Ọjọ́ Kọkanlélọ́gbọ̀n (31), Ọjọ́ Ìsẹ́gun , Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

ÀLÀYÉ ÌWÉ GALATIA L’ẸSẸẸSẸ (6)

Gẹgẹ bí a ti sàlàyé ṣaaju wipe Júù ni gbogbo awọn tó kọ gbogbo ìwé tó wà nínú Bíbélì. Èyí máa n kọ ọpọlọpọ
lominu wípé bóyá ìgbàgbọ Kristẹni kan jẹ ẹsin awọn Júù ni, pàápàá jùlọ nítorípé gbogbo orilẹ-ède àti ẹyà náà
ni wọn ní ẹṣin ati awọn aṣa tiwọn. Satani máa n lo èyí láti fa ọkan awọn ti wọn rò wípé wọn jẹ ọjọgbọn ní ayé
yìí. Ẹ jẹ kí a mọ wipe ikú Jésù àti ihinrere tó wà fún wa pẹlu ìgbàlà ati ibasepọ pẹlu Ọlọrun ti a rí gbà nipasẹ
Jésù jẹ imusẹ ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún Abrahamu ẹni tí kìíse Júù gan fúnra rẹ.


JẸNẸSISI 12:2-3
[2]Emi o si sọ ọ di orilẹ-ède nla, emi o si busi I fun ọ, emi o si sọ orukọ rẹ di nla; ibukun ni iwọ o si jasi:
[3]Emi o bukun fun awọn ti nsúre fun ọ, ẹniti o nfi ọ ré li emi o si fi ré; ninu rẹ li a o ti bukun fun gbogbo idile
aiye.


Gbogbo ìdílé ayé kìíse orilẹ ede kan ṣugbọn gbogbo ènìyàn pátápátá. Ìdí èyí ni Episteli sí àwọn ará Rómù
fihan wá wipe nígbàtí Ọlọrun dá Abrahamu laré gẹgẹ bí àpẹẹrẹ bí yóò ṣe dá ẹnikẹni tó bá gbagbọ ninu Kristi
laré , a kò tíì kọ Abrahamu ní ìlà nígbà náà.


ROMU 4:9-10
[9]Ibukún yi ha jẹ ti awọn akọla nikan ni, tabi ti awọn alaikọla pẹlu? Nitoriti a wipe, a kà igbagbọ́fun
Abrahamu si ododo.
[10]Bawo li a ha kà a si i? nigbati o wà ni ikọla tabi li aikọla? Kì iṣe ni ikọla, ṣugbọn li aikọla ni.
Ìbí ti Episteli yìí n tọkasi ni akọsilẹ Mósè


JẸNẸSISI 15:6
[6]O si gba OLUWA gbọ́; on si kà a si fun u li ododo.
Bí Kristi ti wá láti inú irú ọmọ Abrahamu jẹ imusẹ ìlérí Ọlọrun, nitoripe ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún Abrahamu niiṣe
pẹlu Kristi Jésù Oluwa wa.


GALATIA 3:8-9
[8]Bi iwe-mimọ́si ti ri I tẹlẹ pe, Ọlọrun yio dá awọn Keferi lare nipa igbagbọ́, o ti wasu ihinrere ṣaju fun
Abrahamu, o nwipe, Ninu rẹ li a o bukún fun gbogbo orilẹ-ède.
[9]Gẹgẹ bẹ̃li awọn ti iṣe ti igbagbọ́jẹ ẹni alabukún-fun pẹlu Abrahamu olododo.


Nitorinà kìíse fún ẹyà kan ni ìlérí náà wà fún sùgbón ohun tó jẹ Pataki ẹyà Júù, tàbí àwọn tí a n pè ní ikọla ni
wipe nipasẹ wọn ni Jésù Olúwa gbà wá. Nitorinà awọn ló wà ní sàkání wọn nígbà náà àti wípé àwon iwé
awọn wòlíì wọn ni a fi ṣàlàyé ìgbàlà tó wà nínú Kristi.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading