Ọjọ́ Kẹrinla (14), Ọjọ́ Àbámẹ́ta, Oṣù Kíní , Ọdún 2023

BI ỌLỌRUN ṢE N DARÍ ONIGBAGBỌ (6)

BI ỌLỌRUN ṢE N DARÍ ONIGBAGBỌ (6)


Nínú ìgbàgbọ nínú Kristi, onigbagbọ máa n dàgbà síi ni. Ìrètí Ọlọrun ni wipe bí a ṣe n gbọ ọrọ rẹ, a o máa
dagbasoke síi nípa ti Èmi.


PETERU KEJI 3:18
[18]Ṣugbọn ẹ mã dàgba ninu õre-ọfẹ ati ninu ìmọ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi; ẹniti ogo wà fun nisisiyi
ati titi lai. Amin.


Bí a ṣe n dagbasoke si nínú ìmọ, ìrètí Ọlọrun ni wipe ìdàgbàsókè wa nínú Èmi yóò máa farahàn nípa bí a ṣe n
gbọ láti ọdọ Ọlọrun. Ìbí kan ni èèyàn tí maa ni bẹrẹ. Fún àpẹẹrẹ, tí a bá fẹ gbọ ohùn Ọlọrun lórí nkan kan
pàtó, kìíse ìgbà yen gan-an ni a ó bẹrẹ sí níí kọ́bí a ṣe n gbọ ohùn Ọlọrun. Ní ọpọlọpọ ìgbà, Ọlọrun máa n bá
wa sọrọ nipasẹ ìwàásù kan tàbí òmíràn tí a n gbọ, ìgbà míràn nípa ẹsẹ Bíbélì kan tabi omiran ni yóò fi bá wa
sọrọ. Ṣugbọn ti a kò bá kobi ara sí àwọn ọnà yìí, ọna ti a n retí wípé yóò fi bá wa sọrọ kò ní rí bẹẹ́ ̀. Ẹnikẹni tí
kò bá já ọrọ Ọlọrun tí a kọ sílẹ kunra, kò níí já ohun Ọlọrun náà kunra nitoripe Ọlọrun kan náà tó fún àwọn tó
kọ Bíbélì ní isipaya náà ni a fẹ gbọ láti ọdọ rẹ.


Tí a bá fi àwọn Aposteli Kristi ṣe àpẹẹrẹ lẹhin àjínde Kristi, nígbàtí wọn kọkọ fẹ yan ẹlòmíràn láti rọpo Júdásì
nínú iṣẹ iransẹ, ẹ wo ọna ti wọn gbà.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 1:23,26
[23]Nwọn si yàn awọn meji, Josefu ti a npè ni Barsabba, ẹniti a sọ apele rẹ̀ni Justu, ati Mattia.
[26]Nwọn si dìbo fun wọn; ìbo si mu Mattia; a si kà a mọ awọn aposteli mọkanla.


Njẹ a ri wipe wọn dibò yan ẹni tí yóò rọ́pò Júdásì ni? Kìíse ìfẹ Ọlọrun pípé wípé wọn yóò máa dibò yan awọn
ènìyàn sínú iṣẹ iransẹ ṣugbọn nitoripe ipele tí ìdàgbàsókè wọn wà nínú iṣẹ iransẹ àti igbesiaye Kristẹni nígbà
náà nìyẹn, wọn dibò. Lẹhin èyí, kò sí ìbi kánkan mọ tí wọn tún ti dibo yan ẹnikẹni.
Tí a bá tún wo ìgbà míràn tí wọn yan awọn ènìyàn sínú iṣẹ iransẹ, ẹ jẹ kí a wo ọna tí wọn gbà ṣe èyí.

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 6:3-5
[3]Nitorina, ará, ẹ wo ọkunrin meje ninu nyin, olorukọ rere, ẹniti o kún fun Ẹmí Mimọ́ati fun ọgbọ́n, ẹniti
awa iba yàn si iṣẹ yi.
[4]Ṣugbọn awa o duro ṣinṣin ninu adura igbà, ati ninu iṣẹ iranṣẹ ọ̀rọ na.
[5]Ò rọ na si tọ́loju gbogbo ijọ: nwọn si yàn Stefanu, ọkunrin ti o kún fun igbagbọ́ati fun Ẹmí Mimọ́, ati Filippi
ati Prokoru, ati Nikanoru, ati Timoni, ati Parmena, ati Nikola alawọṣe Ju ara Antioku:


Ní ibi kíkà yìí, wọn lo àwọn ohun àmúyẹ tí onigbagbọ gbọdọ ní láti ṣe iṣẹ Ọlọrun. Ó gbọdọ kún fún Èmí Mimọ
ati ọgbọn. Ìpele míràn ni èyí nitoripe ní àkókò yíì, wọn kò dibò bíi ti akọkọ. Lẹhin iṣẹlẹ yìí, a tún rí ìgbà míràn
tí wọn yan awọn ènìyàn sínú iṣẹ iransẹ.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 13:2
[2]Bi nwọn si ti njọsìn fun Oluwa, ti nwọn si ngbàwẹ, Ẹmí Mimọ́wipe, Ẹ yà Barnaba on Saulu sọtọ̀fun mi fun
iṣẹ ti mo ti pè wọn si.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading