Ọjọ́ ́Kíní (1), Ọjọ́rú , Oṣù Kejì , Ọdún 2023

IGBỌWỌLÈ ÀTI IṢẸ IRANSẸ (1)

IGBỌWỌLÈ ÀTI IṢẸ IRANSẸ (1)

Ọkan nínú àwọn nkan tí ìjọ Ọlọrun máa n ṣe julọ nínú ìgbàgbọ Kristẹni ni igbọwọlè, èyí wà lára àwọn ìpìlẹ ẹkọ
tí a tọkasi nínú ìwé Hébérù.


HEBERU 6:1-2
[1]NITORINA ki a fi ipilẹṣẹ ẹkọ́Kristi silẹ, ki a lọ si pipé; li aitún fi ipilẹ ironupiwada kuro ninu okú iṣẹ lelẹ, ati ti
igbagbọ́sipa ti Ọlọrun,
[2]Ati ti ẹkọ́ti iwẹnu, ati ti igbọwọle-ni, ati ti ajinde okú, ati ti idajọ ainipẹkun.


Ọpọlọpọ awọn nkan ni a maa n lo igbọwọlè fún ninu igbagbọ wa. Ní akọkọ òòrè ọfẹ tí ẹni-kọọkan ní àti ìpele
tí ẹni-kọọkan wà nínú iṣẹ iransẹ yatọ sí ara. Nitorina awọn ẹbun èmi àti agbára nípa ti ẹmi tí a fi jinki wa
bákannáà lórí nítorípé gbogbo wa ni a ní èmi Mimọ ṣugbọn bí Olórun ti n lo wa yatọ sí ara wọn. Agbára àti
àmín òróró tí a ti rìn nínú rẹ yatọ sí ara wọn. Ipè wa yatọ sí ara wọn. Nitorina tí a bá sọ wípé òòrè ọfẹ yatọ sí
ara wọn, kìíse òòrè ọfẹ tó n mú ìgbàlà wá ni a n sọ bikòṣe òòrè ọfẹ tí a n pè ní àmín òróró. Fún àpẹẹrẹ ẹ je kí
a wo òòrè ọfẹ tó niiṣe pẹlu ìgbàlà.


TITU 2:11
[11]Nitori ore-ọfẹ Ọlọrun ti nmu igbala fun gbogbo enia wá ti farahan,
EFESU 2:8
[8]Nitori ore-ọfẹ li a ti fi gbà nyin là nipa igbagbọ́; ati eyini kì iṣe ti ẹnyin tikaranyin: ẹ̀bun Ọlọrun ni:
Ṣugbọn kìíse gbogbo nkan ti a n pè ní òòrè ọfẹ nìyẹn.

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 4:33
[33]Agbara nla li awọn aposteli si fi njẹri ajinde Jesu Oluwa; ore-ọfẹ pipọ si wà lori gbogbo wọn.


Òòrè ọfẹ tí a n sọ nínú ẹsẹ yìí kìíse ohun tó niiṣe pẹlu ìgbàlà ṣugbọn ohun tó niiṣe pẹlu agbára. Ìdí tí a fi n péé
ní oore ofe kìíse wípé gbogbo ènìyàn ló ní èyí ṣugbọn nitoripe láti ọdọ Ọlọrun ló ti wá.
Paulu ṣe amenuba èyí náà nígbà tó n kọ lẹta rẹ sí àwọn ará Rómù.


ROMU 1:5
[5]Lati ọdọ ẹniti awa ri ore-ọfẹ ati iṣẹ aposteli gbà, fun igbọràn igbagbọ́lãrin gbogbo orilẹ-ède, nitori orukọ
rẹ̀:


Nínú ibi kíkà yìí, O n sọrọ nípa ipè iṣẹ iransẹ rẹ, Ó sì pèé ní òòrè ọfẹ. Nitorinaa ipè sí iṣẹ iransẹ rẹ, oore ọfẹ tó
n ṣe amenuba rẹ nínú ìbí kìíse èyí tó wà fún gbogbo ènìyàn. O tilẹ sọ fún àwọn ará Galatia wípé òòrè ọfẹ yìí a
fífún òun ni yatọ sí àwọn Aposteli yòókù.


GALATIA 2:9
[9]Ati nigbati Jakọbu, ati Kefa, ati Johanu, awọn ẹniti o dabi ọwọ̀n, woye ore-ọfẹ ti a fifun mi, nwọn si fi ọwọ́
ọtún ìdapọ fun emi ati Barnaba, pe ki awa ki o mã lọ sọdọ awọn Keferi, ati awọn sọdọ awọn onila.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading