Ọjọ́ Kejìlélógún (22), Ọjọ́ Àìkú , Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

ṢÍṢE IṢẸ OLÚWA (4)

Kìíse ojú lásán tàbí ẹnu lásán ni Ọlọrun fi retí wípé a o máa wàásù ìhìnrere, pàápàá jùlọ tí a bá wo ohun tí
Jésù sọ nígbà tó n ṣe agbekalẹ bí ìjọ rẹ yóò ṣe máa wàásù ìhìnrere rẹ. Ko tó padà lọ sí ọdọ Bàbá, O kọkọ ran
wọn jáde nígbà tó sì wà pẹlu wọn.


LUKU 10:19
[19]Kiyesi i, emi fun nyin li aṣẹ lati tẹ̀ejò ati akẽkẽ mọlẹ, ati lori gbogbo agbara ọtá: kò si si ohunkan bi o ti
wù ki o ṣe, ti yio pa-nyin-lara.


Nígbà tí a n sọ yìí gan kò tíì fún wọn ni Èmi Mimọ rẹ. Lootọ wọn kò tíì gba Èmi rẹ nígbà náà sugbọn kìíse
ìpinnu rẹ wipe ẹnikẹni tó bá rán jáde kó má lè rìn nínú agbára rẹ.


JOHANU 14:12
[12]Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, iṣẹ ti emi nṣe li on na yio ṣe pẹlu; iṣẹ ti o tobi jù wọnyi
lọ ni yio si ṣe; nitoriti emi nlọ sọdọ Baba.


Ìpinnu rẹ ni wipe ọna tí àwon ènìyàn yóò gbà mọ wipe lootọ òun ló rán wa ni wípé a n fi agbára rẹ hàn gẹgẹ
bí ohun náà ti máa n ṣe. Kìíse wípé kí a máa fi enu nikan jewo rẹ ṣugbọn ìdùnnú Ọlọrun ni wipe agbára rẹ náà
yóò máa jẹyọ nínú ayé àti nínú iṣẹ iransẹ wa ní ọnà tí yóò fihàn wípe lootọ ni Kristi wà láàyè nitoripe ẹnikẹni
tí a bá n rí iṣẹ rẹ, a jẹ wípé ẹni náà wà láàyè nìyẹn. Ìhìnrere ti Kristi náà ni wipe O jinde kúrò nínú òkú àti wípé
O wà láàyè Títí láé. Nitorina ìdánilójú wípé òtítọ ni Kristi n bẹ láàyè ni wipe bó ṣe n ṣiṣe ìyanu nígbà náà, O sì
n ṣiṣe náà Títí di àkókò yíì.

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 4:13
[13]Nigbati nwọn si kiyesi igboiya Peteru on Johanu, ti nwọn si mọ̀pe, alaikẹkọ ati òpe enia ni nwọn, ẹnu yà
wọn; nwọn si woye wọn pe, nwọn a ti ma ba Jesu gbé.


Nípa ìgboyà awọn Aposteli ni awọn eniyan fi mọ wipe lootọ ni wọn jẹ ọmọlẹyìn Jésù àti wípé wọn ti wà pẹlu
Jésù ní òtítọ nítorípé kò sí ẹnikẹ́ni tó má se n sọrọ bẹẹ ayafi tí Kristi bá n ṣiṣe nipasẹ ẹni náà. Kí ló fún wọn ní
ìgboyà yìí bikòṣe wípé àwon iṣẹ agbára n ṣẹlẹ nínú iṣẹ iransẹ wọn, wọn gbàdúrà, wọn sì máa n kún fún Èmí
Mimọ ní gbogbo ìgbà.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 4:30-31
[30]Ki iwọ si fi ninà ọwọ́rẹ ṣe dida ara, ati ki iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu ki o mã ṣe li orukọ Jesu Ọmọ mimọ́rẹ.
[31]Nigbati nwọn gbadura tan, ibi ti nwọn gbé pejọ si mi titi; gbogbo wọn si kún fun Ẹmí Mimọ́, nwọn si nfi
igboiya sọ ọ̀rọ Ọlọrun.


Ẹnikẹni tó bá n wàásù ìhìnrere Kristi gbọdọ kún fún ádùrá kí Ọlọrun na ọwọ agbára rẹ kí iṣẹ amin àti iṣẹ ìyanu
lè ṣẹlẹ. Awọn iṣẹ irú èyí ló jẹrìí nípa irú ẹni tí Kristi jẹ.


JOHANU 10:25
[25]Jesu da wọn lohùn wipe, Emi ti wi fun nyin, ẹnyin kò si gbagbọ́; iṣẹ ti emi nṣe li orukọ Baba mi, awọn ni
njẹri mi.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading