Ọjọ́ Kọkàndínlógún (19), Ọjọ́bọ̀, Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

ṢÍṢE IṢẸ OLÚWA (1)

Nítorípé a jẹ ẹyà ara Kristi, gbogbo wa pátápátá ni a ni iṣẹ tó yẹ kí a máa ṣe nínú eya ara rẹ. Gẹgẹ bí ènìyàn
náà, a ní àwọn ẹyà ara, bẹẹ sì ni gbogbo eya ara wa máa n ní iṣẹ tí ọkọọkan máa n ṣe nínú ara wa. Tí ẹyà kan
bá wà tí kò ṣiṣe, a o ri wipe inú wa kò lè dun sí ẹyà náà, bẹẹ sì ni a o máa wá gbogbo ọnà láti lè ri wipe a gba
iwosan, èyí tíí se ìmúláradá fún ẹyà ara náà. Bẹẹ náà ni ti Kristi Jésù Oluwa wa rí.


KỌRINTI KINNI 12:27-29
[27]Njẹ ara Kristi li ẹnyin iṣe, olukuluku nyin si jẹ ẹ̀ya ara rẹ̀.
[28]Ọlọrun si gbé awọn miran kalẹ ninu ijọ, ekini awọn aposteli, ekeji awọn woli, ẹkẹta awọn olukọni,
lẹhinna iṣẹ iyanu, lẹhinna ẹ̀bun imularada, iranlọwọ, ẹbùn akoso, onirũru ède.
[29]Gbogbo wọn ni iṣe aposteli bi? gbogbo wọn ni iṣe woli bi? gbogbo wọn ni iṣe olukọni bi? gbogbo wọn ni
iṣe iṣẹ iyanu bi?


Nígbàtí Bíbélì sọ nípa wipe a jẹ ẹyà ara Kristi, ohun tí Bíbélì n tọkasi ni awọn iṣẹ tí Ọlọrun ti ti gbé fún wa.
Nitorina ko sí ẹyà ara Kristi kan tí kò ní iṣẹ tó n ṣe nínú ara Kristi, nínú ara Kristi ni gbogbo àwa onigbagbo wa


Njẹ a mọ wipe lootọ iṣẹ yàtọ tí ẹyà ara kọọkan n ṣe nínú ara sùgbón ìdí tí wọn fí n ṣe iṣẹ ati ogun tí wọn n ṣe
iṣẹ fún bákannáà ni. Ohun tí orí fẹ ní gbogbo ẹyà ara máa n ṣe, kò sí ẹyà ara kánkan tó n gba àṣẹ lọwọ ẹyà
ara míràn àyàfi lọwọ orí ara. Bẹẹ náà ni ara Kristi jẹ, gbogbo ẹyà ara Kristi ti gba àṣẹ láti ọwọ Kristi nítorípé o
ní ìdí tí Kristi funrararẹ fi wá.

MATIU 1:21
[21]Yio si bí ọmọkunrin kan, Jesu ni iwọ o pè orukọ rẹ̀: nitori on ni yio gbà awọn enia rẹ̀là kuro ninu ẹ̀ṣẹ
wọn.


Jésù wá láti gba àwọn èèyàn là kuro nínú ẹsẹ àti aiṣedede won ni. Nkan tó gbé lé àwa náà lọwọ nìyẹn.


LUKU 19:10
[10]Nitori Ọmọ-enia de lati wá awọn ti o nù kiri, ati lati gbà wọn là.


Nítorínáà ohun tí iṣẹ Olúwa túmọ̀sí ni wipe kí a máa ṣe laalaa àti akitiyan tó niiṣe pẹlu ìgbàlà ọkan awọn
ènìyàn. Ohun tí Ọlọrun n retí láti ọdọ wa ni èyí gẹgẹ bí ẹyà ara Kristi ní tòótọ.


Tí a bá n ṣe èyí, a o rí wipe ìgbà yìí gan ni a n dúró nínú ìfẹ Ọlọrun nítorípé ìfẹ Ọlọrun ni kí àwọn ènìyàn lè wá
sí òye ìgbàlà tó wà nínú Kristi.


TIMOTI KINNI 2:4
[4]Ẹniti o nfẹ ki gbogbo enia ni igbala ki nwọn si wá sinu ìmọ otitọ

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading