Ọjọ́ Ogún (20), Ọjọ́ Ajé , Osù Kejì , Ọdún 2023

ORỤKỌ RẸ̀ NI OLÙGBÀLÀ

Ẹnikẹni tó bá nílò Olùgbàlà túmọ̀ sí wípé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ní ìsòro kan tàbí òmíràn. Nítorínáà tí a bá sọ wípé gbogbo aráyé ló nílò Olùgbàlà, ó túmọ̀ sí wípé gbogbo ènìyàn ní ó wà nínú ìsòrò kan nìyẹn. Bí ìsòro yìí bá jẹ́ àìrọ́mọbí ni, à jẹ́ wípé Jesu kìíse Olùgbàlà gbogbo aráyé nìyẹn nítorípé kìíse gbogbo ènìyàn náà ni kò rí ọmọ bí. Bị ìsòrō yìí bá jẹ́ tí àìlówólọ́wọ́ ni, a jẹ́ wípé Kristi kìíse Olùgbàlà gbogbo aráyé nìyẹn, nítorípé kìíse gbogbo ènìyàn náà ló jẹ́ tálákà. Nítorínáà, ó yẹ́ kí a béèrè wípé “Njẹ́ lóòótọ́ ní Kristi jẹ́ Olùgbàlà gbogbo aráyé?

Johanu Kinni 2:2
“On si ni ètutu fun ẹ̀ṣẹ wa: kì si iṣe fun tiwa nikan, ṢUGBỌN FUN TI GBOGBO ARAIYE PẸLU.”

A rí ka ní ibi yìí wípé ikú Jésù wà fún gbogbo aráyé. Ìdí rẹ̀ ni èyí tó fi sọ fún gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀ nígbàtí o jíǹde wípé kí wọ́n lọ wàásù ihinrere fun gbogbo ẹ̀dá alààyè. (Matiu 28:19). Bẹ́ẹ̀ náà ló tún sọ nínú Ìwé Marku 16:15 – “O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ si gbogbo aiye, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda”

Nítorípé Ìhìnrere rẹ̀ wà fún gbogbo ẹ̀dá, a jẹ́ wípé ìṣòro gbogbo ẹ̀dá tí Jesu gbani là kúrò nínú rẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀kan náà. Kíni ìsòro yìí ?

Romu 3:23

“Gbogbo enia li o sá ti ṣẹ̀, ti nwọn si kuna ogo Ọlọrun”

Ìyẹn ni wípé ẹ̀ṣẹ̀ ni ìsoro gbogbo aráyé. Èyí jẹ́ ohun tí kò yọ enikẹ́ni sílẹ̀ rárá. Báwo wa ni Ìhìnrere ti Jesu yóò se fi òpin sí ìsòro yìí? Ní ìwọn ìgbà ti gbogbo aráyé jẹ́ ẹlẹ́sẹ̀̀, ohun tó yẹ kí a mọ̀ nípa èyí ni wípé, kò sí ẹnikẹni tó lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ yìí bíkòṣe wípé ó rí ìdáríjì gbà. Ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ yìí náà ni ojúrere tí Ọlọrun fi hàn sí gbogbo ẹ̀dá nípa rírán ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi láti wá san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ náà.

Romu 5:8
“Ṣugbọn Ọlọrun fi ifẹ On papa si wa hàn ni eyi pe, nigbati awa jẹ ẹlẹṣẹ, Kristi kú fun wa.”

Nítorínáà, Kristi ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ẹni tí a bá ti san gbèsè rẹ̀ kìíse ajigbèsè mọ́. Ohun tí o kàn wá kù náà ni láti gbàgbọ́ wípé Ọlọrun tí tórí èyí fún wa ní ìdáríjì ̄ ẹ̀ṣẹ̀. Ìdí èyí ni Jesu se rán àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ jáde lọ láti máa se ìkéde fún gbogbo àyé wípé Ọlọrun tí fi ojú rere rẹ̀ hàn nípa ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.

Luku 24:47
“Ati ki a wasu ironupiwada ati idariji ẹ̀ṣẹ li orukọ rẹ̀, li orilẹ-ède gbogbo, bẹ̀rẹ lati Jerusalemu lọ” Ẹnikẹ́ni tó bá tí gbà Ìhìnrere yìí gbọ́ ti di ẹni ìgbàlà nìyẹn.
Romu 10:9

“Pe, bi iwọ ba fi ẹnu rẹ jẹwọ Jesu li Oluwa, ti iwọ si gbagbọ́ li ọkàn rẹ pe, Ọlọrun jí i dide kuro ninu okú, a o gbà ọ là”

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading