Ọjọ́ Kejìdínlógún (18), Ọjọ́rú , Oṣù Kíní , Ọdún 2023

ÒFIN TÍTÚN TI KRISTI (3)

ÒFIN TÍTÚN TI KRISTI (3)


Ara amin wipe ènìyàn gbagbọ ninu Kristi ni wipe yóò máa lépa láti tẹlé awọn Ilana ti Kristi Jésù. Kíni oore ọfẹ
Kristi kọ wa? Njẹ oore ọfẹ yìí túmọ sí wipe ohunkohun tó bá wù wá ni a lè ṣe?
Paulu ninu lẹta rẹ sí Titu dahùn awọn ìbéèrè yìí.


TITU 2:11-12
[11]Nitori ore-ọfẹ Ọlọrun ti nmu igbala fun gbogbo enia wá ti farahan,
[12]O nkọ́wa pe, ki a sẹ́aiwa-bi-Ọlọrun ati ifẹkufẹ aiye, ki a si mã wà li airekọja, li ododo, ati ni ìwa-bi-Ọlọrun
ni aiye isisiyi;


Nitorina oore ọfẹ Ọlọrun kọ wa láti takete sí aisododo. Tí a bá ṣe ayẹwo ẹkọ Kristi, o fún wa ní ojúṣe gẹgẹ bíi
ọmọlẹyìn rẹ ju òfin Mósè lọ.


TIMOTI KEJI 2:19
[19]Ṣugbọn ipilẹ Ọlọrun ti o daju duro ṣinṣin, o ni èdidi yi wipe, Oluwa mọ̀awọn ti iṣe tirẹ̀. Ati pẹlu, ki
olukuluku ẹniti npè orukọ Oluwa ki o kuro ninu aiṣododo.

Ìpìlẹ Ọlọrun n tọkasi oore ọfẹ tó wà nínú Kristi. Oore ọfẹ yìí kìíse fún ẹsẹ ṣugbọn O n gbà wá lọwọ agbára ẹsẹ
náà. Èyí ni a kọ sínú Episteli sí àwọn ará Róòmù.

ROMU 6:14
[14]Nitori ẹ̀ṣẹ kì yio ni ipa lori nyin: nitori ẹnyin kò si labẹ ofin, bikoṣe labẹ ore-ọfẹ.

Gẹgẹ bí ẹni tó ti wà labẹ oore ọfẹ Ọlọrun, ara àwọn nkan tó yẹ kí a mọ ni wipe ririn ni ọna tó bá ìfẹ Ọlọrun
mu kìíse àjàgà fún wa mọ nítorípé a ti dá wa n’ide kúrò nínú agbára tí ẹsẹ n ní lórí ọkàn alaigbagbọ. Lórí ayé
alaigbagbọ, ẹsẹ máa n jọba níbè ni nítorípé wọn kò ní agbára láti gba ara wọn sílẹ kúrò nínú igbekun ẹsẹ náà.
Ṣugbọn ti onigbagbo yàtọ. A ti sọ wá di ominira kúrò labẹ gbogbo ìgbèkùn ẹsẹ.

GALATIA 5:1
[1]NITORINA ẹ duro ṣinṣin ninu omnira na eyi ti Kristi fi sọ wa di omnira, ki ẹ má si ṣe tún fi ọrùn bọ àjaga ẹrú
mọ́.

Nínú oore ọfẹ Kristi ni ominira yìí wà. Kìíse ominira láti máa dá ẹsẹ bikòṣe òmìnira kúrò lọwọ gbogbo nkan tó
bá iṣẹ satani, ìgbèkùn, okunkun ti ayé yìí mu.

JOHANU 8:12,32
[12]Jesu si tun sọ fun wọn pe, Emi ni imọlẹ aiye; ẹniti o ba tọ̀mi lẹhin kì yio rìn ninu òkunkun, ṣugbọn yio ni
imọlẹ ìye.
[32]Ẹ ó si mọ̀otitọ, otitọ yio si sọ nyin di omnira.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading