Ọjọ́ Kọkàndínlógún (19), Ọjọ́ Àìkú , Osù Kejì , Ọdún 2023

KRISTẸNI GẸGẸ BÍ IMỌLẸ (12)

Tí ènìyàn bá n rìn nínú ìfẹ kíni àwọn nkan tí yóò máa farahàn nínú ayé rẹ?

ROMU 12:9-10
[9]Ki ifẹ ki o wà li aiṣẹtan. Ẹ mã takéte si ohun ti iṣe buburu; ẹ faramọ́ ohun ti iṣe rere.
[10]Niti ifẹ ará, ẹ mã fi iyọ́nu fẹran ara nyin: niti ọlá, ẹ mã fi ẹnikeji nyin ṣaju.
Ìfẹ yóò jẹ kí a máa fi ti ẹnìkejì ṣáájú. Ìfẹ yóò jẹ kí a yọnu sí àwọn míràn gẹgẹ bí Ọlọrun ti yọnu sí àwa náà.

A kò níí máa dúró de wípé àwon kan yóò kọkọ fi ìfẹ hàn sí wa. Awọn gan ni a o kọkọ máa fi ìfẹ hàn sí àwọn ènìyàn nitoripe bí ìfẹ ti Kristi ṣe rí gan ni èyí.

JOHANU KINNI 4:10
[10]Ninu eyi ni ifẹ wà, kì iṣe pe awa fẹ Ọlọrun, ṣugbọn on fẹ wa, o si rán Ọmọ rẹ̀ lati jẹ ètutu fun ẹ̀ṣẹ wa.

Bó ti wulẹ kí a ro wipe a fẹràn Ọlọrun tó, kìíse àwa ni a kọkọ fẹràn rẹ, òun ló kọkọ fẹràn wa. Bẹẹ náà ló ṣe yẹ kí awa onigbagbọ rí. A gbọdọ ní ìtara láti fẹràn ọmọnikeji. Ìdí èyí ló fí jẹ wípé nínú gbogbo nkan tí Kristi kọ́ gẹgẹ bí ẹkọ fún àwọn ọmọlẹyìn rẹ, ọkan péré nínú rẹ ló pè ní òfin, òun náà sì ni ifẹ sí ọmọnikeji. Tí a bá wo ohun tí Paulu náà sọ fún àwọn ará Kọrinti gẹgẹ bí ojútùú sí gbogbo aawọ tó wà láàrin wọn, ìfẹ náà ni.

KỌRINTI KINNI 13:4-8
[4]Ifẹ a mã mu suru, a si mã ṣeun; ifẹ kì iṣe ilara; ifẹ kì isọrọ igberaga, kì ifẹ̀,
[5]Kì ihuwa aitọ́, kì iwá ohun ti ara rẹ̀, a kì imu u binu, bẹ̃ni kì igbiro ohun buburu;
[6]Kì iyọ̀ si aiṣododo, ṣugbọn a mã yọ̀ ninu otitọ;
[7]A mã farada ohun gbogbo, a mã gbà ohun gbogbo gbọ́, a mã reti ohun gbogbo, a mã fàiyarán ohun gbogbo.
[8]Ifẹ kì iyẹ̀ lai: ṣugbọn biobaṣepe isọtẹlẹ ni, nwọn ó dopin; biobaṣepe ẹ̀bun ahọn ni, nwọn ó dakẹ; biobaṣepe ìmọ ni, yio di asan.

Tí a bá wo ìjọ Kọrinti yìí daradara ìjà wà láàrin wọn, ẹsẹ àti darudapo wà nínú ìjọ wọn, sibẹsibẹ ohun tí Paulu kọ sí wọn gẹgẹ bí ojútùú náà ni kí won ma rìn nínú ìfẹ nitoripe ife ló lè yanjú awọn iṣẹ tí ara. Tí a bá n ṣe àríyànjiyàn nípa igi tí ẹnìkan sọ wípé ìgi báyìí ni, tí ẹlòmíràn sọ wípé rárá ìgi tòhún ni, tí èso rẹ bá tí farahàn, àríyànjiyàn parí nìyẹn nítorípé èso ni Ifarahan iseda igi. Ìdí èyí ni Paulu fi pe ìfẹ ní èso ti Ẹmi. Jésù náà sì sọ wípé ní iwọn tí a bá ti sọ wá di rere èso wa náà yóò di rere.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading