Ọjọ́ Kérìndínlọgbọ̀n (26), Ọjọ́ Àìkú , Osù Kejì , Ọdún 2023

ÀLÀYÉÌWÉGALATIAL’ẸŚẸẸSẸ(12)

Tí a bá pin Majẹmu Titun sí ìdá mẹta, ìdá méjì níbẹ, Paulu lo kọọ́. Ọpọ ẹkọ àti ìgbàgbọ Kristẹni lóde òní, orí awọn ẹkọ tí Paulu kọ ni a gbe le. Kilode? Ìgbà míràn tí àwọn míràn máa n woye wípé kilode ti ọpọlọpọ awọn oníwàásù máa n tọkasi akọsilẹ rẹ ní ọpọlọpọ ìgbà.

Ohun tó yẹ kí a mọ dájúdájú ni wípé ìgbàgbọ Kristẹni bẹrẹ pẹlu àjínde Kristi. Ìgbàgbọ nínú àjínde Kristi ni ohun tí a n pè ní ìgbàgbọ Kristẹni.

KỌRINTI KINNI 15:12-14
[12]Njẹ bi a ba nwasu Kristi pe o ti jinde kuro ninu okú, ẽhatiṣe ti awọn miran ninu nyin fi wipe, ajinde okú kò si?
[13]Ṣugbọn bi ajinde okú kò si, njẹ Kristi kò jinde:
[14]Bi Kristi kò ba si jinde, njẹ asan ni iwãsu wa, asan si ni igbagbọ́ nyin pẹlu.

Idariji ẹsẹ tó wà nínú ikú ati ajinde Kristi ni ihinrere. Ìhìnrere ni wipe Ọlọrun kò níí ka ẹsẹ àti aiṣedede sí wa lọrùn nitoripe a ti san gbese ẹsẹ wa nipasẹ ikú àti àjínde rẹ.

HEBERU 9:22
[22]O si fẹrẹ jẹ́ ohun gbogbo li a fi ẹ̀jẹ wẹ̀nu gẹgẹ bi ofin; ati laisi itajẹsilẹ kò si idariji.

Nitorina àjínde Kristi jẹ sáà titun nínú ayé yìí. Ìkéde Idariji ẹsẹ tí a fi ẹjẹ Jesu ṣe ni ìròyìn rere. Èyí ni ohun tí Jésù n sọ fún wọn wípé wọn kò lè gba nígbà ko too lọ sórí igi agbelebu. Ṣugbọn o sọ wípé Èmi Mimọ yóò sàlàyé rẹ fún wọn.

JOHANU 16:12-13
[12]Mo ni ohun pipọ lati sọ fun nyin pẹlu, ṣugbọn ẹ kò le gbà wọn nisisiyi.
[13]Ṣugbọn nigbati on, ani Ẹmí otitọ ni ba de, yio tọ́ nyin si ọ̀na otitọ gbogbo; nitori kì yio sọ̀ ti ara rẹ̀; ṣugbọn ohunkohun ti o ba gbọ́, on ni yio ma sọ: yio si sọ ohun ti mbọ̀ fun nyin.

Kilode ti wọn kò lè gba nígbà náà? Nitoripe iṣẹlẹ tí Èmi Mimọ yóò lo láti sàlàyé ohun tó wà lọkàn Ọlọrun lati ìbẹrẹ kò tíì ṣẹlẹ. Olóore àti alaanu tó n darí ẹsẹ jinni ni Ọlọrun jẹ

ORIN DAFIDI 103:3
[3]Ẹniti o dari gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ jì; ẹniti o si tan gbogbo àrun rẹ,

Ọna tí Ọlọrun yóò fi ṣe èyí kò tíì ṣẹlẹ nígbà náà. Nítorí ìdí èyí ni Jésù sọ wípé Èmi Mimọ yóò kọ wọn nípa òun. Ikú rẹ àti àjínde rẹ àti ohùn tó jasi nínú ayé ọmọ eniyan ni ohun tí Èmi Ọlọrun yóò sí ojú ènìyàn sí. Awọn nkan náà ni Paulu kọ sínú àwọn ìwé rẹ, ọkan nínú àwọn ẹkọ náà ni ìwé Galatia èyí tí a n sàlàyé. Ìdí èyí ni awọn ẹkọ labẹ iṣẹ iransẹ Paulu fi ṣe pàtàkì lọpọlọpọ fún onigbagbọ. Wọn jẹ awọn Ìdánilẹkọ nípa Kristi Jésù, nípa àwọn nkan tó wà fún wa ṣùgbọ́n tí kò sọ nípa ara rẹ ṣugbọn tí Èmi Ọlọrun siju awọn Aposteli gẹgẹ bíi Paulu láti rí àti láti kọ gẹgẹ bí ẹkọ.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading