Ọjọ́ Kẹrinla (14), Ọjọ́ Ìsẹǵ un , Osù Kejì , Ọdún 2023

KRISTẸNI GẸGẸ BÍ IMỌLẸ (6)

Báwo ní Ọlọrun ṣe pinnu wípé a o máa fi ìfẹ hàn sí àwọn ènìyàn?
Ní akọkọ o ṣe pàtàkì kí a mọ gẹgẹ bí onigbagbọ wípé ìfẹ sí Ọlọrun àti ìfẹ sí ọmọnikeji nkan kan náà ni.

JOHANU KINNI 4:20
[20]Bi ẹnikẹni ba wipe, Emi fẹran Ọlọrun, ti o si korira arakunrin rẹ̀, eke ni: nitori ẹniti kò fẹran arakunrin rẹ̀ ti o ri, bawo ni yio ti ṣe le fẹran Ọlọrun ti on kò ri?

Ìdí èyí ló fàá tí Jésù kò fún àwọn ọmọlẹyìn rẹ ní ìlànà tabi ofin láti fẹ Ọlọrun nítorípé oun tó n jẹ wípé ènìyàn n fẹ Ọlọrun ni wipe o fẹràn ọmọnikeji rẹ. Ọpọlọpọ máa n rò wípé bí àwọn bá ṣe máa n lọ sí ilé ìjósìn tó lo fihàn nípa bí àwọn ṣe fẹràn Ọlọrun tó. Kò rí bẹ́ẹ̀ ràrá. Ọna ti a fi lè mọ wipe lootọ ni a fẹ Ọlọrun ni wipe a fẹràn ọmọnikeji.

Ẹkọ tí Jòhánù Olufẹ gbé jáde nínú ẹsẹ tí a tọkasi yìí jẹ ohun tó kọ láti ara Jésù Kristi gan funrararẹ.

MATIU 25:36-40
[36]Mo wà ni ìhoho, ẹnyin si daṣọ bò mi: mo ṣe aisan, ẹnyin si bojuto mi: mo wà ninu tubu, ẹnyin si tọ̀ mi wá.
[37]Nigbana li awọn olõtọ yio da a lohun wipe, Oluwa, nigbawo li awa ri ti ebi npa ọ, ti awa fun ọ li onjẹ? tabi ti ongbẹ ngbẹ ọ, ti awa fun ọ li ohun mimu?
[38]Nigbawo li awa ri ọ li alejò, ti a gbà ọ si ile? tabi ti iwọ wà ni ìhoho, ti awa daṣọ bò ọ?
[39]Tabi nigbawo li awa ri ti iwọ ṣe aisan, ti a bojuto ọ? tabi ti iwọ wà ninu tubu, ti awa si tọ̀ ọ wá?
[40]Ọba yio si dahùn yio si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakunrin mi wọnyi ti o kere julọ ẹnyin ti ṣe e fun mi.

Jésù fihàn kedere wipe ohun tí a n ṣe fún ènìyàn ni a n ṣe fún Ọlọrun. Nitorina a kò lè kòrira arakunrin wa tàbí arábìnrin wa tàbí ọkọ tàbí ìyàwó tàbí alabagbe, tàbí alabaṣiṣẹpọ wa kí a wá lọ sínú ìjọ Ọlọrun kí a sọ wípé a fẹràn Ọlọrun. Ojú tí Ọlọrun yóò fi máa wò wá náà ni wipe a kòrira ohun.

Ìgbà miran wà tó jẹ wípé a maa ṣe awawi wípé àwon ènìyàn náà hùwa búburú sí wa ṣùgbọ́n awawi lásán ni eyí

Ọlọrun mọ nkan tó wà nínú eniyan

JOHANU 2:25
[25]On ko si wa ki ẹnikẹni ki o jẹri enia fun on: nitoriti on mọ̀ ohun ti mbẹ ninu enia.

Ọlọrun mọ wipe awọn ènìyàn burú sibẹ o ní wípé kí a fi ìfẹ hàn sí wọn. Nítorínaa oju tó yẹ kí onigbagbọ fi máa wòó ni wipe ohun tí a n ṣe, Ọlọrun ni a n ṣe fún kìíse ènìyàn.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading