Ọjọ́ Kẹrinlélógún (25), Ọjọ́ Ẹtì , Osù Kejì , Ọdún 2023

ÀLÀYÉÌWÉGALATIAL’ẸŚẸẸSẸ(11)

Ẹnikẹni tó bá jìyà tó sì ṣetan láti kú nítorí ihinrere Kristi jẹ ẹni tó ṣeé gbagbọ. Bẹẹ ní ihinrere Kristi ti rí nitoripe nípa iṣẹ tí ìgbàgbọ n ṣe ni a fi máa n mọ ìgbàgbọ.

JAKỌBU 2:18
[18]Ṣugbọn ẹnikan le wipe, Iwọ ni igbagbọ́, emi si ni iṣẹ: fi igbagbọ́ rẹ hàn mi li aisi iṣẹ, emi o si fi igbagbọ́ mi hàn ọ nipa iṣẹ mi.

Ìdí rẹ ló fi jẹ wípé ni ibẹrẹ ìgbàgbọ Kristẹni, nítorí inúnibíni tó pọ káàkiri tó gbòde kan nígbà náà, ẹnikẹni tó bá jẹ́wọ́ ní gbangba níwájú gbogbo ènìyàn wípé lootọ ni Jésù jinde, O gbọdọ jẹ wípé ẹni náà gbagbọ nìyẹn. Nitoripe ìgbàgbọ kò ṣeé fojú rí, ohunkóhun tí ènìyàn bá f’enu sọ tàbí tó bá farahàn nínú isé ni a lè tọkasi gẹgẹ bí ìgbàgbọ nínú Kristi.

ROMU 10:9-10
[9]Pe, bi iwọ ba fi ẹnu rẹ jẹwọ Jesu li Oluwa, ti iwọ si gbagbọ́ li ọkàn rẹ pe, Ọlọrun jí I dide kuro ninu okú, a o gbà ọ là.
[10]Nitori ọkàn li a fi igbagbọ́ si ododo; ẹnu li a si fi ijẹwọ si igbala.

Tó bá jẹ Episteli tí Pétérù kọ ni a n sàlàyé ni a kò nilo láti máa lo ọpọlọpọ ààyè láti sàlàyé wípé Aposteli ní tòótọ ló jẹ nitoripe O jẹ ọmọlẹyìn Jésù, O sì ní ìrírí àwọn nkan agbaayanu tó ṣẹlẹ labẹ iṣẹ iransẹ Jésù tó fihàn wípe lootọ òun ni Olugbala aráyé. Paulu gẹgẹ bí ẹnìkan kò sí níbẹ nígbà náà, ṣugbọn awọn iya to ṣetan láti jẹ nitori ìwàásù ihinrere Kristi àti oun tí ojú rẹ rí nídìí iṣẹ náà fihàn wípe lootọ ni Ọlọrun péé àti wípé kìíse òun ló pe ara rẹ.

Láti ibẹrẹ iṣẹ iransẹ rẹ nígbà tó ti di onígbàgbọ ni Ọlọrun ti sọ nípa iya tí yóò jẹ.

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 9:16
[16]Nitori emi o fi gbogbo ìya ti kò le ṣaijẹ nitori orukọ mi han a.

Ananaia ni ẹni tí Ọlọrun bá sọ èyí nípa Paulu. Bẹẹ náà ni nígbà tí Ọlọrun fi ipè rẹ múlẹ láàrin ìjọ, kìíse òun ló n sọ wípé Ọlọrun pe oun bikòṣe awọn ènìyàn tó wà níbẹ gẹgẹ bí ọmọlẹyìn Kristi àti àwọn tí a pè gẹgẹ bíi wòlíì.

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 13:1-2
[1]AWỌN woli ati awọn olukọni si mbẹ ninu ijọ ti o wà ni Antioku; Barnaba, ati Simeoni ti a npè ni Nigeri, ati Lukiu ara Kirene, ati Manaeni, ti a tọ́ pọ̀ pẹlu Herodu tetrarki, ati Saulu.
[2]Bi nwọn si ti njọsìn fun Oluwa, ti nwọn si ngbàwẹ, Ẹmí Mimọ́ wipe, Ẹ yà Barnaba on Saulu sọtọ̀ fun mi fun iṣẹ ti mo ti pè wọn si.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading