Ọjọ́ Kẹrìndínlógún (16), Ọjọ́bọ̀ , Osù Kejì , Ọdún 2023

KRISTẸNI GẸGẸ BÍ IMỌLẸ (9)

Ní àna a n sọ nípa òfin titun tí Jésù fi le’lẹ . Láti lè jẹ kí a mọ wipe èyí yatọ sí òfin Mósè, Jésù péé ní òfin titun. Tó bá jẹ wípé nkan kan náà tí Mósè ti sọ naa ni Jésù n tún sọ ni, Jésù kò níí sọ wípé titun ni.

JOHANU 13:34-35
[34]Ofin titun kan ni mo fifun nyin, Ki ẹnyin ki o fẹ ọmọnikeji nyin; gẹgẹ bi emi ti fẹran nyin, ki ẹnyin ki o si le fẹran ọmọnikeji nyin.
[35]Nipa eyi ni gbogbo enia yio fi mọ̀ pe, ọmọ-ẹhin mi li ẹnyin iṣe, nigbati ẹnyin ba ni ifẹ si ọmọnikeji nyin.

Tí a bá fi ofin yii we nkan tí ofin Mósè sọ nípa ìfẹ sí ọmọnikeji, a o ri wípé kìíse nkan kan náà.

DIUTARONOMI 6:5
[5]Ki iwọ ki o si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ.
LEFITIKU 19:18
[18]Iwọ kò gbọdọ gbẹsan, bẹ̃ni ki o máṣe ṣe ikùnsinu si awọn ọmọ enia rẹ, ṣugbọn ki iwọ ki o fẹ́ ẹnikeji rẹ bi ara rẹ: Emi li OLUWA.

Ọna méjì tí òfin Mósè ti sọrọ nípa ìfẹ ni èyí. Nitorina òfin Mósè fi iyatọ sí àárín ìfẹ sí Ọlọrun àti ìfẹ sí ọmọnikeji, o sì gba awọn ènìyàn niyanju láti fẹràn ọmọnikeji gẹgẹ bí ara wọn. Ṣugbọn tí a bá wo òfin Kristi, o sọ wípé kí a fẹ ọmọnikeji wa gẹgẹ bí òun ti fẹ wa. Èyí ló n sọ fún wa wípé labẹ òfin Kristi, òye bí Kristi ṣe fẹ wa kọkọ gbọdọ yé wa, lẹhin ìgba náà ni a lè fẹ ọmọnikeji wa gẹgẹ bí Kristi ṣe fẹ wa.
Nitorinà, ìbéèrè tó yẹ kí a béèrè lọwọ ara wa ni wípé báwo ni Kristi ṣe fẹ wa? Ìdáhùn èyí wà nínú Episteli sí àwọn ará Rómù.

ROMU 5:6-8
[6]Nitori igbati awa jẹ alailera, li akokò ti o yẹ, Kristi kú fun awa alaiwa-bi-Ọlọrun.
[7]Nitori o ṣọ̀wọn ki ẹnikan ki o to kú fun olododo: ṣugbọn fun enia rere boya ẹlomiran tilẹ le dába ati kú. [8]Ṣugbọn Ọlọrun fi ifẹ On papa si wa hàn ni eyi pe, nigbati awa jẹ ẹlẹṣẹ, Kristi kú fun wa.

Awọn akiyesi pataki tí a lè rí kọ nínú abala tí a tọkasi yìí ni wipe ní ìgbà tí a jẹ ọta Ọlọrun nipasẹ aigbagbọ nínú rẹ, nígbàtí a kò yẹ ní ẹni tó yẹ láti fi ìfẹ hàn fún ni Kristi ti kú fún wa. Kristi san ìyè tó pọju fún wa nipasẹ wipe a fi Emi rẹ rúbọ fún àwa tí kò yẹ rárá. Nitorina ìfẹ Kristi kò niiṣe pẹlu bí àwọn ènìyàn tí hùwa sí wa.

Inú wa máa n dùn gẹgẹ bí ènìyàn tí a bá sọ nípa bí Ọlọrun ṣe fẹ wa pẹlu ifẹ nlá alailẹgbẹ ṣugbọn a máa n gbàgbé ni ọpọlọpọ ìgbà wípé àwa náà ní ojúṣe láti fi irú ìfẹ kan náà hàn fún àwọn ènìyàn.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading