Ọjọ́ Kẹrinlélógún (24), Ọjọ́ Ẹtì , Osù Kejì , Ọdún 2023

ÀLÀYÉÌWÉGALATIAL’ẸŚẸẸSẸ(10)

A ti sàlàyé wípé sí àwọn ikọla àti aláikola ni Ọlọrun rán Paulu sí gẹgẹ bó ṣe ran àwọn Aposteli yòókù náà O ṣe pàtàkì kí a sọ wípé a lè ran onígbàgbọ tàbí iransẹ Ọlọrun sí ìbi tí Ọlọrun bá ni lokan. Nitorina kìíse dandan wipe Ọlọrun ran gbogbo ènìyàn sí ibi kan náà. Ohun tí a gbọdọ mọ ni wípé lootọ Ọlọrun lè rán olúkúlùkù wa sí ìbi tó bá wuu, ohun tí Ọlọrun kìíse ni wipe kí o fi iṣẹ tó yàtọ rán wa. Iṣẹ kan náà ni Olorun fún gbogbo wa patapata

Kò sí ohunkóhun tó jọ mọ wipe iṣẹ iransẹ temi yatọ sí ti gbogbo ènìyàn nitoripe ohun tí Ọlọrun fi ran mi yatọ sí ti gbogbo ènìyàn. Kò sí ẹnikẹ́ni tí Kristi Jésù pè sí kọ̀rọ̀ yàrá tàbí sí ẹgbẹ kan láti le sọ wípé iṣẹ iransẹ tirẹ gẹgẹ bí ọmọlẹyìn tàbí Aposteli rẹ, yatọ sí ti awọn omolehin rẹ míràn. Nigbati Jésù mọọmọ pe orukọ Peteru láti bọ awọn aguntan rẹ , kò sọ wípé irú oúnjẹ báyìí báyìí ni kí o máa fi bọ awọn aguntan náà nitoripe kò nilo láti sọ bẹẹ. Irú oúnjẹ kan péré ló wà nípa ti Ẹmi èyí náà sì ni ọrọ Ọlọrun. O ti sọ èyí fún gbogbo ọmọlẹyìn rẹ nígbà tí o b’awọn sọrọ ní gbangba.

Gbogbo awọn tó kọ ihinrere kọọkan ló ṣe amenuba ohun tí Jésù ní kí wọn máa wàásù.

MAKU 16:15
[15]O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ si gbogbo aiye, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda.

Ó ní kí wọn máa wàásù ìhìnrere.

MATIU 28:20
[20]Ki ẹ ma kọ́ wọn lati ma kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa li aṣẹ fun nyin: ẹ si kiyesi i, emi wà pẹlu nyin nigbagbogbo, titi o fi de opin aiye. Amin.

O ní kí wọn máa wàásù ohun gbogbo to ti pa lasẹ fún wọn.

Nitorina kò sí ẹnikẹ́ni tó ní ihinrere tirẹ. Paulu náà kò ní ihinrere tirẹ bikòṣe ihinrere ti Kristi.
Nitoripe ìwé Galatia ni a n gbìyànjú láti ni òye rẹ. Ó dára kí a fi dá wa lójú wípé ẹni tó kọ ìwé yìí gba isipaya láti ọwọ Ọlọrun. Awọn ìwé tí àwọn wòlíì kọ, òun tó ṣe pàtàkì jùlọ ni wipe nípa isipaya Èmi Mimọ ni a fi kọ wọn.

PETERU KEJI 1:20-21
[20]Ki ẹ kọ́ mọ̀ eyi, pe kò si ọ̀kan ninu asọtẹlẹ inu iwe-mimọ́ ti o ni itumọ̀ ikọkọ.
[21]Nitori asọtẹlẹ kan kò ti ipa ifẹ enia wá ri; ṣugbọn awọn enia nsọrọ lati ọdọ Ọlọrun bi a ti ndari wọn lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ wá.

Paulu náà ni Èmi Mimọ, nítorínaa, O ní ìmísí Ọlọrun nínú àwọn ẹkọ àti àkọsílẹ̀ rẹ

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 9:17
[17]Anania si lọ, o si wọ̀ ile na; nigbati o si fi ọwọ́ rẹ̀ le e, o ni, Saulu Arakunrin, Oluwa li o rán mi, Jesu ti o fi ara hàn ọ li ọ̀na ti iwọ ba wá, ki iwọ ki o le riran, ki o si kún fun Ẹmí Mimọ́.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading