Ọjọ́ Kẹ̀sán (9), Ọjọ́ Ajé , Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

BI ỌLỌRUN ṢE N DARÍ ONIGBAGBỌ (1)


Gẹgẹ bí Kristẹni, ohun kan tí a mọ dájúdájú ni wípé ìfẹ Ọlọrun ni kí a gba ìdarí rẹ. Labẹ gbogbo sáà ni èyí jẹ.
Dáfídì Ọba gan nínú Psalmu rẹ sọ nípa èyí.

BI ỌLỌRUN ṢE N DARÍ ONIGBAGBỌ (1)


ORIN DAFIDI 23:3
[3]O tù ọkàn mi lara; o mu mi lọ nipa ọ̀na ododo nitori orukọ rẹ̀.


Nitorina kìíse ìfẹ Ọlọrun kí a wà nínú okunkun biribiri nínú ayé yìí, Ọlọrun ni ife láti fi ọna rẹ hàn wá, pàápàá
jùlọ lórí ọrọ ayé wa. Ninu Kristi ni imọlẹ wa túmọ̀sí wípé ẹnikẹni tó bá tẹlẹ Kristi tàbí gbagbọ nínú rẹ kò lè rìn
nínú okunkun rárá.


JOHANU 1:4
[4]Ninu rẹ̀ni ìye wà; ìye na si ni imọlẹ̀araiye.


JOHANU 8:12
[12]Jesu si tun sọ fun wọn pe, Emi ni imọlẹ aiye; ẹniti o ba tọ̀mi lẹhin kì yio rìn ninu òkunkun, ṣugbọn yio ni
imọlẹ ìye.


Nitorina ìlérí Kristi fún àwa onigbagbọ nínú rẹ ni wipe a o máa rìn nínú imọlẹ. Lootọ ririn nínú imọlẹ túmọ̀sí
wípé a n rìn ní ọnà tó yàtọ sí tí okunkun, iporuru àti ibi tó wà ní ayé isisiyi ṣugbọn kò parí síbẹ̀, o tun tumosi
wípé a o mọ awọn nkan tó niiṣe pẹlu ayé wa nípa ti Èmi. Tí a bá ti n sọrọ nípa itọni tàbí ìdarí Ọlọrun, ohun tó
máa n kọ ọpọlọpọ lominu ni wipe wọn máa n ronú wípé “emi kò gbọ ohun kánkan, báwo ni Ọlọrun ṣe wa lè
darí mi?”

Nínú ìdarí láti ọdọ Ọlọrun wá, Kirisiteni gbọdọ mọ dájú wípé ohun tó tọ sí wa ni.


ROMU 8:14
[14]Nitori iye awọn ti a nṣe amọ̀na fun lati ọdọ Ẹmí Ọlọrun wá, awọn ni iṣe ọmọ Ọlọrun.


Iha tó yẹ kí a kọ sí ẹsẹ Bíbélì yìí kìíse wípé bóyá ní iwọn ìgbà ti àwa kò máa gbọ́láti ọdọ Ọlọrun, bóyá a kìíse
ọmọ Ọlọrun nìyẹn. Kìíse irú iha tó yẹ kí a kọ sí ọrọ náà ni eyi. Iha tó yẹ kí a kọ sí ẹsẹ Bíbélì náà ni wipe, ní
iwọn ìgbà tí ọrọ Ọlọrun ti sọ wípé onigbagbọ máa n gbọ láti ọdọ Ọlọrun, otitọ náà gbọdọ fún wa ní ìgboyà
wípé a jẹ wípé ìfẹ Ọlọrun ni láti bá wa sọrọ nìyẹn. Bó ṣe jẹ wípé tí a bá fẹ gbọ láti ọdọ ẹnikan pàtó, a gbọdọ
béèrè lọwọ ará wa wipe “bawo ni ẹni náà ṣe máa n sọrọ jáde “ bẹẹ náà ni tí Ọlọrun rí, láti ọla lọ, a o máa ṣe
ayẹwo nípa ọna tí Ọlọrun máa n gbà bá àwọn tirẹ sọrọ.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading