Ọjọ́ Kẹrin (4), Ọjọ́rú , Oṣù Kíní , Ọdún 2023

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ WA NIPA AAWẸ̀(4)

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ WA NIPA AAWẸ̀(4)


Ìbéèrè pàtàkì tó yẹ kí a bi ara wa leere ni wípé nítorí kì ni a fi n gba aawẹ̀? Labẹ Majẹmu Lailai, a rí òpòlopò
ìgbà tí àwọn ènìyàn gba aawẹ̀. Ẹkọ wà tó yẹ kí a kọ níbẹ. Ọkan nínú ohun ti a lè ṣakiyesi nípa aawẹ̀wọn ni
wipe ní ọpọlọpọ ìgbà awọn eniyan máa n fi aawẹ̀rẹ ara wọn sílẹ níwájú Olúwa. Èyí túmò sí wipe wọn máa n
lo anfààní aawẹ̀láti wá ojú Oluwa. Ìgbà míràn wà tó jẹ wípé boya wọn ti dá ẹsẹ kan tàbí òmíràn. Ìgbà míràn
wà tó jẹ wípé wọn ní ìṣòro. A sì rí ìgbà tó jẹ wípé wọn n lòó láti ronupiwada kúrò nínú àwọn ẹsẹ àti
aisedeede wọn.


Nitorinaa a o ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Bíbélì tó fihàn wá nípa àwọn ìhà tí àwọn ènìyàn kọ sí aawẹ̀labẹ
Majẹmu láilái.

JOẸLI 2:12
[12]Njẹ nitorina nisisiyi, ni Oluwa wi, Ẹ fi gbogbo ọkàn nyin yipada si mi, ati pẹlu ãwẹ̀, ati pẹlu ẹkún, ati pẹlu
ọ̀fọ.

Nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, wòlíì Joeli n sọ fún àwọn Isreali láti ronupiwada. Gẹgẹ bí a ṣe ṣàlàyé lánàá, ironupiwada
niiṣe pẹlu ọkàn, bẹẹ náà ni aawẹ̀jẹ. Nípa èyí, aawẹ̀máa n jẹyọ nínú ironupiwada nígbà miran. Ẹ jẹ kí a mọ
dájúdájú wipe kìíse wipe tí a bá kọ láti jẹun ni yóò mú kí Ọlọrun d’áríjì wá. Labẹ Majẹmu Titun, a ní Idariji ẹsẹ
nipasẹ ẹjẹ Jésù.

EFESU 1:7
[7]Ninu ẹniti awa ni irapada wa nipa ẹjẹ rẹ̀, idariji ẹ̀ṣẹ wa, gẹgẹ bi ọrọ̀ore-ọfẹ rẹ̀;

Ẹjẹ Jésù ló fún wa ní Idariji ẹsẹ. Kìíse bẹẹ nìkan, otito ati ododo Ọlọrun wà lẹhin Idariji ẹsẹ fun wa gẹgẹ bí
onigbagbo.


JOHANU KINNI 1:9
[9]Bi awa ba jẹwọ ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ ati olododo li on lati dari ẹṣẹ wa jì wa, ati lati wẹ̀wa nù kuro ninu aiṣododo
gbogbo.


Nitorinaa, aawẹ̀kìíse ọna tí a fi n parọwa sí Ọlọrun láti d’áríjì wá tàbí ọna tí a fi n sọ fún Ọlọrun wipe
ironupiwada wa jẹ ojúlówó ati wipe okan wa ló ti wá. Ọlọrun mọ ohun tó n lọ lokan wa. Nitorinaa ti a bá n
gba aawẹ̀nígbà tí a n ronupiwada, fún ara wa ló wà fún kìíse fún Ọlọrun.

A rí àwọn àpẹẹrẹ miran náà labẹ Majẹmu láéláé.


NEHEMAYA 1:4
[4]O si ṣe nigbati mo gbọ́ọ̀rọ wọnyi, mo joko, mo si sọkun, mo si ṣọ̀fọ ni iye ọjọ, mo si gbãwẹ, mo si gbàdura
niwaju Ọlọrun ọrun.


Aawẹ̀tí Nehemaya gbà niiṣe pẹlu ẹdun ọkan rẹ

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading