Ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n (29), Ọjọ́ Àìkú , Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

ÀLÀYÉ ÌWÉ GALATIA L’ẸSẸẸSẸ (4)

Ó ṣe pàtàkì kí a mọ awọn tí a kọ ìwé Galatia sí. Júù ló pọ jù láàrín wọn gẹgẹ bi itan ti sọ. Awọn Júù tí a fọn
káàkiri nítorí ọrọ ajé lo wà níbẹ


PETERU KINNI 1:1
[1]PETERU, Aposteli Jesu Kristi, si awọn ayanfẹ ti nṣe atipo ti nwọn tuka kiri si Pontu, Galatia, Kappadokia,
Asia, ati Bitinia,


Awọn ohun tí Paulu torí rẹ kọ ìwé náà ni láti ṣe àtúnṣe àwọn ẹkọ òdì nitoripe awọn kan wà láàrin wọn tí wọn
tún ni gba awọn ènìyàn niyanju láti máa ṣe atẹle òfin Mósè lẹhin ìgba tí wọn tí di onígbàgbọ. Ìdí rẹ ló fi jẹ
wípé tí a bá ka ìwé yìí, O fẹ dàbí ìgbà wípé ìbínú ni Paulu fí kọ.


Awọn nkan wà tí a lè tọkasi nínú ìwé yìí tó fihàn wípe ọrọ tó ṣe pàtàkì ni Paulu n kọ sínú lẹta yìí.
Èkíní, Gbogbo lẹta rẹ ló máa gbàdúrà kó tó bẹrẹ rẹ. Èyí ni wipe O máa n sọ nípa ádùrá tó n gbà fún àwọn tó n
kọ lẹta sí, èyí yatọ patapata nínú ìwé Galatia. Àpẹẹrẹ irú ádùrá tí Paulu máa n gbà fún àwọn ọmọlẹyìn rẹ ni a
rí nínú ìwé Efesu.


EFESU 1:17-18
[17]Pe ki Ọlọrun Jesu Kristi Oluwa wa, Baba ogo, le fun nyin li Ẹmi nipa ti ọgbọ́n ati ti ifihan ninu ìmọ rẹ̀:
[18]Ki oju ọkàn nyin le mọlẹ; ki ẹnyin ki o le mọ ohun ti ireti ìpe rẹ̀jẹ, ati ohun ti ọrọ̀ogo ini rẹ̀ninu awọn
enia mimọ́jẹ,


Kìíse bẹẹ nìkan, o pè wọn ní alainironu náà.


GALATIA 3:1
[1]ẸNYIN alaironu ara Galatia, tani ha tàn nyin jẹ, ki ẹnyin ki o máṣe gbà otitọ gbọ́, li oju ẹniti a fi Jesu Kristi
hàn gbangba lãrin nyin li ẹniti a kàn mọ agbelebu.


Ní ọpọlọpọ ìgbà, Paulu máa n sọ awọn nkan tí àwọn ẹlòmíràn máa n ba kọwe nípa rẹ ní. Ṣugbọn ní ti àwọn
ará Galatia, O fi ọwọ ara rẹ kọwe sí wọn ni. Nítorínaa ọwọ Paulu gan funrararẹ ni a fi kọ episteli sí àwọn ará
Galatia láti jẹ kí a mọ bí nkan tí a kọ sibẹ ṣe ṣe pàtàkì tó. Ìdí èyí ló fi pe àkíyèsí wọn sì.

GALATIA 6:11
[11]Ẹ wò bi mo ti fi ọwọ ara mi kọwe gàdàgbà-gàdàgbà si nyin.


Ohun míràn to tún tọkasi pàtàkì ẹkọ tó wà nínú Episteli sí àwọn ará Galatia ni wipe egún wà níbè, pàápàá
jùlọ fún àwọn tó n yí òtítọ ihinrere Kristi padà


GALATIA 1:8
[8]Ṣugbọn bi o ṣe awa ni, tabi angẹli kan lati ọrun wá, li o ba wasu ihinrere miran fun nyin ju eyiti a ti wasu
fun nyin lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading