Ọjọ́ Kérìndínlọgbọ̀n (26), Ọjọ́bọ̀, Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

ÀLÀYÉ ÌWÉ GALATIA L’ẸSẸẸSẸ (1)

Ìjọ Ọlọrun tó wà ní Galatia jẹ ọkan lára àwọn ìjọ tí Paulu kọwe sí. Ìbínú ni Paulu fi kọ lẹta náà nítorí àwọn
nkan tó n lọ láàrin wọn. Kìíse wípé ẹsẹ ló n lọ láàrin ṣugbọn ẹkọ òdì ni. Ewu tó wà nínú ẹkọ òdì ni wípé yóò
yori sí àwọn ìwà tí kò t’ọna ní ikehin náà ni. Nítorínaa, tí a bá n ka Episteli náà, o ṣe pàtàkì kí a f’ọkan sí àwọn
nkán tí Paulu n ba wọn wí fún. Nítorínaa, a o bẹrẹ àlàyé àwọn ẹkọ tí a fẹ kọ nípa iwe yìí láti inú lẹta rẹ sí wọn
orí kíni.


GALATIA 1:1
[1]PAULU, Aposteli (ki iṣe lati ọdọ enia wá, tabi nipa enia, ṣugbọn nipa Jesu Kristi, ati Ọlọrun Baba, ẹniti o


Gbogbo ìgbà tí Paulu bá tí fẹ kọ lẹta sí àwọn ìjọ Ọlọrun ló máa n sàlàyé ẹni tó jẹ, o sì máa n pe ara rẹ ní
Aposteli. Ìdí rẹ ni wipe awọn ènìyàn fe mọ bóyá O ní ẹtọ láti ṣe ikoni tó n ṣe. Ìdí rẹ ní wípé ìjọ Ọlọrun ṣẹṣẹ
bẹrẹ ni ayé ìgbà náà ni, ìyẹn ìgbàgbọ Kristẹni. Nitorinà ọpọlọpọ awọn ẹkọ ló n fo káàkiri, o sì ṣe pàtàkì kí
ẹnikẹ́ni tí yóò bá ṣe ikoni ní àṣẹ láti ṣe ikoni náà nitoripe awọn Aposteli nìkan ló ni aṣẹ láti ṣe ẹkọ nípa ìpìlẹ
ìgbàgbọ Kristẹni. Nítorí èyí ló fi jẹ wípé titi di oni oloni yìí, awọn ẹkọ wọn ni a sì n tẹle, kò si sí ẹnikẹ́ni láyé
òde òni tó ní ẹtọ láti kọ ohunkohun tí àwọn Aposteli kò kọ nínú ẹkọ wọn.


EFESU 2:20
[20]A si ngbé nyin ró lori ipilẹ awọn aposteli, ati awọn woli, Jesu Kristi tikararẹ̀jẹ pàtaki okuta igun ile;


Lootọ Paulu kò sí níbẹ nígbà iṣẹ iransẹ Jésù láàrin àwọn Júù, tí àwọn ọmọlẹyìn rẹ sí n tẹle fún iṣẹ iransẹ
ṣugbọn awọn kan wà níbè nígbà náà, Jésù sì ṣe ìlérí wípé Èmi Mimọ yóò fi àwọn nkán tí òun kò ní anfààní láti
sọ fún wọn, yé wọn.


JOHANU 16:13-15
[13]Ṣugbọn nigbati on, ani Ẹmí otitọ ni ba de, yio tọ́nyin si ọ̀na otitọ gbogbo; nitori kì yio sọ̀ti ara rẹ̀; ṣugbọn
ohunkohun ti o ba gbọ́, on ni yio ma sọ: yio si sọ ohun ti mbọ̀fun nyin.
[14]On o ma yìn mi logo: nitoriti yio gbà ninu ti emi, yio si ma sọ ọ fun nyin.
[15]Ohun gbogbo ti Baba ni temi ni: nitori eyi ni mo ṣe wipe, on ó gbà ninu temi, yio si sọ ọ fun nyin.

Nitorinà ẹnikẹni tí yóò ṣe ikoni gbọdọ gba àṣẹ lọwọ àwọn tó wà níbẹ nígbà náà. Pàápàá jùlọ àwọn tí Jésù gbé
iṣẹ le lọwọ. Nitorinà Ẹ jẹ kí a wo ibasepọ tó wà láàrin Paulu àti àwọn tí Jésù gbé iṣẹ náà le lọwọ.


PETERU KEJI 3:15-16
[15]Ki ẹ si mã kà a si pe, sũru Oluwa wa igbala ni; bi Paulu pẹlu, arakunrin wa olufẹ, ti kọwe si nyin, gẹgẹ bi
ọgbọ́n ti a fifun u;
[16]Bi o ti nsọ̀rọ nkan wọnyi pẹlu ninu iwe rẹ̀gbogbo; ninu eyi ti ohun miran ti o ṣòro lati yéni gbé wà, eyiti
awọn òpè ati awọn alaiduro nibikan nlọ́, bi nwọn ti nlọ́iwe mimọ́iyoku, si iparun ara wọn.


Nitorina, o dájú wípé Peteru pe awọn ohun tí Paulu n kọ gẹgẹ bí ẹkọ ní ìwé mímọ, nípa bẹẹ o fi ontẹ Lu awọn
ẹkọ náà

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading