Ọjọ́ Kẹrìndínlógún (16), Ọjọ́ Ajé , Oṣù Kíní , Ọdún 2023

ÒFIN TÍTÚN TI KRISTI (1)

ÒFIN TÍTÚN TI KRISTI (1)


Mósè fi ofin fún àwọn ọmọ Israẹli gẹgẹ bí adari wọn. Ní ìgbà míràn ninu òfin, O n sọ fún wọn nípa ìwà tó lè
jẹ ki wọn le máa gbé ní irẹpọ láwùjọ ara wọn nígbà náà. Awọn ofin náà niiṣe pẹlu ibaṣepọ láàrin àwọn
ènìyàn.


Gẹgẹ bí ọmọ Israẹli, dandan ni fún wọn láti mọ òfin náà kí wọn sì máa gbọran si. Tí wọn bá gbọran si, ìbùkún
wà níbè, bẹẹ náà ni egún wà níbè ti won bá ṣe aigbọran sí òfin náà.


JOṢUA 1:8
[8]Iwé ofin yi kò gbọdọ kuro li ẹnu rẹ, ṣugbọn iwọ o ma ṣe àṣaro ninu rẹ̀li ọsán ati li oru, ki iwọ ki o le kiyesi
ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ sinu rẹ̀: nitori nigbana ni iwọ o ṣe ọ̀na rẹ ni rere, nigbana ni yio si dara fun ọ.

DIUTARONOMI 28:15
[15]Yio si ṣe, bi iwọ kò ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi ati ṣe gbogbo aṣẹ rẹ̀ati ìlana rẹ̀ti mo
filelẹ fun ọ li oni; njẹ gbogbo egún wọnyi yio ṣẹ sori rẹ, yio si bá ọ.

Nitorina awọn tó bá fẹ ṣe rere láàrin wọn, òfin yìí ni wón máa fi n ṣe àṣàrò.

ORIN DAFIDI 119:97
[97]Emi ti fẹ ofin rẹ to! Iṣaro mi ni li ọjọ gbogbo.

Gẹgẹ bíi Kristẹni a kò ní ojúṣe láti tẹlé awọn ọfin náà nítorípé àwọn ọmọ Israẹli ni a fi òfin náà fún labẹ iṣẹ
iransẹ Mósè. Awọn ọmọ Israẹli gan náà láyè òde òní kò ní ojúṣe láti tẹlé awọn ọfin yìí nítorípé ẹnikẹni tó bá ti
wà nínú Kristi, Kristi ti di òpin ofin fún irú ẹni bẹẹ, àti wipe awọn nkan tí òfin náà kò lágbára láti ṣe ni o ṣẹlẹ
nínú ikú àti àjínde rẹ fún wa.

ROMU 10:4
[4]Nitori Kristi li opin ofin si ododo fun olukuluku ẹniti o gbagbọ

Nkan kan wà tí ènìyàn nilo láti wà ní àlàáfíà pẹlú Ọlọrun, òfin Mósè kò lágbára láti ṣe èyí.

ROMU 8:3
[3]Nitori ohun ti ofin kò le ṣe, bi o ti jẹ alailera nitori ara, Ọlọrun rán Ọmọ on tikararẹ̀li aworan ara ẹ̀ṣẹ, ati bi
ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ, o si da ẹ̀ṣẹ lẹbi ninu ara:

Kíni ohun tí òfin ko lagbara láti ṣe

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 13:39
[39]Ati nipa rẹ̀li a ndá olukuluku ẹniti o gbagbọ lare kuro ninu ohun gbogbo, ti a kò le da nyin lare ninu ofin
Mose.

Idanilare ni ohun tí òfin Mósè kò lè ṣe.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading