn ni, aawẹ̀kìí dá dúró.

MATIU 17:21
[21]Ṣugbọn irú eyi ki ijade lọ bikoṣe nipa adura ati àwẹ̀.


Nínú ẹsẹ tí a tọkasi yìí, Jésù n sọ fún àwọn ọmọlẹyìn rẹ wipe ọna tí aigbagbọ fi lè kuro ninu ọkan wọn ni nípa
aawẹ̀àti ádùrá. Lẹẹkansi, ẹ jẹ kí a ṣakiyesi wipe kò sọ nípa aawẹ̀nìkan.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 13:2
[2]Bi nwọn si ti njọsìn fun Oluwa, ti nwọn si ngbàwẹ, Ẹmí Mimọ́wipe, Ẹ yà Barnaba on Saulu sọtọ̀fun mi fun
iṣẹ ti mo ti pè wọn si.


Bí wọn ṣe n jọsin fún Oluwa tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ niiṣe pẹlu ádùrá nítorípé ádùrá ajumogba ni ẹsẹ náà n tọkasi.
Èyí ni wipe awọn onigbagbo ti a tọkasi ni abala Bíbélì n gbàdúrà papọ, wọn n gba aawẹ̀papọ náà. Nitorina
wọn kò ṣe okan laiṣe èkejì.
Ẹ jẹ kí a tun ṣe àgbéyẹ̀wò ẹsẹ míràn.


LUKU 2:37
[37]O si ṣe opó ìwọn ọdún mẹrinlelọgọrin, ẹniti kò kuro ni tẹmpili, o si nfi àwẹ ati adura sìn Ọlọrun lọsán ati
loru.

Anna tó jẹ wòlíì ni ẹni tí a n sọ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, o n sìn Ọlọrun pẹlu aawẹ̀ati ádùrá. Nitorina ẹ maṣe jẹ kí a fi
aawẹ̀ṣofo. Nitorinà tí a bá pinnu wipe a fẹ gba aawẹ̀, ìbéèrè tí a o kọkọ béèrè lọwọ ara wa ni wípé njẹ a o ní
anfààní lati fi akoko silẹ láti gbàdúrà?

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading