Ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n (27), Ọjọ́ Ẹtì , Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

ÀLÀYÉ ÌWÉ GALATIA L’ẸSẸẸSẸ (2)

Tí a bá tún wo ohun tí àwọn Aposteli tó wà ní Jerusalemu sọ nípa Paulu àti àwọn alabaṣiṣẹpọ rẹ, O dájú wípé
wọn fi ontẹ lu iṣẹ iransẹ wọn.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 15:12,25-26
[12]Gbogbo ajọ si dakẹ, nwọn si fi eti si Barnaba on Paulu, ti nwọn nròhin iṣẹ aṣẹ ati iṣẹ àmi ti Ọlọrun ti ti
ọwọ́wọn ṣe lãrin awọn Keferi.
[25]O yẹ loju awa, bi awa ti fi imọ ṣọkan lati yàn enia ati lati rán wọn si nyin, pẹlu Barnaba on Paulu awọn
olufẹ wa.
[26]Awọn ọkunrin ti o fi ẹmí wọn wewu nitori orukọ Oluwa wa Jesu Kristi.


Kìíse bẹẹ nìkan, láàrin àwọn onígbàgbọ yòókù ni Ọlọrun ti pe Ṣaulu tí a mọ sí Paulu jade fún iṣẹ iransẹ tó ti
fún. Nítorínaa kìíse ẹni tó gba ìpè iṣẹ iransẹ ní kòrò yaara kan. A n sàlàyé gbogbo èyí kí o lè yé wa wípé
ojúlówó iṣẹ iransẹ ni iṣẹ iransẹ Paulu kìíse ayederu. A o tún ṣe amenuba awọn ohun àmúyẹ tó fihàn wípe ní
tòótọ ni Ọlọrun péé fún iṣẹ iransẹ rẹ àti wípé àwon ẹkọ tó kọ ṣeé gbẹkẹle gẹgẹ bí ẹkọ ọrọ Ọlọrun.


Awọn onigbagbọ kan wà tí wọn kìí fé gbọ ohunkohun tó niiṣe Pẹlu Paulu nitoripe wọn gbagbọ wípé àwon
ẹkọ rẹ takò ohun tó wà nínú ẹkọ awọn Aposteli yòókù. Kò t’ọna rárá
Kódà nípa iṣẹ iransẹ Paulu ní ìgbàgbọ Kristẹni fí gbòòrò daradara láàrin àwọn alaikọlà nitoripe awọn
ọmọlẹyìn Kristi kọkọ gbagbọ wípé ìgbàgbọ nínú Kristi niiṣe pẹlu awọn Júù nikan ni. Nitorina, àwa alawọ dúdú
gẹgẹ bí aláikola kò gbọdọ fi ẹkọ náà seré rárá.


Awọn kan tún gbagbọ wípé nipasẹ oore ọfẹ tí Paulu n ṣe ikoni rẹ ni awọn kan fi n tẹsiwaju nínú ẹsẹ. Irọ lásán
ni eyí náà jẹ. Paulu gan náà ṣe amenuba awọn nkan tó jọ bẹẹ.

ROMU 3:8
[8]Ẽṣe ti a kò si wipe (gẹgẹ bi a ti nsọrọ wa ni ibi, ati gẹgẹ bi awọn kan ti nsọ pe, awa nwipe,) Ẹ jẹ ki a mã ṣe
buburu, ki rere ki o le jade wá? awọn ẹniti ẹ̀bi wọn tọ́.


ROMU 6:1-2
[1]NJẸ awa o ha ti wi? Ki awa ki o ha joko ninu ẹ̀ṣẹ, ki ore-ọfẹ ki o le ma pọ̀si i?
[2]Ki a má ri. Awa ẹniti o ti kú si ẹ̀ṣẹ, awa o ha ṣe wà lãye ninu rẹ̀mọ?́


Ọkan ninu awọn nkan tó tún yẹ kí a fí gbagbọ ninu iṣẹ iransẹ rẹ ni wipe ẹnikẹni tó bá kojú inúnibíni nitori
ìwàásù ọrọ Ọlọrun, a jẹ wípé lootọ ni irú ẹni béè gbagbọ nínú nkan tó n wàásù nìyẹn. Nitori Kristi Jésù,
inúnibíni nla dide sí Paulu, gẹĺẹ́bẹẹ náà ni o ṣetan láti kú fún ìgbàgbọ náà


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 21:13
[13]Nigbana ni Paulu dahùn wipe, Ewo li ẹnyin nṣe yi, ti ẹnyin nsọkun, ti ẹ si nmu ãrẹ̀ba ọkàn mi; nitori emi
mura tan, kì iṣe fun didè nikan, ṣugbọn lati kú pẹlu ni Jerusalemu, nitori orukọ Jesu Oluwa.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading