Ọjọ́ Kọkanlélogun (21), Ọjọ́ Ìsẹ́gun , Osù Kejì , Ọdún 2023

ÀLÀYÉÌWÉGALATIAL’ẸŚẸẸSẸ(7)

Paulu jẹ ẹni tí a ṣe inúnibíni sí kó tó di onígbàgbọ nínú Kristi. Ìrírí nínú ẹsìn awọn Júù gẹgẹ bí ọmọ orilẹ-ede Israẹli àti ẹkọ tó kọ nínú ìwé àwọn wòlíì fihan wipe kìíse ọmọde nínú ẹsìn náà.

GALATIA 1:14
[14]Mo si ta ọpọlọpọ awọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ ninu isin awọn Ju larin awọn ara ilu mi, mo si ni itara lọpọlọpọ si ofin atọwọdọwọ awọn baba mi.

O wà lára àwọn tó n ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọ Ọlọrun nígbà tí kò tíì bá Kristi pàdé. Èyí n fihàn wípe kò sí bí ènìyàn ṣe lè burú tó tí Jésù Kristi kò lè yí irú ayé ẹni bẹẹ padà.
Ó wà níbè nígbà tí wọn n lẹ Stefani ní òkúta.

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 7:58-59
[58]Nwọn si wọ́ ọ sẹhin ode ilu, nwọn sọ ọ lí okuta: awọn ẹlẹri si fi aṣọ wọn lelẹ li ẹsẹ ọmọkunrin kan ti a npè ni Saulu.
[59]Nwọn sọ Stefanu li okuta, o si nképe Oluwa wipe, Jesu Oluwa, gbà ẹmí mi.

Ó ni ìtara láti gbé àwọn onígbàgbọ lọ sínú ide nitoripe o ro wipe o n ṣiṣe fún Ọlọrun nígbà náà.

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 9:1-2
[1]ṢUGBỌN Saulu, o nmí ẹmi ikilọ ati pipa sibẹ si awọn ọmọ-ẹhin Oluwa, o tọ̀ olori alufa lọ;
[2]O bẽre iwe lọwọ rẹ̀ si Damasku si awọn sinagogu pe, bi on ba ri ẹnikẹni ti mbẹ li Ọna yi, iba ṣe ọkunrin, tabi obinrin, ki on le mu wọn ni didè wá si Jerusalemu.

Nitorinà gbogbo awọn onigbagbọ ló mọ wipe eni tó korira awọn omolehin Kristi ló jẹ. Wọn tilẹ ṣọra fún gan láti darapọ mọ nínú ìgbàgbọ Kristẹni nígbà tó bá Jésù pàdé tán. Ohun tí a lè kọ gẹgẹ bí ẹkọ nínú ìyípadà tó bá Paulu ni wipe awọn nkán tí ènìyàn lè gbẹkẹle gẹgẹ bí ohun àmúyẹ ló gbé sí ẹgbẹ kan nígbà tó bá Jésù pàdé.

FILIPI 3:4-7
[4]Bi emi tikarami tilẹ ni igbẹkẹle ninu ara. Bi ẹnikẹni ba rò pe on ni igbẹkẹle ninu ara, temi tilẹ ju:
[5]Ẹniti a kọ nilà ni ijọ kẹjọ, lati inu kukuté Israeli wá, lati inu ẹ̀ya Benjamini, Heberu lati inu Heberu wá; niti ofin, Farisi li emi;
[6]Niti itara, emi nṣe inunibini si ijọ; niti ododo ti o wà ninu ofin, mo jẹ alailẹgan.
[7]Ṣugbọn ohunkohun ti o ti jasi ère fun mi, awọn ni mo ti kà si òfo nitori Kristi.
Gbogbo awọn nkan tí ènìyàn lè máa kà sí ohun àmúyẹ ló gbé sí ẹgbẹ kan nítorí ihinrere tí Kristi.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading