Ọjọ́ Kẹtàlá (13), Ọjọ́Ẹtì , Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

BI ỌLỌRUN ṢE N DARÍ ONIGBAGBỌ (5)

BI ỌLỌRUN ṢE N DARÍ ONIGBAGBỌ (5)


Niwọn igba ti a ti mọ wipe nínú onigbagbọ ni Èmi Ọlọrun kalẹ sí, a jẹ wípé láti inú wa náà ni yóò ti máa ṣe
ìdarí wa nìyẹn. Ni ọpọlọpọ ìgbà nípa ohùn kẹlẹkẹlẹ nínú wa ni yóò fi maa bá wa sọrọ. Ìgbà míràn wà tí ohun
kẹlẹkẹlẹ yìí lè jọ wipe bóyá ìrònú inú wa lásán ni nitoripe kìíse ohùn tó ga sókè tàbí bí ìgbà tí ènìyàn kan bá
sọrọ sókè tí gbogbo ènìyàn lè gbọ.


Fún ọpọlọpọ onígbàgbọ, a máa tilẹ n rí àwọn nkan míràn ti yóò ṣẹlẹ tí yóò sì dà bí ìgbà wípé a ti mọ nípa wọn
télètélè nínú wa ṣùgbọ́n tó jẹ wípé a kò pe àkíyèsí síi.


Ní ọpọlọpọ ìgbà tí Bíbélì bá sọ wípé Èmi Mimọ sọ nkan kan, Ó lè niiṣe pẹlu wípé onigbagbọ gba ìdarí láti ọdọ
Ọlọrun wá láti inú ọkàn wa tí kò sì niiṣe pẹlu wípé bóyá Ọlọrun lo ẹnikan kan láti sọ èyí.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 16:6
[6]Nwọn si là ẹkùn Frigia já, ati Galatia, ti a ti ọdọ Ẹmí Mimọ́kọ̀fun wọn lati sọ ọ̀rọ na ni Asia.
Ìgbà míràn wà to jẹ wípé “Ẹ̀mi Mimọ sọ pé “ lè tọkasi àsọtẹlẹ náà.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 21:11
[11]Nigbati o si de ọdọ wa, o mu amure Paulu, o si de ara rẹ̀li ọwọ́on ẹsẹ, o si wipe, Bayi li Ẹmí Mimọ́wi,
Bayi li awọn Ju ti o wà ni Jerusalemu yio de ọkunrin ti o ni amure yi, nwọn o si fi i le awọn Keferi lọwọ.

Tí onigbagbọ kò bá máa ṣakiyesi awọn nkán tó n jẹyọ lọkàn rẹ, kò níí mọ ìgbà tí Èmi Mimọ bá n ba sọrọ
Láti ṣe atupale èyí, nínú ènìyàn, èrò ọkàn wa tí kò niiṣe pẹlu ìdarí Ọlọrun. Ṣugbọn nínú ọkàn kan náà ìdarí
Ọlọrun lè wá fún wa níbẹ. Báwo ni a ṣe lè mọ iyatọ?

Ó ní ọnà tí èrò ọkàn n gbà wá. Èrò ọkàn ènìyàn lasan niiṣe pẹlu awọn nkan tí a rí tàbí tí a gbọ tàbí àwọn ohun
tí a pinnu láti ro nípa rẹ. Ṣugbọn ìdarí Ọlọrun láti inú wa wá yatọ. Kò niiṣe pẹlu awọn nkan tí a rí tàbí tí a gbọ.
Yóò mú àṣẹ àti ìdánilójú wá ṣugbọn tí a bá ṣe ìwádìí lórí nkan náà, a o ri wipe kò niiṣe pẹlu nkan tí a gbọ tàbí
ti a rí. Ìgbà míràn O lè jẹ nkan tí kò bá ìfẹ inú wa gan mu.


Nkan tí a lè ṣe nípa rẹ ni èyí. Èkíní gbogbo ìdarí Ọlọrun tí a bá gbà kò gbọdọ tako ohun tí Bíbélì sọ. Ọlọrun kìí
tako ara rẹ. Fún àpẹẹrẹ a ti rí àwọn kan tí wọn sọ wípé Ọlọrun sọ wípé kí àwon lọ fẹ ìyàwó ẹlòmíràn tó wà
nílé ọkọ rẹ. Kìíse wípé èyí kò bojumu nìkan ṣùgbọ́n o takò ọrọ Ọlọrun nitoripe kí ẹnikẹ́ni mase yà wọn ní ọrọ
Ọlọrun sọ. Nitorinaa kò lè ṣe ọdọ Ọlọrun ló ti wá.


Ọna Kejì láti mọ bóyá ọdọ Ọlọrun ló ti wa ni wípé, ní ọpọlọpọ ìgbà Ọlọrun máa n lo ọna míràn láti fí dá wa
lójú wípé láti ọdọ òun ni ìdarí náà ti wá. Àpẹrẹ èyí ṣẹlẹ ní Antioku.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 13:2
[2]Bi nwọn si ti njọsìn fun Oluwa, ti nwọn si ngbàwẹ, Ẹmí Mimọ́wipe, Ẹ yà Barnaba on Saulu sọtọ̀fun mi fun
iṣẹ ti mo ti pè wọn si.


Àkíyèsí pàtàkì ni wipe nínú ìdarí tí wọn gbà, nkan tí Èmi Mimọ sọ fún wọn ni wipe “si iṣẹ tí mo ti pe wọn sí “ .
Èyí ni wipe ipè tí wọn n sọ nínú àsọtẹlẹ yìí kìíse nkan àjèjì sí Barnaba àti Ṣaulu. Wọn ti mọ tẹlẹ tẹlẹ, Èmi
Ọlọrun ni ṣe ìfimuleẹ̀rẹ nípa àsọtẹlẹ ni

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading