Ọjọ́ Kẹta (3), Ọjọ́ Ẹtì , Oṣù Kejì , Ọdún 2023

IGBỌWỌLÈ ÀTI IṢẸ IRANSẸ (3)

IGBỌWỌLÈ ÀTI IṢẸ IRANSẸ (3)


Ní ìgbà tí a ti di onígbàgbọ, a ti di ẹyà ara kan náà pẹlu Kristi.


EFESU 5:30
[30]Nitoripe awa li ẹ̀ya-ara rẹ̀, ati ti ẹran-ara rẹ̀, ati ti egungun ara rẹ̀.


Iṣẹ Ẹ̀mí Mimọ ni èyí nínú atunbi, kìíse iransẹ Ọlọrun kankan lo n pè wá sí èyí. A ti di ọkan pẹlu Kristi. Ẹyà ara
Kristi ni a jẹ.


KỌRINTI KINNI 12:13
[13]Nitoripe ninu Ẹmí kan li a ti baptisi gbogbo wa sinu ara kan, iba ṣe Ju, tabi Hellene, iba ṣe ẹrú, tabi
omnira; a si ti mú gbogbo wa mu ninu Ẹmí kan.


Bí kò ṣe sí ẹyà ara kánkan nínú ara wa tí kò ní iṣẹ tó n ṣe, bẹẹ náà ni kò sí ẹyà ara kánkan nínú Kristi tí kò ní
iṣẹ iransẹ. Gbogbo wa patapata ni a ni iṣẹ iransẹ níwòn ìgbà tí a ti di onígbàgbọ ninu Kristi. A ti pe wá nìyẹn.
Gbigba Kristi ní Olúwa àti Olùgbàlà wa kìíse ipè sí ìyè nìkan, ipè sí iṣẹ iransẹ náà ló jẹ. Ẹnikẹni tó bá ti bá Kristi
pàdé ti ṣetan láti tẹlé Kristi ni ìtumò rẹ. Èyí ni láti ṣe àwọn iṣẹ tí Kristi náà n ṣe ní ayé yìí. Jésù sọ nípa amin tí
yóò máa tẹlé awọn tó ti gbagbọ nínú òun.


MAKU 16:17
[17]Àmi wọnyi ni yio si ma ba awọn ti o gbagbọ́lọ; Li orukọ mi ni nwọn o ma lé awọn ẹmi èṣu jade; nwọn o si
ma fi ède titun sọ̀rọ;


Njẹ a sakiyesi wipe amin tí yóò máa tẹlé awọn tó bá gbagbọ ni Jésù wí kìíse amin tí yóò máa tẹlé awọn tó ti
pẹ nínú iṣẹ iransẹ tàbí àwọn tó ti lorukọ nla gẹgẹ bí olusoaguntan? Nítorínaa awọn amin tó sọ niiṣe pẹlu
awọn amin ẹni tó n wàásù ìhìnrere. Nitorina gbogbo wa ni a ti ní iṣẹ iransẹ. Jésù ni orí wa. Bó ṣe jẹ wípé kò sí
ẹyà ara kan tó ní ọpọlọpọ yatọ sí orí bẹẹ náà ni ijọ Ọlọrun tàbí ara Kristi rí. Gbogbo ìlànà àti ìpinnu, láti ọdọ
Kristi ló tí n wa. Òun ló mọ nkan tí yóò pè wá láti ṣe.


JOHANU 14:12
[12]Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, iṣẹ ti emi nṣe li on na yio ṣe pẹlu; iṣẹ ti o tobi jù wọnyi
lọ ni yio si ṣe; nitoriti emi nlọ sọdọ Baba.


Ṣugbọn O jẹ ki a mọ wipe iṣẹ tí òun náà n ṣe ló pè wá láti ṣe. Èyí tumosi wípé irú ifara-eni-jin tí òun náà fi sínú
iṣẹ náà ló retí láti ọdọ wa. Nípa èyí ni awọn agbára àti òòrè ọfẹ tó ti fi jinki wa lè bẹrẹ sí níí farahàn. Lẹhin
ìgba tó ti hàn gbangba sí gbogbo ènìyàn ní ọjọ Pentikosti wípé àwon ọmọlẹyìn kristi ti kún fún Èmí Mimọ,
wọn kò káwó gbéra, wọn ni tẹsiwaju nínú ádùrá, kilode? Kí wọn lè máa kún fún Èmí ní gbogbo ìgbà, kí wọn lè
wà ní ipò láti máa ṣe àwọn ohun tí Jésù sọ wípé wọn yóò ṣe.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 4:31,33
[31]Nigbati nwọn gbadura tan, ibi ti nwọn gbé pejọ si mi titi; gbogbo wọn si kún fun Ẹmí Mimọ́, nwọn si nfi
igboiya sọ ọ̀rọ Ọlọrun.
[33]Agbara nla li awọn aposteli si fi njẹri ajinde Jesu Oluwa; ore-ọfẹ pipọ si wà lori gbogbo wọn

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading