Ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n (27), Ọjọ́ Ajé , Osù Kejì , Ọdún 2023

ÀLÀYÉÌWÉGALATIAL’ẸŚẸẸSẸ(13)

Tí kiiba ṣe awọn àkọsílẹ Paulu, titi di òní olonii yìí ni ọpọlọpọ awọn onigbagbọ yóò máa tẹlé ofin Mósè. A rí àwọn onígbàgbọ tó máa n sọ wípé Jésù gan funrararẹ mú ofin Mósè ṣẹ, nitorinaa a gbọdọ mú òfin ṣẹ. Ní akọkọ kìíse gbogbo ènìyàn ni a fún ní òfin Mósè laye ìgbà Mósè gan funrararẹ. Awọn Israẹli nikan ni wọn wà labẹ òfin náà.

ROMU 2:12
[12]Nitori iye awọn ti o ṣẹ̀ li ailofin, nwọn ó si ṣegbé lailofin: ati iye awọn ti o ṣẹ̀ labẹ ofin, awọn li a o fi ofin dalẹjọ;

Awọn alailofin ti a mẹnuba nínú ẹsẹ yìí kìíse awọn ẹlẹsẹ bikòṣe awọn ti kò sí labẹ ofin Mósè. Nitorinaa nígbà tí Bíbélì sọ fún wa nípa wípé a ti gbà wá kúrò labẹ òfin Mósè, kìíse gbogbo wa ló n sọ nípa. Ó n sọrọ nípa àwọn tó wà labẹ òfin náà ni nitoripe kò ṣeéṣe láti gba àwọn tí kò sí labẹ ofin kúrò labẹ rẹ.

Nitorinà, ìwé Galatia gẹgẹ bí Episteli ni ọkan nínú àwọn ìwé tí a kọ láti gbà wá kúrò lọwọ àwọn tó n kọ ẹkọ òdì wípé kí Kristẹni máa tẹlé awọn òfin Mósè. Kí ló burú gan nínú òfin Mósè? Bíbélì jẹ kí a mọ wipe aleebu wà níbẹ.

HEBERU 8:8-10
[8]Nitoriti o ri àbuku lara wọn, o wipe, Kiyesi I, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o bá ile Israeli ati ile Juda dá majẹmu titun.
[9]Kì iṣe gẹgẹ bi majẹmu ti mo ti bá awọn baba wọn dá, li ọjọ na ti mo fà wọn lọwọ lati mu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti; nitoriti nwọn kò duro ninu majẹmu mi, emi kò si kà wọn si, ni Oluwa wi.
[10]Nitori eyi ni majẹmu ti emi ó ba ile Israeli da lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi; Emi ó fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ wọn si ọkàn wọn: emi o si mã jẹ́ Ọlọrun fun wọn, nwọn o si mã jẹ́ enia fun mi:

Nitorinà aleebu wà nínú òfin nitoripe òfin n dání lẹbi, kò sí ìdáláre nínú rẹ. Kò sí bí ẹnikẹni ṣe lè gbìyànjú tó. Kò sí akitiyan ti ènìyàn lè máa sa, a kò lè rí ìdáláre gbà nípa òfin.

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 13:39
[39]Ati nipa rẹ̀ li a ndá olukuluku ẹniti o gbagbọ lare kuro ninu ohun gbogbo, ti a kò le da nyin lare ninu ofin Mose.

Nítorí ìdí èyí, Paulu ni ẹni tí Ọlọrun gbé dide láti ja ìjà ẹkọ tó niiṣe pẹlu iṣẹ òfin ní ìbẹrẹ ìgbàgbọ Kristẹni.

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 15:1-2
[1]AWỌN ọkunrin kan ti Judea sọkalẹ wá, nwọn si kọ́ awọn arakunrin pe, Bikoṣepe a ba kọ nyin ni ilà bi iṣe Mose, ẹnyin kì yio le là.
[2]Nigbati iyapa ati iyàn jijà ti mbẹ lãrin Paulu on Barnaba kò si mọ ni ìwọn, awọn arakunrin yàn Paulu on Barnaba, ati awọn miran ninu wọn, ki nwọn goke lọ si Jerusalemu, sọdọ awọn aposteli ati awọn àgbagba nitori ọ̀ran yi.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading