Ọjọ́ Kọkànlá (11), Ọjọ́ Àbámẹ́ta, Oṣù Kejì , Ọdún 2023

KRISTẸNI GẸGẸ BÍ IMỌLẸ (4)

KRISTẸNI GẸGẸ BÍ IMỌLẸ (4)


Episteli Jòhánù Olufẹ jẹ ibi tí àlàyé nípa ìfẹ Ọlọrun nínú ayé onigbagbo ti wọpọ julọ. Tí a bá sakiyesi daradara,
Johannu sàlàyé ririn nínú ìfẹ gẹgẹ bí ifarahan ẹni tí a jẹ nínú Kristi. Ìjọba Kristi, ìjọba imọlẹ ni, bẹẹ náà, ìjọba
ìfẹ ni. Ẹni tí kò bá mọ nípa ìfẹ ko tíì bá Kristi pàdé.


Ádùrá kan wà tí Kristi gba ko tó lọ sórí igi agbelebu.


JOHANU 17:21
[21]Ki gbogbo nwọn ki o le jẹ ọ̀kan; gẹgẹ bi iwọ, Baba, ti jẹ ninu mi, ati emi ninu rẹ, ki awọn pẹlu ki o le jẹ
ọ̀kan ninu wa: ki aiye ki o le gbagbọ́pe, iwọ li o rán mi.


Tí a kò bá ṣe ayẹwo àbala Bíbélì yìí daradara, a lè rò wipe boya irẹpọ láàrin àwa arakunrin àti arábìnrin nínú
Oluwa nikan ló n sọ nínú ádùrá rẹ. Jésù n sọ nípa ibaṣepọ rẹ pẹlu Ọlọrun. O tún n gbàdúrà nípa wipe bí òun
ṣe jẹ ọkan pẹlu Ọlọrun bẹẹ náà ló fẹ kí àwa náà jẹ ọkan pẹlu Ọlọrun, èyí ni láti ní idapọ pẹlu Ọlọrun. Ádùrá yìí
wá sí imusẹ lẹhin àjínde rẹ. Ẹnikẹni tó bá ti gbagbọ nínú rẹ di okan pẹlu rẹ. Èyí ni wipe o ti ní idapọ pẹlu
Ọlọrun. A rí èyí nínú Episteli sí àwọn ará Kọrinti.


KỌRINTI KINNI 1:9
[9]Olododo li Ọlọrun, nipasẹ ẹniti a pè nyin sinu ìdapọ Ọmọ rẹ̀Jesu Kristi Oluwa wa. Bíbélì kò sọ wipe “ypp
pè wá “. “O ti pe wá “ ló sọ. Èyí ni nkan tó ti ṣẹlẹ ní iwọn ìgbà tí ènìyàn bá ti di atunbi. Nitorina onigbagbo ni
idapọ pẹlu Ọlọrun.


Ní wayi, Bíbélì sọ fún wa wípé a kò lè rìn nínú okunkun tó bá jẹ wipe lootọ ni a ti ni idapọ pẹlu Ọlọrun.


JOHANU KINNI 1:6
[6]Bi awa ba wipe awa ní ìdapọ pẹlu rẹ̀, ti awa si nrìn ninu òkunkun, awa nṣeke, awa kò si ṣe otitọ:
Nitorina, amin wipe onigbagbo ní idapọ, tàbí jẹ ọkan pẹlu Ọlọrun ni wipe a n rìn nínú imọlẹ. Tí a bá ka
episteli Johannu siwaju, o sàlàyé ìtùmò kí ènìyàn máa rìn nínú imọlẹ.


JOHANU KINNI 2:9
[9]Ẹniti o ba wipe on mbẹ ninu imọlẹ, ti o si korira arakunrin rẹ̀, o mbẹ ninu òkunkun titi fi di isisiyi

Jòhánù n sàlàyé wípé ẹnikẹni tó bá korira arakunrin rẹ wà nínú okunkun sibẹ. Nitorinà rírìn nínú irú ìfẹ
Kristi, tí kò fi bẹẹ fa ọgbọn yọ níwájú ènìyàn ni ìfihàn wípé a wà nínú imọlẹ. Rinrin nínú imọlẹ yìí ni ló n fi ẹni
tí a jẹ ní tòótọ hàn.


EFESU 5:13
[13]Ṣugbọn ohun gbogbo ti a mba wi ni imọlẹ ifi han: nitori ohunkohun ti o ba fi nkan hàn, imọlẹ ni.
Imọlẹ máa n fi nkan hàn ni. Ìfẹ ló n wá hàn wípé lootọ ni a jẹ ọmọ Ọlọrun

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading