Ọjọ́ Kẹjọ (8), Ọjọ́rú , Oṣù Kejì , Ọdún 2023

KRISTẸNI GẸGẸ BÍ IMỌLẸ (1)

KRISTẸNI GẸGẸ BÍ IMỌLẸ (1)


Bíbélì jẹ kí a mọ wipe nínú ayé yìí, okunkun tó su biribiri lo wà níbẹ. Okunkun yìí túmọ sí iṣẹ satani ati ìwà
búburú àwọn ènìyàn. Nigbati Jésù wá sínú ayé yìí, ẹ gbọ ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ.


JOHANU 1:4-5
[4]Ninu rẹ̀ni ìye wà; ìye na si ni imọlẹ̀araiye.
[5]Imọlẹ na si nmọlẹ ninu òkunkun; òkunkun na kò si bori rẹ̀.


Kò sí ẹnikẹni tó lè kúrò nínú okunkun ayé yìí àyàfi tó bá ṣe alabapade Jésù Kristi nítorípé nínú rẹ ní imọlẹ wà.
A ti sọ wipe okunkun tọkasi iṣẹ satani, awọn èmi búburú rẹ àti ìwà búburú ènìyàn. Nitorina ẹnikẹni tí Kristi
bá ti gbà ti bọ lọwọ àwọn iṣẹ èṣù wọnyii.


KOLOSE 1:13
[13]Ẹniti o ti gbà wa kuro lọwọ agbara òkunkun, ti o si ṣi wa nipo sinu ijọba ayanfẹ ọmọ rẹ̀:


Tí a bá sakiyesi ẹsẹ Bíbélì yìí, kò sọ wipe yóò gbà wá kúrò nínú agbára okunkun ṣugbọn o sọ wipe O ti gbà wá.
Èyí n tọkasi awa onigbagbọ nínú Kristi nítorípé ohun tí Kristi wá ṣe nínú ayé gan ni èyí. Ìdí èyí ni Kristi fi sọ
awọn nkan wọnyii nipa ara rẹ.


JOHANU 9:5
[5]Niwọn igba ti mo wà li aiye, emi ni imọlẹ aiye.


Nítorínáà Jésù nìkan ni ohun tó yàtọ nínú ayé yìí, bo tí wulẹ kí àwọn nkan tí a n rí nínú ayé yìí fa ọgbọn yọ tó
òkùnkùn ni wọn tí kò bá ti ni Jésù nínú. Ìgbà míràn wà tó jẹ wípé àwon alaigbagbọ míràn lè hùwa tó jẹ wípé
onigbagbọ gan fúnra lè máa ro wipe bóyá o dára ju ti awọn ọmọ Ọlọrun gan lọ. Ẹtan satani lásán ni. Laiṣi
Jésù, kò sí ẹnikẹ́ni tó lè ní imọlẹ, bo ti wulẹ kí wọn hùwa rere tó nítorípé ìwà réré láìsí Jésù òkùnkùn ni.
Okunkun yìí kọja ìwà nítorípé ìṣẹ̀dá alaigbagbọ jẹ okunkun.

EFESU 5:8
[8]Nitori ẹnyin ti jẹ òkunkun lẹ̃kan, ṣugbọn nisisiyi, ẹnyin di imọlẹ nipa ti Oluwa: ẹ mã rìn gẹgẹ bi awọn ọmọ
imọlẹ:


Tí a bá sakiyesi ẹsẹ yìí daradara, kò sọ wipe wọn wà nínú okunkun nikan ṣugbọn o pe wọn ní okunkun nígbà
kan rí. O wá sọ wipe wọn tí wá di imọlẹ ní báyìí. Kìíse ọna kan péré tí a ti pe alaigbagbọ ní okunkun ni èyí.


KỌRINTI KEJI 6:14
[14]Ẹ máṣe fi aidọgba dàpọ pẹlu awọn alaigbagbọ: nitori ìdapọ kili ododo ́ ni pẹlu aiṣododo? ìdapọ kini imọlẹ
si ni pẹlu òkunkun?


Nínú ẹsẹ yìí, awọn alaigbagbọ ni Bibeli pe ní okunkun.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading