Ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n (28), Ọjọ́ Ìsẹ́gun , Osù Kejì , Ọdún 2023

ÀLÀYÉÌWÉGALATIAL’ẸŚẸẸSẸ(14)

Ní báyìí a o bẹrẹ sí níí ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ẹkọ tí a lè rí tọkasi ninu Episteli sí àwọn ará Galatia.

GALATIA 1:1
[1]PAULU, Aposteli (ki iṣe lati ọdọ enia wá, tabi nipa enia, ṣugbọn nipa Jesu Kristi, ati Ọlọrun Baba, ẹniti o jí I dide kuro ninu okú),

Gẹgẹ bí a ti sàlàyé siwaju wipe ọrọ nípa ẹni tí Ọlọrun n lo láti ṣe ikọ́ni ṣe pàtàkì nípa ọwọ tí àwọn ènìyàn yóò fi mú ẹkọ náà. Nitorina nínú ẹsẹ tí a n ṣe ayẹwo rẹ yìí, a sọ fún wa wípé Paulu kò gba iṣẹ iransẹ láti ọdọ eniyan bikòṣe lati ọdọ Ọlọrun wá. Gẹgẹ bí onigbagbọ nínú Kristi, ẹkọ tí a lè rí kọ níbẹ ni wipe kìíse ènìyàn ló n fúnni ní iṣẹ iransẹ bikòṣe Ọlọrun gan funrararẹ lootọ O máa n lo awọn ẹlomiran láti ṣe ìfilọ́lẹ̀ àti láti lè jẹ kí o dá àwọn ènìyàn lójú wípé lootọ ni Ọlọrun pè wá sínú iṣẹ iransẹ rẹ.

Tí a bá lo Paulu gẹgẹ bí àpẹẹrẹ, a o ri wipe Ọlọrun pèé sínú iṣẹ iransẹ nipasẹ awọn ẹlomiran.

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 9:13-15
[13]Anania si dahùn wipe, Oluwa, mo ti gburó ọkunrin yi lọdọ ọ̀pọ enia, gbogbo buburu ti o ṣe si awọn enia mimọ́ rẹ ni Jerusalemu.
[14]O si gbà aṣẹ lati ọdọ awọn olori alufa wá si ihinyi, lati dè gbogbo awọn ti npè orukọ rẹ.
[15]Ṣugbọn Oluwa wi fun u pe, Mã lọ: nitori ohun elo àyo li on jẹ fun mi, lati gbe orukọ mi lọ si iwaju awọn Keferi, ati awọn ọba, ati awọn ọmọ Israeli:

Nigbati Paulu gan kò tíì mọ nípa ipè sínú iṣẹ iransẹ ti Ọlọrun ní lọkàn fún ni Ọlọrun ti sọ fún Ananaia nipa rẹ. Kìíse Ananaia nikan ni Ọlọrun lo. Awọn wòlíì àti olukọni nínú ìjọ Ọlọrun tó wà ní Antioku náà, Ọlọrun bá wọn sọrọ nípa ipè sínú iṣẹ iransẹ yìí.

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 13:1-3
[1]AWỌN woli ati awọn olukọni si mbẹ ninu ijọ ti o wà ni Antioku; Barnaba, ati Simeoni ti a npè ni Nigeri, ati Lukiu ara Kirene, ati Manaeni, ti a tọ́ pọ̀ pẹlu Herodu tetrarki, ati Saulu.
[2]Bi nwọn si ti njọsìn fun Oluwa, ti nwọn si ngbàwẹ, Ẹmí Mimọ́ wipe, Ẹ yà Barnaba on Saulu sọtọ̀ fun mi fun iṣẹ ti mo ti pè wọn si.
[3]Nigbati nwọn si ti gbàwẹ, ti nwọn si ti gbadura, ti nwọn si ti gbe ọwọ́ le wọn, nwọn si rán wọn lọ.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading