Ọjọ́ Kẹwàá (10), Ọjọ́ Ìsẹ́gun , Oṣù Kíní , Ọdún 2023

BI ỌLỌRUN ṢE N DARÍ ONIGBAGBỌ (2)


Ohun Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹyìn rẹ tọ sí àwa náà gẹgẹ bí onigbagbọ nínú rẹ.

BI ỌLỌRUN ṢE N DARÍ ONIGBAGBỌ (2)


JOHANU 10:27
[27]Awọn agutan mi ngbọ ohùn mi, emi si mọ̀wọn, nwọn a si ma tọ̀mi lẹhin:


Ní iwọn ìgbà ti a jẹ àgùntàn nínú agbo rẹ, a jẹ wípé yóò bá wa sọrọ nìyẹn. Ipò tí àwọn onígbàgbọ akọkọ wà
lẹhin àjínde Kristi náà ni àwa náà wà ní báyìí nítorí pé ìgbàgbọ kan náà nínú àjínde Kristi kan naa ni gbogbo
wa jọ ní. Nítorí èyí, o ṣe pàtàkì kí a ṣe ayẹwo igbesiaye Kristẹni wọn, kí a wo bí wọn ṣe gbà itọni láti ọdọ
Ọlọrun, kí àwa náà le gba itọni gẹgẹ bí tiwọn.


Lónìí, a pe àkíyèsí wa sí iran. Lootọ ẹbùn iran riri wà gẹgẹ bí ẹbùn ṣugbọn ní ọpọlọpọ ìgbà Ọlọrun máa n sí
onigbagbọ lójú láti rí iran. Kí a tó lọ sínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tó niiṣe pẹlu iran rírí, ohun tí a fẹ kí a mọ ni wípé a
kò gbọdọ máa wá iran káàkiri. Orisirisi ọna ní Ọlọrun fi máa n bá ènìyàn sọrọ, Ọlọrun ló máa n yan ọna tó bá
fẹràn láti lò kìíse ènìyàn. Nitorina kìíse ọna tí Ọlọrun gbà bá wa sọrọ lo ṣe pàtàkì jùlọ bikòṣe ohun tí Ọlọrun n
bá wa sọ gan fúnra rẹ.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 9:10-12
[10]Ọmọ-ẹhin kan si wà ni Damasku, ti a npè ni Anania; Oluwa si wi fun u li ojuran pe, Anania. O si wipe, Wò
o, emi niyi, Oluwa.
[11]Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si lọ si ita ti a npè ni Ọgãnran, ki o si bère ẹniti a npè ni Saulu, ara Tarsu,
ni ile Juda: sá wo o, o ngbadura.
[12]On si ti ri ọkunrin kan li ojuran ti a npè ni Anania o wọle, o si fi ọwọ́le e, ki o le riran.

Ananaia tí a n sọrọ rẹ nínú ibi kíkà yìí kìíse Aposteli, kìíse okan nínú àwọn iransẹ Ọlọrun to lorukọ nígbà náà
sugbọn onigbagbọ nínú Kristi bíi ti ọpọlọpọ wa ni ṣugbọn Ọlọrun fi oju ti yóò ṣe han ní ojuran. Ní ojuran lè
túmọ̀sí wípé o ríran, O lè túmọ̀sí àlá nigbana. Njẹ a sakiyesi wipe Ananaia kò máa wá awọn Aposteli ran tàbí
àwọn wòlíì káàkiri lati lè gba ìtùmò ohun tí Ọlọrun fi hàn. Ẹ jẹ kí a mọ wipe imọlẹ ni Ọlọrun nitorina Ọlọrun
kìí bá wa sọ ohun tí a ó nilo elomiran lati ṣe ìtumò rè fún wa. Ìdí rẹ ni wípé ìfẹ rẹ ni ki a gba itọni láti ọdọ rẹ
wá.


Ní ọpọlọpọ ìgbà, iran máa n wá nipasẹ awọn nkan tó lè nilo ìtùmò sugbon olododo ni Olorun láti fún wa ni
ìtumò àwon nkan náà Bẹẹ náà lórí nínú iṣẹ iransẹ Pétérù. Ọlọrun fi nkan hàn fún, ọrọ náà kò yèé sibẹsibẹ
Ọlọrun kò sọ fún láti lọ gba itọni láti ọdọ ẹlòmíràn.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 10:10-12
[10]Ebi si pa a gidigidi, on iba si jẹun: ṣugbọn nigbati nwọn npèse, o bọ si ojuran,
[11]O si ri ọrun ṣí, ohun elo kan si sọkalẹ bi gọgọwú nla, ti a ti igun mẹrẹrin, sọkalẹ si ilẹ.
[12]Ninu rẹ̀li olorijorí ẹranko ẹlẹsẹ mẹrin wà, ati ohun ti nrakò li aiye ati ẹiyẹ oju ọrun.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading