Ọjọ́ Kẹrin (4), Ọjọ́ Àbámẹ́ta, Oṣù Kejì , Ọdún 2023

IGBỌWỌLÈ ÀTI IṢẸ IRANSẸ (4)

IGBỌWỌLÈ ÀTI IṢẸ IRANSẸ (4)


Ó ní ọnà tí Ọlọrun fi máa n pèsè wa silẹ fún iṣẹ iransẹ. Njẹ a tilẹ mọ wipe bí a ṣe bí wa nípa ti Ẹmi dà bí ìgbà tí
a bá bí ènìyàn nípa ti ara náà ni? Orisirisi ẹbùn amutorunwa ni ọmọ lè ní, bii ẹbùn ayàwòrán, akọrin àti bẹẹ
bẹẹ lọ ṣugbọn kìíse gbogbo awọn ẹbun yìí ni yóò bẹrẹ sí níí jẹyọ ni gẹ́lẹ́tí a bá ti bí ọmọ náà. O nilo lati
dagbasoke. Jésù Olúwa wa gan fúnra rẹ, kò bẹrẹ iṣẹ iransẹ nígbà tó wà ní ọmọde, Ó n kẹkọọ, O sì n béèrè
ìbéèrè ni.


LUKU 2:46,52
[46]O si ṣe, lẹhin ijọ mẹta nwọn ri I ninu tẹmpili o joko li arin awọn olukọni, o ngbọ́ti wọn, o si mbi wọn
lẽre.
[52]Jesu si npọ̀li ọgbọ́n, o si ndàgba, o si wà li ojurere li ọdọ Ọlọrun ati enia.


Nitorina, Ọlọrun retí wípé ìgbà kan wà tí àwa náà yóò máa kẹkọọ kí a lè máa ṣe igbaradi fún iṣẹ iransẹ tí a ti
pe wá sí. Ní ọpọlọpọ ìgbà, kìíse ìgbà tí a bá pè wá ni Ọlọrun fẹ kí a bẹrẹ iṣẹ náà pato. Eleyii kò niiṣe pẹlu iṣẹ
ìwàásù ihinrere tí Jésù ti fi fún gbogbo ènìyàn ṣugbọn awọn àkànṣe iṣẹ iransẹ tó yàtọ, ipè ọtọ tí Ọlọrun fi pè
wá tó yàtọ sí tí gbogbo ènìyàn yòókù.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 13:2
[2]Bi nwọn si ti njọsìn fun Oluwa, ti nwọn si ngbàwẹ, Ẹmí Mimọ́wipe, Ẹ yà Barnaba on Saulu sọtọ̀fun mi fun
iṣẹ ti mo ti pè wọn si.


Nínú ẹsẹ yìí a rí wípé ìgbà tí a ya Barnaba àti Ṣaulu sí ọ̀tọ̀fún iṣẹ iransẹ wọn kìíse ìgbà tí Ọlọrun ti pe wọn.
Ọlọrun ti pè wọn télètélè ṣugbọn nínú abala tí a kà yìí ni o ti yà wọn sọt́ọ̀fún iṣẹ náà, èyí ni wipe àkókò ti tó
láti jáde lọ ṣe iṣẹ náà nìyẹn.


Nítorí èyí ni idagbasoke fi ṣe pàtàkì nínú Èmi. Ìtumò wípé onigbagbọ n dagbasoke nínú Èmi kìíse wípé O n ní
ìmọ àti òye nínú ẹkọ Bíbélì nìkan bikòṣe wípé O ní ìtara púpọ si nípa iṣẹ iransẹ.

Ohun tó yẹ kí iṣẹ iransẹ awọn ti Ọlọrun pè ṣe nínú ayé onigbagbọ nìyẹn. Bí a ṣe lè mọ bóyá a wà labẹ iṣẹ
iransẹ Olusoaguntan tó yẹ kí a wà gan ni èyí. Ó yẹ kí a bi ara wa l’eere wípé “Nje ìwàásù tí mo ti n gbọ láti ọjọ
yìí wa fún mi ní òye, okun, ìtara àti agbára láti ṣe iṣẹ iransẹ bí?” Njẹ mo mọ ìpè tí Ọlọrun pè mí sí bí?


EFESU 4:11-12
[11]O si ti fi awọn kan funni bi aposteli; ati awọn miran bi woli; ati awọn miran bi efangelisti, ati awọn miran
bi oluṣọ-agutan ati olukọni;
[12]Fun aṣepé awọn enia mimọ́fun iṣẹ-iranṣẹ, fun imudagba ara Kristi:
Abala Bíbélì yìí sọ fún wa wípé kí a lè ṣe iṣẹ iransẹ ni ìdí tí a fi wà labẹ iṣẹ iransẹ awọn wọnyii.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading