Ọjọ́ Kẹ̀sán (9), Ọjọ́bọ̀, Oṣù Kejì , Ọdún 2023

KRISTẸNI GẸGẸ BÍ IMỌLẸ (2)

KRISTẸNI GẸGẸ BÍ IMỌLẸ (2)


Ẹnikẹni tó bá ti gba Kristi ti wà nínú imọlẹ. O ti di imọlẹ.


MATIU 5:14-16
[14]Ẹnyin ni imọlẹ aiye. Ilu ti a tẹ̀do lori òke ko le farasin.
[15]Bẹ̃ni a kì itàn fitila tan, ki a si fi I sabẹ òṣuwọn; bikoṣe lori ọpá fitila, a si fi imọlẹ fun gbogbo ẹniti mbẹ
ninu ile.
[16]Ẹ jẹ ki imọlẹ nyin ki o mọlẹ tobẹ̃niwaju enia, ki nwọn ki o le mã ri iṣẹ rere nyin, ki nwọn ki o le ma yìn
Baba nyin ti mbẹ li ọrun logo.


A ti di imọlẹ láàrin okunkun, ìdí èyí ló fi yẹ kí a yàtọ sí àwọn alaigbagbọ nínú èro, ìwà àti iṣe. Ohun tí Jésù n kọ
wa gẹgẹ bí ẹkọ nínú àbala Bíbélì tí a tọkasi yìí ni wipe kí a gba imọlẹ náà láàyè láti mọlẹ, kìíse ko mọlẹ níwájú
Ọlọrun ṣugbọn níwájú ènìyàn. Báwo ni a ṣe lè ṣe èyí? O sọ fún wa wípé kí a máṣe darapọ mọ awọn ti ayé
nìyẹn nítorípé ènìyàn ọtọ ni a jẹ a sì ti pe wá jáde láti kúrò láàrin àwọn ti ayé yìí. Tí a bá n darapọ mọ wọn láti
ṣe àwọn nkan tó jẹ tiwọn a jẹ wípé a kò ṣetan láti tan imọlẹ wa nìyẹn.


KỌRINTI KEJI 6:17-18
[17]Nitorina ẹ jade kuro larin wọn, ki ẹ si yà ara nyin si ọ̀tọ, li Oluwa wi, ki ẹ máṣe fi ọwọ́kàn ohun aimọ́; emi
o si gbà nyin.
[18]Emi o si jẹ Baba fun nyin, ẹnyin o si jẹ ọmọkunrin mi ati ọmọbinrin mi, li Oluwa Olodumare wi.


Wípé ènìyàn jẹ imọlẹ kò sọ wipe ènìyàn n tan imọlẹ náà nítorípé kìíse nkan kan náà. Tó bá jẹ wipe kò ṣeéṣe
láti jẹ imọlẹ kí a má sì tan imọlẹ wa ni, Jésù ko níí kìlọ fún wa wípé ki a má fi fìtílà wa sí abẹ osunwon. Èyí náà
ni Paulu n tọkasi ninu lẹta rẹ sí àwọn ará Efesu.


EFESU 5:8
[8]Nitori ẹnyin ti jẹ òkunkun lẹ̃kan, ṣugbọn nisisiyi, ẹnyin di imọlẹ nipa ti Oluwa: ẹ mã rìn gẹgẹ bi awọn ọmọ
imọlẹ:

O kọkọ sọ fún wọn wipe wọn ti di imọlẹ sugbon kò parí síbẹ̀nítorípé ìyẹn nìkan kò tó. Ọ ṣeéṣe kí ènìyàn jẹ
ọmọ imọlẹ ṣugbọn ko má rìn bí ọmọ imọlẹ. Láti rìn gẹgẹ bí ọmọ imọlẹ, a kò lè ní ìfẹ sí àwọn nkan tí àwọn ti
ayé yìí nifẹ sí.


ROMU 12:1-2
[1]NITORINA mo fi iyọ́nu Ọlọrun bẹ̀nyin, ará, ki ẹnyin ki o fi ara nyin fun Ọlọrun li ẹbọ ãye, mimọ́, itẹwọgbà,
eyi ni iṣẹ-isìn nyin ti o tọ̀na.
[2]Ki ẹ má si da ara nyin pọ̀mọ́aiye yi: ṣugbọn ki ẹ parada lati di titun ni iro-inu nyin, ki ẹnyin ki o le ri idi ifẹ
Ọlọrun, ti o dara, ti o si ṣe itẹwọgbà, ti o si pé

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading