Ọjọ́ Kẹrinlélógún (24), Ọjọ́ Ìsẹ́gun , Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

ṢÍṢE IṢẸ OLÚWA (6)

Ohun tó fún ìgbàgbọ Kristẹni ní agbára láti gbooro síi ni wipe Ọlọrun máa n agbára rẹ hàn nípa ìwàásù
ihinrere ti Kristi. Ìfẹ Ọlọrun ni fún gbogbo onigbagbọ pátápátá láti rìn nínú agbára rẹ nitoripe gbogbo wa
patapata ni Jésù rán jáde láti wàásù ìhìnrere rẹ. Awọn tó kọkọ wàásù ìhìnrere rẹ, Jésù fi agbára rẹ hàn nípasẹ
ìwàásù wọn.


MAKU 16:20
[20]Nwọn si jade lọ, nwọn si nwasu nibigbogbo, Oluwa si mba wọn ṣiṣẹ, o si nfi idi ọ̀rọ na kalẹ, nipa àmi ti
ntẹ̀le e. Amin.


Iṣẹ Àmín àti agbára kìíse àjèjì sí ìwàásù ọrọ Ọlọrun rárá àti rárá.


HEBERU 2:3-4
[3]Awa o ti ṣe là a, bi awa kò ba nani irú igbala nla bi eyi; ti àtetekọ bẹ̀rẹ si isọ lati ọdọ Oluwa, ti a si fi mulẹ
fun wa lati ọdọ awọn ẹniti o gbọ́;
[4]Ọlọrun si nfi iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu, ati onirũru iṣẹ agbara, ati ẹ̀bun Ẹmí Mimọ́bá wọn jẹri gẹgẹ bí ifẹ rẹ̀?


Iṣẹ Àmín jẹ ohun tí Ọlọrun fi máa n pe àkíyèsí awọn ènìyàn sí ìwàásù ihinrere rẹ ni ayé yìí. A rí èyí ní ọjọ
Pentikosti nígbà tí Èmi Mimọ Sọkalẹ tí àwọn ènìyàn sì bẹrẹ sí níí rí iṣẹlẹ kayefi nla tó ṣe iyalenu fún wọn.
Pétérù lo anfààní náà láti wàásù ìhìnrere Kristi fún àwọn tó pejọ ni ọjọ náà a sì ri wipe awọn ènìyàn gbagbọ
nínú nínú nkan tí Pétérù n sọ.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 2:37,41
[37]Nigbati nwọn si gbọ́, ọkàn wọn gbọgbẹ, nwọn si sọ fun Peteru ati awọn aposteli iyokù pe, Ará, kini ki awa
ki o ṣe?
[41]Nitorina awọn ti o si fi ayọ̀gbà ọ̀rọ rẹ̀a baptisi wọn: li ọjọ na a si kà ìwọn ẹgbẹdogun ọkàn kún wọn.

Iṣẹ iransẹ Pétérù lagbara nitoripe agbára Ọlọrun kò sọwọn nínú iṣẹ iransẹ rẹ. Awọn kan máa n sọ wípé ìdí tó
fi rí béè ní wípé Aposteli ní Peteru jẹ gẹgẹ bí ọmọlẹyìn Kristi tó rí Kristi Jésù gan fúnra rẹ lojukokoro. Kíi ṣe
nítorí èyí ni ìṣe àmín ṣe ṣẹlẹ nínú iṣẹ iransẹ rẹ.


Nígbàtí Peteru n sọ nípa agbára Ọlọrun ati gbigba Èmi Mimọ rẹ, ohun tó sọ fún àwọn ènìyàn kìíse wípé bóyá
nitoripe ibasepọ tó wà láàrin rẹ àti Ọlọrun ló yatọ sugbon wípé gbogbo ẹnikẹni tó bá tí gbagbọ nínú Kristi ni
èyí wà fún.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 2:39
[39]Nitori fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jìna rére, ani gbogbo awọn ti
Oluwa Ọlọrun wa ó pè.


Nítorínaa fún gbogbo wa patapata ni ifarahan agbára Ọlọrun wà fún

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading