Ọjọ́ Kẹtàdínlógún (17), Ọjọ́ Ìsẹ́gun , Oṣù Kíní , Ọdún 2023

ÒFIN TÍTÚN TI KRISTI (2)

ÒFIN TÍTÚN TI KRISTI (2)


Tí ọpọlọpọ bá n gbọ wipe a kò sí labẹ òfin mọ wipe a ti wà labẹ oore ọfẹ Kristi, wọn máa n ronú wípé nkan tó
túmọ̀sí ni wipe boya ohun tí a n sọ ni wípé wọn lẹtọ láti ṣe ohunkóhun tó bá wù wọn nìyẹn. Kò rí bẹẹ rárá àti
rárá.


Lootọ ẹ jẹ kí a mọ wipe nipasẹ oore ọfẹ Kristi nikan ni a fi gbà wá là bẹẹ sì ni ko sí ohunkóhun tí ẹnìkan lè ṣe
láti tẹ Olorun lọrùn nípa ìgbàlà yàtọ sí èyí tí Kristi ti ṣe. Ẹbọ tí Jésù fi ara rẹ rú nikan ni ẹbọ tó gba níwájú itẹ
ìdájọ.


Oore ọfẹ Kristi sì nilo kí ènìyàn tẹwọgbà. Bẹẹ ni. Oore ọfẹ tí a kò bá tẹwọgbà kò lè ṣe ohunkóhun nínú ayé
wa. Kò lè fún wa ní ìgbàlà tó wà nínú rẹ.


JOHANU 3:16
[16]Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹ̃gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rẹ̀kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́má bà
ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun.


Gẹgẹ bí ẹsẹ Bíbélì yìí ti sọ fún wa. Tani kò níí ṣegbe? Ẹnikẹni tó bá gbàá, bẹẹ ni Bibeli sọ. Nítorínáà, o nilo kí
ènìyàn ní ìgbàgbọ nínú oore ọfẹ Ọlọrun. Oore ọfẹ Ọlọrun ni ìpèsè tí Ọlọrun ti pèse silẹ fún Idariji ẹsẹ.
Láti di ọmọ Ọlọrun tàbí ní àlàáfíà pẹlú Ọlọrun, iṣẹ tí Ọlọrun ti ṣe sílẹ nipasẹ Jésù Kristi ni ṣugbọn anfaani to rọ
mọ iṣẹ yìí kò lè farahàn nínú ayé wa ayafi tí a bá tẹwọgbà iṣẹ náà.


JOHANU 1:12
[12]Ṣugbọn iye awọn ti o gbà a, awọn li o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn na ti o gbà orukọ rẹ̀
gbọ́:

Kìíse gbogbo ènìyàn ló ní ẹtọ láti di ọmọ Ọlọrun bikòṣe awọn tó gbàá. Nitorina ibi ti iṣẹ ènìyàn wà ni lati
gbàá. Kò sí ohunkóhun tí Ọlọrun béèrè lọwọ ènìyàn ju èyí lọ. Láti gbàgbọ́ni.

EFESU 2:8-9
[8]Nitori ore-ọfẹ li a ti fi gbà nyin là nipa igbagbọ; ati eyini kì iṣe ti ẹnyin tikaranyin: ́ ẹ̀bun Ọlọrun ni:
[9]Kì iṣe nipa iṣẹ, ki ẹnikẹni má bã ṣogo.

Ìgbàlà kìí wá nipasẹ akitiyan ènìyàn. Ẹnikẹni tó bá lérò wípé ìwà mímọ ohun ni yóò sọ òun di ẹni itẹwọgbà
níwájú Ọlọrun, o n gberaga ni. Agbéraga kò lè ní àlàáfíà pẹlú Ọlọrun.

JAKỌBU 4:6
[6]Ṣugbọn o nfunni li ore-ọfẹ si i. Nitorina li o ṣe wipe, Ọlọrun kọ oju ija si awọn agberaga, ṣugbọn o fi oreọfẹ fun awọn onirẹlẹ ọkàn.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading