Ọjọ́ Kejìlá (12), Ọjọ́ Àìkú , Oṣù Kejì , Ọdún 2023

KRISTẸNI GẸGẸ BÍ IMỌLẸ (5)

KRISTẸNI GẸGẸ BÍ IMỌLẸ (5)


Irú ìfẹ wo ni a n sọ tí a bá sọ wípé onigbagbọ n rìn nínú ìfẹ. Jésù ṣàlàyé wípé irú ìfẹ yìí yàtò sí èyí tí ọpọlọpọ
awọn olùgbọ rẹ tó wà labẹ òfin mọ nípa rẹ. O sàlàyé èyí lọpọlọpọ ninu ẹkọ rẹ.


MATIU 5:43-45
[43]Ẹnyin ti gbọ́bi a ti wipe, Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ, ki iwọ si korira ọtá rẹ.
[44]Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ẹ sure fun awọn ẹniti o nfi nyin ré, ẹ ṣõre fun awọn ti o
korira nyin, ki ẹ si gbadura fun awọn ti nfi arankàn ba nyin lò, ti nwọn nṣe inunibini si nyin;
[45]Ki ẹnyin ki o le mã jẹ ọmọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun: nitoriti o nmu õrùn rẹ̀ràn sara enia buburu ati sara
enia rere, o si nrọ̀jo fun awọn olõtọ ati fun awọn alaiṣõtọ.


Jésù kọkọ tọka awọn Olùgbọ rẹ sí nkan tí wọn ti mọ tẹlẹ tẹlẹ nípa “Ẹnyin ti gbọ́bi a ti wipe”, Ofin Mósè ni
Jésù n tokasi sí. O n sọ fún wọn wípé òfin tí ohun fẹ fún wọn yàtọ sí èyí ti wọn ti mọ tẹlẹ tẹlẹ, nitori èyí ló fi
tẹsiwaju láti sàlàyé fún wọn nípa rẹ.


Nigbati Jésù sọ wípé “Ki ẹnyin ki o le mã jẹ ọmọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun”, o n sàlàyé wípé irú ìfẹ tí òun n sọ
yi, ìfẹ tó jẹ wípé ẹni tó bá ti jẹ ọmọ Ọlọrun nìkan ló ṣeéṣe fún ni. Ìfẹ yìí niiṣe pẹlu ẹni tí a jẹ, kìíse àjàgà wíwo
rárá bí ikoni tí àwọn Farisi àti Sadusi àti àwọn olùkọ òfin máa n ṣe.


MATIU 23:4
[4]Nitori nwọn a di ẹrù wuwo ti o si ṣoro lati rù, nwọn a si gbé e kà awọn enia li ejika; ṣugbọn awọn
tikarawọn ko jẹ fi ika wọn kàn ẹrù na.

Ọna kan tí ìlànà Ọlọrun kò fi níí di eru wuwo lè ènìyàn lórí ni wipe ìlànà náà ti di iseda fún wa ni, kìíse ẹrù
wiwo rárá. Ó jẹ nkan tó n fi iseda wa hàn gẹgẹ bí onigbagbọ ni. Jésù tún sọ wípé nipa fifi irú ìfẹ yìí hàn ni
awọn ṣe lè mọ wipe lootọ ọmọ Ọlọrun ni a jẹ nitoripe iru Ife yìí, ìfẹ tó wà nínú mọlẹbi Ọlọrun nìkan ni. Ìfẹ tí
kò fa ogbón yọ gẹgẹ bí ọgbọn ènìyàn ni. Níwájú ènìyàn, a jẹ òmùgọ ṣugbọn níwájú Ọlọrun, a n tẹle ìlànà tí
Kristi ti fi le’lẹ fún wa ni.


JOHANU 13:35
[35]Nipa eyi ni gbogbo enia yio fi mọ̀pe, ọmọ-ẹhin mi li ẹnyin iṣe, nigbati ẹnyin ba ni ifẹ si ọmọnikeji nyin.
Ìfẹ yìí ni imọlẹ tí a ó tàn ti awọn tó wà nínú okunkun yóò fi lè mọ ẹni tí Ọlọrun jẹ nítorípé a fi ìwà jọ Baba wa.
Báwo ni Ọlọrun náà ṣe fi ìfẹ hàn.


ROMU 5:6-8
[6]Nitori igbati awa jẹ alailera, li akokò ti o yẹ, Kristi kú fun awa alaiwa-bi-Ọlọrun.
[7]Nitori o ṣọ̀wọn ki ẹnikan ki o to kú fun olododo: ṣugbọn fun enia rere boya ẹlomiran tilẹ le dába ati kú.
[8]Ṣugbọn Ọlọrun fi ifẹ On papa si wa hàn ni eyi pe, nigbati awa jẹ ẹlẹṣẹ, Kristi kú fun wa.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading