Ọjọ́ Kẹtàlélógún (23), Ọjọ́bọ̀ , Osù Kejì , Ọdún 2023

ÀLÀYÉÌWÉGALATIAL’ẸŚẸẸSẸ(9)

Nítorí aigbagbọ awọn míràn wípé bóyá ẹkọ òdì ni Paulu kọ, O ṣe pàtàkì gẹgẹ bí onigbagbọ kí a mọ bí a ṣe lè dá irú àwọn ènìyàn bẹẹ lohùn. Gẹgẹ bí iransẹ Ọlọrun, òun àmúyẹ pataki ni wipe ẹnikẹni ti yóò bá ṣe ikoni tàbí ìwàásù ihinrere ti gbọdọ kọkọ bá Jésù pàdé. Èyí ni wipe ẹni náà gbọdọ jẹ onígbàgbọ nínú Kristi fúnra rẹ. Kíni àwọn nkan tó mu dá wa lójú wípé lootọ ni Paulu gan funrararẹ gbagbọ ninu Kristi tàbí wipe O bá Jésù pàdé?

Èkíní ni wipe a ṣe àkọsílẹ ìtàn tó sọ nípa bí Paulu gan funrararẹ ṣe bá Jésù pàdé, yatọ sí ẹrí òun gan funrararẹ nínú àwọn Episteli rẹ.

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 9:3-5
[3]O si ṣe, bi o ti nlọ, o si sunmọ Damasku: lojijì lati ọrun wá, imọlẹ si mọlẹ yi i ka:
[4]O si ṣubu lulẹ, o gbọ́ ohùn ti o nfọ̀ si i pe, Saulu, Saulu, ẽṣe ti iwọ fi nṣe inunibini si mi?
[5]O si wipe, Iwọ tani, Oluwa? Oluwa si wipe, Emi Jesu ni, ẹniti iwọ nṣe inunibini si: ohun irora ni fun ọ lati tapá si ẹgún.

Tí a bá ṣakiyesi nínú àbala tí a tọkasi yìí, Paulu, ẹni tí a n pè ní Ṣaulu nígbà náà, ke pe orukọ Olúwa, èyí tó tọkasi wipe o jọwọ ara rẹ fún Kristi ní ìgbà náà nítorí wípé ẹnikẹni tí a kò bá ṣetán láti jọwọ ara wa fún, a kò níí pe irú ẹni bẹẹ ní Olúwa.

Lẹhin èyí, nítorí pàtàkì iṣẹ nínú Igbekale àti ìdàgbàsókè ẹkọ ọrọ Ọlọrun àti itankalẹ ihinrere Kristi káàkiri gbogbo àgbáyé, Ọlọrun bẹrẹ sí fi ìran han Paulu kesekese. Nitorinà, ojúlówó onigbagbọ àti Kristiani ni Paulu jẹ, ní tòótọ kò bá Jésù pàdé nípa ti ara ṣugbọn O mọ Jesu ju ọpọlọpọ awọn ènìyàn tó bá Jésù pàdé nípa ti ara nitoripe awon ẹkọ àti àkọsílẹ rẹ fihàn wípe o mọ Jésù nípa ti Ẹmi.

Ọkan nínú àwọn aṣiṣe tí ọpọlọpọ awọn akékòó ọrọ Ọlọrun máa n ṣe ni wipe wọn máa n rò wípé bóyá Paulu jẹ Aposteli sí àwọn ikọla nìkan ni, rárá àti rárá.

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 9:15
[15]Ṣugbọn Oluwa wi fun u pe, Mã lọ: nitori ohun elo àyo li on jẹ fun mi, lati gbe orukọ mi lọ si iwaju awọn Keferi, ati awọn ọba, ati awọn ọmọ Israeli:

ROMU 1:16
[16]Nitori emi kò tiju ihinrere Kristi: nitori agbara Ọlọrun ni si igbala fun olukuluku ẹniti o gbagbọ́; fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu.

Ṣugbọn ibi tí iṣẹ rẹ wọpọ sí ni láàrin àwọn alaikọlà.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading