Ọjọ́ Ọgbọ̀n (30), Ọjọ́ Ajé , Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

ÀLÀYÉ ÌWÉ GALATIA L’ẸSẸẸSẸ (5)

Níbo ni Galatia gan? Awọn ẹkun ibi tí Paulu ti rìnrìn àjò kinni rẹ ni a n pè ní Galatia. Kìíse ìjọ kan péré ló wà
níbè, ọpọlọpọ awọn ijọ ni.


KỌRINTI KINNI 16:1
[1]NJẸ niti idawo fun awọn enia mimọ́, bi mo ti fi aṣẹ fun awọn ijọ Galatia, bẹ̃gẹgẹ ni ki ẹ ṣe.

Irú ẹkọ kan náà tí Paulu ṣe agbekalẹ rẹ nínú ìwé Rómù náà ló ṣe agbekalẹ rẹ nínú ìwé Galatia. Ọrọ nípa iṣẹ
òfin, òtítọ ihinrere Kristi àti jíjẹ olododo níwájú Ọlọrun.


Awuyewuye máa n wa láàrin àwọn onígbàgbọ nígbà náà nípa pípa òfin Mósè mọ. Ohun tó máa n fa
awuyewuye yìí ni wipe gbogbo awọn ti Ọlọrun lo láti ṣe agbekalẹ ìgbàgbọ Kristẹni jẹ Juu. Awọn Júù ní àṣà
tiwọn tẹlẹ kí wọn tó gbagbọ nínú Kristi. Nitorina awọn tí kìíse Júù máa n bèrè ìbéèrè nípa àwọn òfin àti wípé
bóyá wọn ní ojúṣe láti máa pa awọn òfin náà mọ gẹgẹ bí àwọn Júù ṣe máa n ṣe teletele.


Nítorínaa Paulu gẹgẹ bí Aposteli sí àwọn alaikọlà, èyí awọn tí kìíse Júù, máa n gbèrò láti fi ìdáhùn ati alayé
ìhìnrere ti Kristi sí àwọn ìbéèrè náà.


GALATIA 3:10
[10]Nitoripe iye awọn ti mbẹ ni ipa iṣẹ ofin mbẹ labẹ ègún: nitoriti a ti kọ ọ pe, Ifibu ni olukuluku ẹniti kò
duro ninu ohun gbogbo ti a kọ sinu iwe ofin lati mã ṣe wọn.

Bí èyí ṣe kàn wa ni wípé ipò tí àwọn alaikọlà wà nígbà náà ni àwa náà wà bayi gẹgẹ bí ẹni tí kìíse Júù. Nitorinà
awọn ìdáhùn tí Paulu fún àwọn ìbéèrè náà ló tọ́sí ọpọlọpọ awọn ibeere tí àwa náà lè ní nípa òtítọ ihinrere
Kristi.


Bí Paulu ṣe máa n dahùn ìbéèrè yìí ni láti lè fi dá wa lójú wípé Ọlọrun kìíse ojúsàájú ẹnikẹni, èyí ni wipe
Ọlọrun kò fi iyatọ sí àárín Júù àti àwa tí kìíse Júù, lootọ ọpọ àwọn ìwé tí a n lo nínú ìgbàgbọ Kristẹni jẹ ìwé tí
Ọlọrun fún àwọn tiise Juu láti ṣe àkọsílẹ rẹ.


GALATIA 3:24-26
[24]Nitorina ofin ti jẹ olukọni lati mu ni wá sọdọ Kristi, ki a le da wa lare nipa igbagbọ́.
[25]Ṣugbọn lẹhin igbati igbagbọ́ti de, awa kò si labẹ olukọni mọ́.
[26]Nitoripe ọmọ Ọlọrun ni gbogbo nyin, nipa igbagbọ́ninu Kristi Jesu.


Nípa ìgbàgbọ nínú Kristi, gbogbo wa ní ibasepọ pẹlu Ọlọrun nitoripe Ọlọrun kìíse ẹlẹyamẹya, kò fi iyatọ
sáàrin eniyan nítorí orile-ede tí wọn ti wá

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading