Ọjọ́ Kẹtàdínlógún (17), Ọjọ́ Ẹtì , Osù Kejì , Ọdún 2023

KRISTẸNI GẸGẸ BÍ IMỌLẸ (10)

A sì ní sọrọ nípa bí Jésù ṣe fẹ wa àti bó ṣe yẹ kí àwa náà máa fi ìfẹ kan náà hàn fún ẹlòmíràn. Tí ìfẹ yìí bá jẹ ohun tí agbára ènìyàn lè ṣe, a jẹ wípé kìíse ìfẹ Ọlọrun nìyẹn. Irú ìfẹ tí a n sọ yìí kọja agbára ènìyàn. Nítorínaa kìíse ohun tí a n fi ipá tàbí agbára ṣe rárá. Ohun tí a ní iseda rẹ nínú Atunbi ni.

ROMU 5:5
[5]Ireti kì si idojuti ni; nitori a ti tan ifẹ Ọlọrun ká wa lọ́kàn lati ọdọ Ẹmí Mimọ́ wá ti a fifun wa.

Ìfẹ Ọlọrun ka wa ní ọkàn. Nitorinà Ọlọrun ti fún wa ni Èmi rẹ láti lè ràn wá lọwọ láti rìn nínú ìfẹ Ọlọrun gan funrararẹ, nítorínaa ìgbàgbọ wa gbọdọ dúró le èyí lórí. Tó bá se wípé oun ti a o fi ipá tàbí agbára wa ṣe, tó sì soro a jẹ wípé àjàgà Kristi kò rọrùn nìyẹn. Ṣugbọn kìíse nkan tí Kristi kọ wa ni èyí. Ó sọ wípé àjàgà òun rọrùn. Ó sọ wípé eru òun fuyẹ.

MATIU 11:29-30
[29]Ẹ gbà àjaga mi si ọrùn nyin, ki ẹ si mã kọ́ ẹkọ́ lọdọ mi; nitori oninu tutu ati onirẹlẹ ọkan li emi; ẹnyin o si ri isimi fun ọkàn nyin.
[30]Nitori àjaga mi rọrun, ẹrù mi si fuyẹ.

Kò sí ohunkóhun nínú òfin Kristi tó soro láti ṣe nitoripe o ti fún wa ni èmi rẹ láti kọ wa bẹẹ náà sì ni okun wà nínú ọrọ rẹ láti lè fún wa ni agbára láti ṣe bẹẹ gẹgẹ. Jòhánù náà sàlàyé èyí nínú Episteli rẹ.

JOHANU KINNI 5:3
[3]Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, pe ki awa ki o pa ofin rẹ̀ mọ́: ofin rẹ̀ kò si nira.

Jòhánù sọ wípé kí a pa ofin Ọlọrun mọ sugbọn òfin rẹ kò nira nítorípé òun náà ló n ṣiṣe nínú wa. Tí a bá ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí ọrọ Ọlọrun n ṣe nínú ayé ènìyàn, a o rí ìdí tí òfin rẹ kò fi nira.

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 20:32
[32]Njẹ nisisiyi, ará, mo fi nyin le Ọlọrun lọwọ ati ọ̀rọ ore-ọfẹ rẹ̀, ti o le gbe nyin duro, ti o si le fun nyin ni ini lãrin gbogbo awọn ti a sọ di mimọ́.

Kí ló n gbé ènìyàn dúró? Ọrọ oore ọfẹ Ọlọrun. Nitorinà ẹ jẹ kí a gbagbọ wípé ọrọ oore ọfẹ Ọlọrun lágbára láti lè fún wa ni okun láti dúró ṣinṣin nínú ìfẹ Ọlọrun lórí ọrọ tó niiṣe pẹlu ifarahan ìfẹ rẹ.
Nínú ìfẹ yìí ni àwon Aposteli rìn tó fi jẹ wípé nígbà tí wọn ṣe inúnibíni sí wọn, wọn kò gbàdúrà lodi sí àwọn tó n ṣe inúnibíni sí wọn. Wọn kò sẹ́ èpè le awọn tó n ṣe inúnibíni sí wọn, sibẹ wọn tẹsiwaju láti máa wàásù oore ọfẹ Kristi sí àwọn ènìyàn ni

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading