Ọjọ́ Kẹwàá (10), Ọjọ́ Ẹtì , Oṣù Kejì , Ọdún 2023

KRISTẸNI GẸGẸ BÍ IMỌLẸ (3)

KRISTẸNI GẸGẸ BÍ IMỌLẸ (3)


Gẹgẹ bí akẹkọ ọrọ Ọlọrun, a fẹ kí a mọ wipe kò sí ẹnikẹni tó kọjá ìdánwò. Tí a bá lè Jésù Olúwa wa wo, a jẹ
wipe kò sí ẹni tó kọjá ìdánwò nìyẹn. Nitorinà tí a bá n sọrọ wipe kí a jáde kúrò láàrin ìrònú àti ìhùwàsí awọn
ọmọ tí ayé yìí, èyí tó túmọ̀sí kí a tan imọlẹ wa láàrin okunkun biribiri tó su ni ayé yìí, awọn iransẹ Ọlọrun náà
ni ìdánwò láti darapo mọ ayé yìí.


TIMOTI KEJI 4:10
[10]Nitori Dema ti kọ̀mi silẹ, nitori o nfẹ aiye isisiyi, o si lọ si Tessalonika; Kreskeni si Galatia, Titu si
Dalmatia.


Ọ dájú wípé ọkan nínú àwọn alabaṣiṣẹpọ Paulu ni Dema jẹ ṣugbọn ní ibi tó ti n wàásù Ìhìnrere Kristi pẹlu
Paulu náa ni ọkan rẹ ti rọ mọ awọn nkan ti ayé yìí dé ibi wípé o ní láti fi iṣẹ iransẹ sile
Ìkìlọ pàtàkì ní ẹyi fún wa gẹgẹ bi onigbagbo. Tí ìtara tí ènìyàn ní fún iṣẹ Ọlọrun, ọrọ Ọlọrun bá ti lọ silẹ, kò níí
ṣòro fún àwọn nkan tó n lọ ní ayé yìí láti rọ mọ wa lọkàn . Èròngbà satani náà ni wipe kí a má lè tan imọlẹ wa
láàrin okunkun ayé yìí.


Ọnà míràn tí a tún fi n tan imọlẹ gẹgẹ bí Onigbagbọ ni nípa ìwàásù ọrọ Ọlọrun. O sẹni laanu wipe awon
onigbagbo kan wà tí ojú máa n ti wọn láti sọrọ Ọlọrun fun awọn ènìyàn. Tí a bá mọ ibi tí alaigbagbọ yóò parí
irin-ajo rẹ sí, a kò nii lọra láti wàásù ọrọ náà fún wọn. Nípa èyí ni a lè fi le iṣẹ satani jáde nínú ayé wọn
nítorípé ipò tí wọn wà gẹgẹ bí alaigbagbọ, okunkun ni wọn jẹ, bẹẹ sì ni iṣẹ satani n farahàn nínú ayé wọn.


KỌRINTI KEJI 4:3-4
[3]Ṣugbọn bi ihinrere wa ba si farasin, o farasin fun awọn ti o nù:
[4]Ninu awọn ẹniti ọlọrun aiye yi ti sọ ọkàn awọn ti kò gbagbọ́di afọju, ki imọlẹ ihinrere Kristi ti o logo, ẹniti
iṣe aworan Ọlọrun, ki o máṣe mọlẹ ninu wọn.

Nínú ikẹkùn satani ni alaigbagbọ wà. Ojú èyí náà ló yẹ kí a máa fi wò wọn. Satani n jọba lórí ọkàn wọn. Àwa
ni Ọlọrun gbé iṣẹ le lọwọ láti pa èyí dà nínú ayé wọn. Nípa ihinrere Kristi sì ni èyí fi lè ṣeéṣe.


JOHANU KINNI 3:8
[8]Ẹniti o ba ndẹṣẹ ti Èṣu ni; nitori lati àtetekọṣe ni Èṣu ti ndẹṣẹ. Nitori eyi li Ọmọ Ọlọrun ṣe farahàn, ki o le
pa iṣẹ Èṣu run.


Láti pa iṣẹ èṣù run ni Jésù fi wá. Nitorina, àwa ni aṣoju Kristi, ikọ̀àti ìríjú rẹ láàrin okunkun ayé, nípa ìwàásù
ihinrere wa si awọn alaigbagbọ ni iṣẹ satani fi n dẹkùn.


KỌRINTI KEJI 5:19
[19]Eyini ni pe, Ọlọrun wà nínu Kristi, o mba araiye làja sọdọ ara rẹ̀, kò si kà irekọja wọn si wọn lọrùn; o si ti fi
ọ̀rọ ìlaja le wa lọwọ.


Ìwàásù ihinrere ni ọrọ ilaja tí Ọlọrun fi le wa lọwọ.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading