Ọjọ́ Kejìdínlógún (18), Ọjọ́ Àbámẹ́ta, Osù Kejì , Ọdún 2023

KRISTẸNI GẸGẸ BÍ IMỌLẸ (11)

Gẹgẹ bí onigbagbọ a gbà wá níyànjú láti rìn nínú ìwà mímọ àti láti ta kété sí ẹsẹ.

TẸSALONIKA KINNI 5:22
[22]Ẹ mã takéte si ohun gbogbo ti o jọ ibi.

EFESU 5:3
[3]Ṣugbọn àgbere, ati gbogbo ìwa ẽrí, tabi ojukòkoro, ki a má tilẹ darukọ rẹ̀ larin nyin mọ́, bi o ti yẹ awọn enia mimọ́;

EFESU 4:22
[22]Pe, niti iwa nyin atijọ, ki ẹnyin ki o bọ ogbologbo ọkunrin nì silẹ, eyiti o dibajẹ gẹgẹ bi ifẹkufẹ ẹ̀tan;

Nitorinà gẹgẹ bí onigbagbọ, a nilo láti ta kété sí ẹsẹ àti láti rìn ní ọnà tó wu Ọlọrun. Ní ọpọlọpọ ìgbà ni èyí máa n ṣòro fún ènìyàn, gẹgẹ bí eleran ara, láti ṣe. Nitorina kini ohun tí Bíbélì kọ wa láti ṣe nípa èyí?

GALATIA 5:16
[16]Njẹ mo ni, Ẹ ma rìn nipa ti Ẹmí, ẹnyin kì yio si mu ifẹkufẹ ti ara ṣẹ.

Nitorina ohun tí Bíbélì jẹ kí a mọ ni wípé tí a bá n rìn nínú Èmi, a kò ní mú ifekufe ti ara ṣẹ. Ohun tí èyí tún fihàn fún wa ni wípé ara ní iseda tirẹ, àti àwọn nkan tó fẹràn láti ṣe. Ara wa kò tíì di Atunbi, èmi inú wa ló ti yípadà. Nitorina awọn ifẹ ti ara wà, bẹẹ náà sì ni àwọn ìfẹ ti emi wà.

ROMU 8:13
[13]Nitori bi ẹnyin ba wà ni ti ara, ẹnyin ó kú: ṣugbọn nipa Ẹmí bi ẹnyin ba npa iṣẹ́ ti ara run, ẹnyin ó yè.

Tí a bá n tẹle ifekufe ti ara, q kò lè ṣe aseyege nínú Kristi. Bíbélì sọ wípé ikú ni. Èyí ni wipe ara ni iseda ati awọn ifẹ tirẹ. Bẹẹ náà ni Emi ní tirẹ. Nitorinà nkan tó niiṣe pẹlu ti Emi ló yẹ ki a tẹle. Báwo ni ènìyàn ṣe n tẹle nkan ti Ẹmi? A rí ìdáhùn yìí tí a bá padà sínú ìwé Galatia.

GALATIA 5:22-23
[22]Ṣugbọn eso ti Ẹmí ni ifẹ, ayọ̀, alafia, ipamọra, ìwa pẹlẹ, iṣore, igbagbọ́, [23]Ìwa tutù, ati ikora-ẹni-nijanu: ofin kan kò lodi si iru wọnni.

Nípa rìnrìn nínú ìfẹ ni nkan tí a n pè ní rìnrìn nínú Èmi. Èyí tumosi wípé tí a bá n rìn nínú ìfẹ, a kò ní lu awọn òfin tí a fi sílẹ nítorí ẹsẹ.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading