Ọjọ́ Kọkanlélogun (21), Ọjọ́Àbámẹ́ta, Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

ṢÍṢE IṢẸ OLÚWA (3)

Nígbà tí Jésù Olúwa wa jinde ohun tó sọ gbẹhin ṣe pàtàkì lọpọlọpọ, bẹẹ sì ni gbogbo awọn tó ṣe àkọsílẹ
ihinrere mérèèrin ṣe àkọsílẹ rẹ. Ẹ jẹ kí a ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí Jésù sọ ko tó gòkè re òrun.


MATIU 28:18-19
[18]Jesu si wá, o si sọ fun wọn, wipe, Gbogbo agbara li ọrun ati li aiye li a fifun mi.
[19]Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ́orilẹ-ède gbogbo, ki ẹ si ma baptisi wọn li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmí
Mimọ́:


Jésù sọ wípé a ti fún ohun ní gbogbo agbára láyé àti ní òrun. Ohun tí a lè rò gẹgẹ bí ènìyàn eleran ara ni wipe
lẹhin ìgba tí Kristi sọ wípé a ti fún òun ní agbára láyé àti ni orun, yíò fún wa ní ìgboyà wípé kí a mọ wipe kò sí
agbára kánkan, bóyá ti oso ni tàbí ajẹ́tó lè ní ipá lórí wa mọ. Lootọ agbára yìí kọja gbogbo ète tàbí ìmọ
satani àti àwọn èmi búburú oju òrun ṣugbọn kìíse òun tí Jésù tenumo ni èyí lẹhin ìgba tó ṣe ìkéde wípé a ti
fún òun ni agbára láyé àti lọrùn. Ó sọ nípa nitori agbára tí a ti fún òun náà kí wọn lọ sí gbogbo ayé láti lọ máa
wàásù ìhìnrere.


Ẹkọ pàtàkì tí a lè rí kọ nínú èyí ni wipe kìíse ẹnu lásán ni onigbagbọ fi máa n wàásù ìhìnrere ti Kristi. A ni lo
láti lo agbára Ọlọrun láti wàásù ìhìnrere rẹ. Nínú àkọsílẹ Marku náà, a rí bí Jésù ṣe sọrọ nípa àwọn nkán tí
yóò máa tẹlé onigbagbọ nitoripe ìgbàgbọ nínú rẹ àti ìwàásù ihinrere rẹ

MAKU 16:15-18
[15]O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ si gbogbo aiye, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda.
[16]Ẹniti o ba gbagbọ́, ti a ba si baptisi rẹ̀yio là; ṣugbọn ẹniti kò ba gbagbọ́yio jẹbi.
[17]Àmi wọnyi ni yio si ma ba awọn ti o gbagbọ́lọ; Li orukọ mi ni nwọn o ma lé awọn ẹmi èṣu jade; nwọn o si
ma fi ède titun sọ̀rọ;
[18]Nwọn o si ma gbé ejò lọwọ; bi nwọn ba si mu ohunkohun ti o li oró, kì yio pa wọn lara rara: nwọn o gbé
ọwọ́le awọn ọlọkunrun, ara wọn ó da.


Ara awọn ohun tó n mú iṣẹ ìwàásù Kristi láti ṣeéṣe fún onigbagbọ ni wipe agbára Ọlọrun n farahàn nipasẹ
ìwàásù ọrọ rẹ. Nigbati Paulu náà n kọ episteli rẹ sí àwọn ará Rómù, òun náà ṣe amenuba èyí níbè.

ROMU 1:16
[16]Nitori emi kò tiju ihinrere Kristi: nitori agbara Ọlọrun ni si igbala fun olukuluku ẹniti o gbagbọ́; fun Ju
ṣaju, ati fun Hellene pẹlu.


Paulu pe ihinrere Kristi ní agbára Ọlọrun fún ìgbàlà. A pe ihinrere yìí ní agbára Ọlọrun nitoripe kí a tó lè gba
ènìyàn là kúrò nínú ìparun, Ẹ jẹ kí a mọ wipe o ní agbára tó de ní igbèkun sínú ìparun. Nitorina nípa agbára
naa ni a ó fí gba ẹni náà kúrò nínú ìgbèkùn wá sínú ìgbàlà tó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading