Ọjọ́ Ogún (20), Ọjọ́ Ẹtì , Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

ṢÍṢE IṢẸ OLÚWA (2)

Nítorí àwọn Iya àìnípẹkun tó n dúró de awọn alaigbagbọ ni ìwàásù ihinrere Kristi ṣe ṣe pàtàkì lọpọlọpọ.
Ẹnikẹni tí kò bá gbagbọ nínú Kristi Jésù ti wà lábé ìdájọ Ọlọrun.


JOHANU 3:18
[18]Ẹniti o ba gbà a gbọ́, a ko ni da a lẹjọ; ṣugbọn a ti da ẹniti kò gbà a gbọ́lẹjọ na, nitoriti kò gbà orukọ Ọmọ
bíbi kanṣoṣo ti Ọlọrun gbọ́.


Tí a kò bá wàásù Kristi Jésù, pàápàá jùlọ kí a bẹrẹ láti ọdọ àwọn tó wà ní sàkání wa bí àwọn mọlẹbi, ọrẹ ará
àti ojúlùmò wa, a jẹ wipe ayérayé wọn kò já mọ nkankan fún wa nìyẹn. Bíbélì sọ wipe ayafi ti ẹnikẹni bá
gbagbọ ninu Kristi ló tó lè ní ìyè àìnípẹkun.


JOHANU 3:16
[16]Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹ̃gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rẹ̀kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́má bà
ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun.


Nítorí iya tó n dúró de alaigbagbọ, a kò gbọdọ̀fàsẹhin nínú iṣẹ ìwàásù ihinrere Kristi fún wọn. Kí àwọn ènìyàn
tó lè gbagbọ, wọn gbọdọ gbọ ọrọ Ọlọrun to niiṣe pẹlu ìgbàlà. Ọlọrun kìí déédé yí àwọn ènìyàn lọkàn padà.
Ènìyàn míràn eleran ara bíi tiwa náà ló máa n lo láti yí wọn lọkàn padà láti pe àkíyèsí wọn sí ìgbàlà tó wà nínú
Kristi. Nípa gbigbọ ọrọ Ọlọrun tí a bá wàásù fún wọn nikan ni wọn ṣe lè gbagbọ ninu Kristi Oluwa.

ROMU 10:17
[17]Njẹ nipa gbigbọ ni igbagbọ́ti iwá, ati gbigbọ nipa ọ̀rọ Ọlọrun.


Bí Ọlọrun ṣe ṣe agbekalẹ rẹ ni wipe ohun tí ènìyàn bá gbọ nìkan ló lè gbagbọ. Ìgbàgbọ niiṣe pẹlu Kí eniyan
gbọ ọrọ Ọlọrun. Nitorinà Ọlọrun n gbẹkẹle wa gẹgẹ bí ikọ̀àti ìríjú rẹ ní ayé yìí láti wàásù ìhìnrere rẹ láàrin
àwọn ènìyàn bíi tiwa.


JẸNẸSISI 18:19
[19]Nitoriti mo mọ̀ọ pe, on o fi aṣẹ fun awọn ọmọ rẹ̀ati fun awọn ara ile rẹ̀lẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o ma pa ọ̀na
OLUWA mọ́lati ṣe ododo ati idajọ; ki OLUWA ki o le mu ohun ti o ti sọ fun Abrahamu wá fun u.

Ohin tí a fẹ pe àkíyèsí wa sí nínú ẹsẹ Bíbélì yìí ni wipe Ọlọrun ri wipe Òun lè gbẹkẹle Abrahamu lati kọ awọn
ènìyàn ní ọnà rẹ, awọn ọmọ rẹ. Ìbéèrè tó yẹ kí olukuluku wa bi ara wa l’eere ni wipe Njẹ Ọlọrun lè gbẹkẹle
wa ni ibi tí a wà wipe a o wàásù ìhìnrere ti Kristi fún àwọn ènìyàn tó wà níbè?


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 18:9-10
[9]Oluwa si sọ fun Paulu li oru li ojuran pe, Má bẹ̀ru, sá mã sọ, má si ṣe pa ẹnu rẹ mọ:́
[10]Nitoriti emi wà pẹlu rẹ, kò si si ẹniti yio dide si ọ lati pa ọ lara: nitori mo li enia pipọ ni ilu yi.

Ọlọrun mọ iye àwọn tó ní ní ìlú kọọkan, nitorinà a gbọdọ béèrè lọwọ ara wa wipe njẹ mo wa lára àwọn tí
Ọlọrun n gbára lé ní ìlú yìí, nínú ilé iṣẹ yìí tàbí lórí ilẹ yìí, tàbí nínú mọlẹbi yìí, láti wàásù Ìhìnrere ti Kristi?

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading