Ọjọ́ Kẹtàlélógún (23), Ọjọ́ Ajé , Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

ṢÍṢE IṢẸ OLÚWA (5)

Kí ló máa n fàá tí agbára Ọlọrun lè má farahàn nínú iṣẹ iransẹ? Ọna wo ni èyí fi lè yípadà?
Wipe Jésù ṣe ìlérí wípé agbára rẹ yóò máa farahàn nínú iṣẹ iransẹ àti ìwàásù rẹ ninu ayé wa kò sọ wípé laiṣe
nkan kan yóò máa rí bẹẹ́ ̀. Rárá àti rárá. Ó ní àwọn nkan tó yẹ kí a ṣe, Jésù náà retí wípé àwon ifara-eni-jin wà
tó jẹ bí ojúṣe wa gẹgẹ bí onigbagbọ.


Ẹ jẹ kí a ṣe àgbéyẹ̀wò ibi ti a ti rí ìgbà kan tí agbára rẹ kò farahàn lootọ awọn eniyan tí wọn n gbìyànjú láti rìn
nínú agbára rẹ jẹ ọmọlẹyìn rẹ.


MATIU 17:15-16
[15]Oluwa, ṣãnu ọmọ mi, nitori o ni warapa, o si njoro gidigidi: nigba pupọ ni ima ṣubu sinu iná, ati nigba
pupọ sinu omi.
[16]Mo si mu u tọ̀awọn ọmọ-ẹhin rẹ wá, nwọn kò si le mu u larada.


Nínú àbala tí a tọkasi yìí, arakunrin náà kò sọ wípé àwon ọmọlẹyìn kristi kọ tàbí wipe wọn kò fẹ láti mú ọmọ
tó ní wárápá náà lára dà, wọn kò lè ṣeé ni, lootọ wọn pète láti ṣeé, wọn gbiyanju láti lo agbára tí Kristi fún
wọn nitoripe Kristi tí fún wọn ni agbára náà tẹlẹ rí.


LUKU 10:19
[19]Kiyesi i, emi fun nyin li aṣẹ lati tẹ̀ejò ati akẽkẽ mọlẹ, ati lori gbogbo agbara ọtá: kò si si ohunkan bi o ti
wù ki o ṣe, ti yio pa-nyin-lara.


Ìdí tí wọn kò fi lè rìn nínú agbára yìí ní Jésù ṣàlàyé nínú àwọn ẹsẹ wọny

MATIU 17:19-21
[19]Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ọ wá lẹhin, nwọn bi i pe, Ẽṣe ti awa kò fi le lé e jade?
[20]Jesu si wi fun wọn pe, Nitori aigbagbọ́nyin ni: lõtọ ni mo sá wi fun nyin, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́bi wóro
irúgbin mustardi, ẹnyin o wi fun òke yi pe, Ṣi nihin lọ si ọ̀hun, yio si ṣi; kò si si nkan ti ẹ ki yio le ṣe.
[21]Ṣugbọn irú eyi ki ijade lọ bikoṣe nipa adura ati àwẹ̀.


Jésù ṣàlàyé fún wọn wípé òun tó fàá ni aigbagbọ wọn. Irú aigbagbọ tí Jésù n sọ yìí kìíse aigbagbọ lasan tó
niiṣe pẹlu kí ènìyàn ní ipenija nipa erokero to niiṣe pẹlu iyemeji. Kìíse bẹẹ. Ohun tí Jésù n sọ fún wọn ni wipe
wọn kò ní ìgboyà láti lè rìn nínú agbára Ọlọrun. Kí ló fàá tí wọn kò fi ní ìgboyà yìí? Jésù sọ ohun tó n ṣẹlẹ fún
wọn tí a bá ka àlàyé rẹ síwájú. Ó sọ wípé irú èyí kìí jáde bikòṣe nípa aawẹ ati ádùrá. Kíni ipa tí aawẹ àti ádùrá
n ko nínú Ifarahan agbára Ọlọrun bikòṣe wípé O máa n fúnni ní ìgboyà. Ìgboyà yìí ló n le aigbagbọ jáde nínú
ọkàn ẹni tó fẹ rìn nínú agbára Ọlọrun. Ohun tí igbesiaye ádùrá tó f’ẹsẹ rinlẹ máa n ṣe fún onigbagbọ tàbí
iransẹ Ọlọrun ni wipe o máa n fúnni ní ìgboyà láti rìn nínú agbára Ọlọrun. Irú ìgboyà tàbí ìgbàgbọ yìí kìí
farahàn bikòṣe nípa aawẹ àti ádùrá. Nitorina iransẹ Ọlọrun tó bá tèlé ohun tí Kristi Jésù sọ yìí, yóò rí ifarahan
agbára Ọlọrun nínú iṣẹ iransẹ rẹ.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading