Ọjọ́ Kọkànlá (11), Ọjọ́rú , Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

BI ỌLỌRUN ṢE N DARÍ ONIGBAGBỌ (3)

BI ỌLỌRUN ṢE N DARÍ ONIGBAGBỌ (3)


Labẹ Majẹmu Titun, ara ìlérí Ọlọrun ni wipe awọn nkan tó niiṣe pẹlu Èmi Ọlọrun kò níí ṣe àjèjì sí wa. Èyí ni
wipe awọn nkan Èmi Ọlọrun yóò máa ṣẹlẹ nínú ayé wa àti nínú iṣẹ iransẹ wa daradara. Èyí kò sì yọ ẹnìkankan
silẹ láti ìgbà tí Ọlọrun ti tú Èmi Mimọ rẹ jáde sára eniyan gbogbo, awọn onigbagbọ. Pétérù ṣe amenuba èyí
nínú ìwàásù rẹ ní ọjọ Pentikosti. Ó tọkasi àsọtẹlẹ lati ẹnu wòlíì Joeli tí Ọlọrun ti ṣe ìlérí rẹ.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 2:16-18
[16]Ṣugbọn eyi li ọ̀rọ ti a ti sọ lati ẹnu woli Joeli wá pe;
[17]Ọlọrun wipe, Yio si ṣe ni ikẹhin ọjọ, Emi o tú ninu Ẹmí mi jade sara enia gbogbo: ati awọn ọmọ nyinọkunrin ati awọn ọmọ nyin obinrin yio ma sọtẹlẹ, awọn ọdọmọkunrin nyin yio si ma ri iran, awọn arugbo nyin
yio si ma lá alá:
[18]Ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi ọkunrin, ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi obinrin li emi o tú ninu Ẹmí mi jade li ọjọ
wọnni; nwọn o si ma sọtẹlẹ:


Tí a bá ṣe ayẹwo fínífíní nipa abala Bíbélì yìí, a o ri wipe kò yọ ẹnìkankan silẹ. O darukọ ọmọde àti àgbà àti
ọkùnrin àti obìnrin, àti ẹrù àti òmìnira. Èyí ni wipe Ọlọrun kìíse ojúsàájú nípa àwọn nkan tó niiṣe pẹlu Èmi rẹ.
Gbogbo ẹnikẹni tó bá ti gbagbọ ninu Kristi ló wà fún. Nígbà tí Èmi Mimọ Sọkalẹ ní ọjọ Pentikosti, mélòó nínú
wọn ló kún fún Èmí Mimọ nígbà náà?


Tí a bá padà lọ sí ẹsẹ Kejì ati ìkẹta, a o lè dáhùn ìbéèrè yií.

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 2:2-3
[2]Lojijì iró si ti ọrun wá, gẹgẹ bi iró ẹ̀fũfu lile, o si kún gbogbo ile nibiti nwọn gbé joko.
[3]Ẹla ahọn bi ti iná si yọ si wọn, o pin ara rẹ̀o si bà le olukuluku wọn.


Njẹ a ṣakiyesi wípé ẹsẹ Kejì sọ wípé “gbogbo ilé” ẹsẹ kẹta sọ wípé “olukuluku wọn”. Nitorina kò bá ìfẹ Ọlọrun
mu kí a máa ro wipe bóyá awọn kan wà tí Ọlọrun fẹ láti yọ silẹ. Rárá àti rárá kìíse ìfẹ rẹ nítorípé níní Èmi
Mimọ kìíse ohun tó niiṣe pẹlu ipè, O niiṣe pẹlu wípé a tí di ọmọ Ọlọrun ni. Lẹhin ìgba ti a ti di ọmọ Ọlọrun,
kìíse iyalẹnu kí bàbá wa ṣe ìdarí fún wa. Ọlọrun kìíse ojúsàájú ènìyàn.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 10:34
[34]Peteru si yà ẹnu rẹ̀, o si wipe, Nitõtọ mo woye pe, Ọlọrun kì iṣe ojuṣaju enia:
Ìdí tó fi yẹ kí a mọ wipe ifẹ Ọlọrun ni láti ṣe ìdarí fún wa ni wípé tí a kò bá retí ìdarí yìí láti ọdọ Ọlọrun, nígbà tí
Ọlọrun bá n darí wa, a kò níí mọ wipe ìdarí Ọlọrun ni nitoripe kìíse nkan tí a n retí.


Ohun tí a tún fẹ pe àkíyèsí wa sí lónìí ni wipe nínú Èmi ni Ọlọrun máa n darí ènìyàn. Ọpọlọpọ wà tí wọn má n
retí ìdarí nípa kí Ọlọrun sọrọ sí wọn létí nípa ti ara. Ẹ jẹ kí a mọ dájúdájú wípé Èmi ní Ọlọrun nitorinaa nínú
Èmi náà ni yóò gba ṣe ìdarí fún wa.


JOHANU 4:24
[24]Ẹmí li Ọlọrun: awọn ẹniti nsìn i ko le ṣe alaisìn i li ẹmí ati li otitọ.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading