Ọjọ́ Kejìlélógún (22), Ọjọ́rú , Osù Kejì , Ọdún 2023

ÀLÀYÉÌWÉGALATIAL’ẸŚẸẸSẸ(8)

A ti rí àwọn kan tí wọn máa n sọ wípé àwon ẹkọ tí Paulu kọ yatọ sí ohun tí Kristi ati awọn ọmọlẹyìn rẹ kọ́. Awọn yìí máa n sọ bẹẹ kí wọn má baà gba awọn nkán tí Èmi Mimọ fún Paulu ní isipaya láti kọ sílẹ gbọ. Ẹ jẹ kí a mọ wipe igbagbo Kristiani dúró lórí ajinde Kristi. Àjínde Kristi ni ìpìlẹ tó lágbára julọ nínú ìgbàgbọ Kristẹni.

KỌRINTI KINNI 15:12-14
[12]Njẹ bi a ba nwasu Kristi pe o ti jinde kuro ninu okú, ẽhatiṣe ti awọn miran ninu nyin fi wipe, ajinde okú kò si?
[13]Ṣugbọn bi ajinde okú kò si, njẹ Kristi kò jinde:
[14]Bi Kristi kò ba si jinde, njẹ asan ni iwãsu wa, asan si ni igbagbọ́ nyin pẹlu.

Kìíse Paulu lo bẹrẹ sí níí sọ nípa àjínde Kristi gẹgẹ ohun tó yẹ kí àwọn ènìyàn gbagbọ láti di ẹni ìgbàlà. Kí Jésù Olúwa wa tó kú lórí igi agbelebu tó sì jinde kúrò nínú òkú, o tí kọkọ bá Pétérù sọrọ nípa wípé ijẹwọ Peteru nípa Kristi ni ohun tí ìjọ Ọlọrun yóò dúró le lórí.

MATIU 16:16-18
[16]Simoni Peteru dahùn, wipe, Kristi, Ọmọ Ọlọrun alãye ni iwọ iṣe.
[17]Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Alabukun-fun ni iwọ Simoni Ọmọ Jona: ki iṣe ẹran ara ati ẹ̀jẹ li o sá fi eyi hàn ọ, ṣugbọn Baba mi ti mbẹ li ọrun.
[18]Emi si wi fun ọ pẹlu pe, Iwọ ni Peteru, ori apata yi li emi ó si kọ ijọ mi le; ẹnu-ọ̀na ipo-oku kì yio si le bori rẹ̀

Nitorina Jésù ló jẹ kí a mọ pàtàkì ijẹwọ Pétérù nípa Kristi. Peteru yìí kan náà ni Ọlọrun lo láti bá àwọn ènìyàn sọrọ ní ọjọ Pentikosti nígbàtí wọn pejọ lẹhin ìgba tí Èmi Mimọ bà lé àwọn onígbàgbọ nínú Kristi. Pétérù sọrọ nípa àsọtẹlẹ Dáfídì Ọba gẹgẹ bí wòlíì tó sọrọ ṣaaju nípa àjínde Kristi.

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 2:27,29,31-32
[27]Nitoriti iwọ ki yio fi ọkàn mi silẹ ni ipò-okú, bẹ̃ni iwọ ki yio jẹ ki Ẹni-Mimọ́ rẹ ki o ri idibajẹ.
[29]Ará, ẹ jẹ ki emi ki o sọ fun nyin gbangba niti Dafidi baba nla pe, o kú, a si sin I, ibojì rẹ̀ si mbẹ lọdọ wa titi o fi di oni yi.
[31]O ri eyi tẹlẹ̀, o sọ ti ajinde Kristi pe, a kò fi ọkàn rẹ̀ silẹ ni ipò-okù, bẹ̃li ara rẹ̀ kò ri idibajẹ.
[32]Jesu na yi li Ọlọrun ti ji dide, ẹlẹri eyiti gbogbo wa iṣe.

Nigbati Pétérù sọ èyí, Paulu kò tíì di onígbàgbọ nígbà náà. Nitorinà kìíse òun ló bẹrẹ sí níí sọ nípa àjínde Kristi kuro nínú òkú gẹgẹ bí ọna iye tí Ọlọrun gbé kalẹ fún ìgbàlà gbogbo arayé.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading